islamkingdomfacebook


ỌLA TI O WA FUN AWỌN ỌJỌ MẸWA AKỌKỌ OSU DHUL-HIJJAH (OSU KEJILA OJU ỌRU

ỌLA TI O WA FUN AWỌN ỌJỌ MẸWA AKỌKỌ   OSU DHUL-HIJJAH (OSU KEJILA OJU ỌRU

6415
Eko ni soki
Igba ti o tobi julo ni alubarika ni awon ojo mewa akoko ninu osu dhil-hijjah, nitori wipe o ni ipo ti o ga lodo Olohun oba ti ola re ga, eleyi ti o ntoka si ife ti Olohun ni sii ati gbigbe tobi re, ohun ni awon ojo mewa alalubarika, ti awon daadaa po ninu re, ti awon aburu inu re si kere, ipo re si ga oniranran ise oloore lo wa nibe, Olohun bura pelu re, Olohun ko si bura pelu nkan ayafi ki nkan naa o tobi, O si se ni eleyi ti o lola julo ninu awon ojo aye patapata

Awọn erongba lori Khutuba naa:

1-     Sise alaye wipe Ọlọhun lagbara ati se ẹda nkan ti o wu U, ati agbara ati sa ẹsa eyi ti o wu U.

2-     Riran awọn eniyan ni eti awọn asiko oore, ati lati se amulo wọn fun awọn isẹ daada;

3-     Sise alaye ọla awọn ọjọ yi;

4-     Sise alaye pe Ọla Ọlọhun ati Aanu Rẹ pọ fun awọn ẹru Rẹ.

 

(ogun isẹju):

الحمد لله القائل {وَلَيالٍ عَشْرٍ} [الفجر: 2]. والصّلاة والسّلام على رسول الله القائل: ((ما من أيام العمل الصالح فيها أحب إلى الله من هذه الأيام " يعني أيام العشر قالوا يارسول الله ولا الجهاد في سبيل الله ؟ قال " ولا الجهاد في سبيل الله إلا رجل خرج بنفسه وماله فلم يرجع من ذلك بشىء)).

Dajudaju Ọlọhun ni agbara ati se ẹda nkan ti o wu U, Osi ni agbara ati sa ẹsa eyi ti o wu U. Ki a bẹru Ọlọhun naa, Eyi ti O da awọn sanma ti O si sa ẹlẹẹkeje ni ẹsa, O da awọn alijanna O si sa alijanna Firdaos ni ẹsa ni aarin wọn, O da awọn malaikah O si sa Jibrila, Mikail ati Israfil ni ẹsa ni aarin wọn, O da gbogbo ẹda O si sa awọn mumini ni ẹsa ni aarin wọn, O si sa awọn annabi ni ẹsa ni aarin awọn mumini, ti O si se ẹsa awọn ojisẹ ni aarin awọn annabi, O tun mu awọn oni aniyan ti o gaju (ulu-'azmi: Nuh, Ibrahim, Musa, 'Isa ati Muhammad) ni aarin awọn ojisẹ, O tun se ẹsa awọn aayo meji (Ibrahim ati Muhammad) ni inu wọn, ti O si tun se ẹsa Muhammad (صلّى الله عليه وسلّم) ni inu awọn aayo mejeeji naa. O da awọn ilẹ O se ẹsa Mọkka, O da awọn osu O si se adayanri osu Ramadan, ni inu awọn ọjọ O se adayanri ọjọ Jimọh, ni inu awọn oru, O se adayanri oru èbùbù abiyi (Lailatul Kọdir), ninu awọn wakati O se ẹsa wakati kan ni ọjọ Jimọh, ni inu awọn ọjọ mẹwa Ọlọhun se ẹsa awọn ọjọ mẹwa akọkọ osu Dhul-Hijjah. Titobi Ọlọhun ninu ọla ati agbara Rẹ.

Gbogbo isẹmi mumini alubarika ati oore ni o jẹ, ni inu isẹ rẹ ati asiko rẹ. Eyi ti alubarika rẹ tobi ju ni isẹ daada ti o ba fi awọn asiko rẹ se. Ọlọhun sọ bayi pe:

{مَنْ جَاءَ بِالْحَسَنَةِ فَلَهُ عَشْرُ أَمْثَالِهَا} [الأنعام: 160].

Itumọ tun wa ni inu Hadith Ibn 'Abbas. [Sahihul Bukhari ati Musilimu].

Itẹle ti Ọlọhun alubarika ni o jẹ, yala ọrọ ẹnu ni o, tabi isẹ afarase. Gbolohun kan tabi isẹ daada kan yoo lọpo si mẹwa. Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) gba ẹgbawa ni ati ọdọ Ọlọhun pe: " irun kan ti mumini ba ki, laada irun mẹwa ni yoo gba". Ti o tumọ si pe irun kan soso se deede aadọta irun ni ibi laada rẹ. [Sahihul Bukhari ati Musilimu].

Aawẹ osu Ramadan kan soso si se deede aawẹ osu mẹwa, ti aawẹ ọjọ mẹfa pere ni inu osu Shawwal –osu kẹẹwa oju ọrun- si se deede aawẹ osu meji gbako. [Ibn Khuzaimah ati al-Nasaai].

Laada sara kan ni sise yoo lọpo si ọgọrun meje igba. [Ahmad].

Haji Mabrur –Haji ti o ni alaafia- ẹsan rẹ ni alijanna.

Gbogbo isẹ daada afọmọ ni o jẹ kuro ni ibi ẹsẹ. Afọmọ kuro ni ibi ẹsẹ ni irun ti a n ki jẹ pẹlu. [Muwata Malik].

Kódà itẹle ti Ọlọhun ni inu ibasepọ pẹlu awọn eniyan alubarika ni o jẹ.

Ni inu awọn asiko ti o ni alubarika julọ ni mẹwa akọkọ osu Dhul-Hijjah ni itori ipo nla rẹ ni ọdọ Ọlọhun.

Ni inu ọla asiko yi ni ọdọ Ọlọhun nipe: O fi asiko naa bura

{وَلَيالٍ عَشْرٍ} [الفجر: 2]

Nkan ti o ba ni ọla sini Ọlọhun maa fi n bura ni inu awọn asiko, gẹgẹ bi igba owurọ, irọlẹ, iyalẹta, oru, ọsan ati mẹwa akọkọ osu Dhul-Hijjah. Bi Ọlọhun ti se maa n bura pẹlu awọn ẹda Rẹ ti o ni apọnle bi: ilẹ, sanma, oorun, osupa, irawọ ati atẹgun, ti O si maa n bura pẹlu aaye apọnle bi Mọkkah.

Ọlọhun le bura pẹlu nkan ti o ba wu U, sugbọn ko tọ ki awa ẹda bura pẹlu nkan miran yatọ si Ọlọhun.

Bibura ti Ọlọhun n bura pẹlu awọn ẹda Rẹ yi n tọka si titobi ati ọla wọn ni.

Ni inu ọla ti o wa fun mẹwa osu Dhul-Hijjah nipe Ọlọhun fi asiko oru eyi ti o ni ọpọlọpọ ọla ti o si jẹ asiko gbigba adua. Ọlọhun sọbayi ninu Al-Kuran:

{ كانوا قليلاً من الليل ما يهجعون . وبالأسحار هم يستغفرون} [الذاريات 17-18].

Ọlọhun N royin awọn ti wọn maa n dide loru lati sin Oluwa wọn wipe: diẹ pere ni inu oru wọn ni wọn maa n fi n sun, ti wọn si maa tọrọ aforijin ni asiko saari, eyi ti o sun mọ asiko asuba. [Ad-Dhaariyaat 17-18]. Tun wo itumọ yi ninu:

{تَتَجَافَى جُنُوبُهُمْ عَنْ الْمَضَاجِعِ يَدْعُونَ رَبَّهُمْ خَوْفًا وَطَمَعًا وَمِمَّا رَزَقْنَاهُمْ يُنفِقُونَ} [السّجدة: 16].

{وَعِبَادُ الرَّحْمَنِ الَّذِينَ يَمْشُونَ عَلَى الأَرْضِ هَوْنًا وَإِذَا خَاطَبَهُمْ الْجَاهِلُونَ قَالُوا سَلامًا وَالَّذِينَ يَبِيتُونَ لِرَبِّهِمْ سُجَّدًا وَقِيَامًا} [الرّحمن 63-64].

Ni inu ọla ti o wa fun mẹwa osu Dhul-Hijjah nipe Ọlọhun se idẹra Rẹ fun awọn ẹda Rẹ ni asepe, pẹlu pe; O se isipaya ọkan wọn fun awọn orisirisi ijọsin ti a n sọ ni ẹnu ni, tabi ti a n se ni isẹ, tabi ibasepọ laarin awọn eniyan.

{الْيَوْمَ أَكْمَلْتُ لَكُمْ دِينَكُمْ وَأَتْمَمْتُ عَلَيْكُمْ نِعْمَتِي وَرَضِيتُ لَكُمْ الإِسْلامَ دِينًا} [المائدة 5: 3].

Ni inu idẹra ni wiwọ ti awọn eniyan wọ inu Isilaamu ti onka wọn si ju ẹgbẹrun ni ọna ọgọrun lọ. Ni inu pipe idẹra ni pe Ọlọhun fi ẹsin Isilaamu han ni erekusu ilẹ larubawa lẹyin ti o se wipe awọn ẹsin Yahudi, Nasaara, Abọna, Oloosa ati awọn munaafiki ni wọn ti wa ni ibẹ. wo [Suratut-Taobah: 33].

{هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَى وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ وَكَفَى بِاللَّهِ شَهِيدًا} [التّوبة: 33].

Ni inu asepe idẹra Ọlọhun tun ni sise wiwọ Haram ni eewọ fun awọn keferi (alaigbagbọ), ti O si se ijọ musulumi ni ọkan. Ni inu ọla ti o wa fun mẹwa akọkọ osu Dhul-Hijjah nipe o ko ọpọlọpọ ati orisirisi awọn ijọsin si inu, gẹgẹ bi irun, saara, yiyọ saka, gbigba aawẹ, Haji, iranti Ọlọhun, adua ati bẹẹbẹẹ lọ.Ni inu ọla ti o wa fun mẹwa osu Dhul-Hijjah tun nipe oun ni oni oore julọ ni inu gbogbo ọjọ aye, isẹju rẹ, wakati rẹ, ọsan rẹ ati oru rẹ ni o ni oore, o jẹ asiko ti Ọlọhun ni ifẹsi julọ. ti Ọlọhun si ni ifẹ si awọn isẹ daada ni inu rẹ julọ. Asiko ikore ati ọla ni o jẹ, ti o si tun jẹ papa idije fun oniranran isẹ oloore. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ pe: "ko si ni inu awọn ọjọ ti Ọlọhun ni ifẹ si isẹ daada ni inu rẹ ju ọjọ mẹwa yi lọ" wọn si bi Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) wipe: jijagun si oju ọna Ọlọhun wa n kọ? O dahun pe: "jijagun si oju ọna Ọlọhun ko ni oore to, ayafi arakunrin kan ti o jade pẹlu ẹmi ati owo rẹ ti ikankan ko si baa pada si ile rẹ mọ". [Sahiah Bukhari]. Eleyi tumọ sipe isẹ daada ni inu awọn ọjọ mẹwa akọkọ Dhul-Hijjah ni oore ju jijagun si oju ọna Ọlọhun pẹlu ẹmi tabi pẹlu owo lọ.

Ni inu ọla ti o wa fun mẹwa akọkọ osu Dhul-Hijjah tun ni pe: ninu rẹ naa ni ọjọ Arafa wa, ti o jẹ ọjọ kẹsan osu Dhul-Hijjah, ọjọ naa jẹ ọjọ ti o ni oore pupọ, adua ọjọ naa si ni oore pupọ pẹlu, gẹgẹ bi Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ti wi. ọjọ yii gan an ni o tobi ju ni inu ọjọ Haji.

Ni inu ọla ti o wa fun mẹwa akọkọ osu Dhul-Hijjah tun nipe: ninu rẹ naa ni ọjọ igunran wa, tii se ọjọ kẹwa. Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) sọ pe: "ọjọ ti o ni ọla julọ ni ọjọ igunran". Ni inu ọjọ yi naa ni ọpọlọpọ isẹ Haji bọ si, gẹgẹ bi: jiju oko, fifa ori, pipa ẹran hadayah, rirọ kiri ka ile Ọlọhun ni Mọkka ati ipọsẹsẹ laarin safa ati mọriwa fun Haji, irun ọdun ati ẹran ileya, akojọpọ awọn musulumi fun ọdun naa.

Ẹyin musulumi ododo! ọla ti o wa fun awọn ọjọ mẹwa akọkọ Dhul-Hijjah yi pọ rẹpẹtẹẹ, ki a gbiyanju ati se ojukokoro isẹ daada ni inu rẹ, ki Ọlọhun se aforijin fun wa, ki O si gba isẹ daada wa.

 

(isẹju mẹẹdogun) 

الحمد لله والصّلاة والسّلام على رسول الله وبعد؛ عباد الله!

Ẹyin musulumi ododo! ni inu awọn isẹ daada ti Isilaamu se ni ẹtọ ni inu awọn ọjọ yii ni:

-         Iranti Ọlọhun, sise ẹyin fun Un, ida ọpẹ fun Un. [suratul Haji: 28].

{لِيَشْهَدُوا مَنَافِعَ لَهُمْ وَيَذْكُرُوا اسْمَ اللَّهِ فِي أَيَّامٍ مَعْلُومَاتٍ عَلَى مَا رَزَقَهُمْ مِنْ بَهِيمَةِ الأَنْعَامِ} [الحج:28].

-         Abu Huraera ati Ibn 'Umar (رضي الله عنهما) meji ni inu awọn saabe Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ti wọn tun jẹ ẹni ti o gba hadiisi wa julọ, ti wọn si maa n tẹle sunna Annabi, ni inu isesi wọn ni igbati awọn ọjọ mẹwa akọkọ Dul-Hijjah yi bati wọle nipe: wọn a maa jade lọ si ọja, ti onikaluku wọn yoo si maa wi gboloun igbe Ọlọhun tobi ni ọtọọtọ, ti awọn eniyan naa yoo si maa wi funrawọn ni ọtọọtọ.

-         Kike Al-Kuran Alapọnle, nitori wipe oun ni ọga iranti Ọlọhun.

-         Ki a lọọ mọ wipe iranti Ọlọhun ni okunfa gbogbo oriire aye ati ti ọrun.

-         Ọla ti o wa fun iranti Ọlọhun pọ pupọ. Ọlọhun paapọ pẹlu awọn orisiris awọn ijọsin gẹgẹ bi: irun [suratu an-Nisaai: 103], Jum'at [suratul Jum'at: 10], Aawẹ [suratul Baqarah: 185], Haji [suratul Baqarah 200], Jihad [suratul Anfaal: 45], Ọlọhun ko se majẹmu asiko tabi isesi fun iranti, kódà Ọlọhun pasẹ mi maa ranti Rẹ ni gbogbo ipo ti o ba wu ki a wa. [suratu an-Nisaa: 103].

{فَإِذَا قَضَيْتُمْ الصَّلاةَ فَاذْكُرُوا اللَّهَ} [النّساء: 103]، وقرنه بالجمعة فقال: {فَإِذَا قُضِيَتْ الصَّلاةُ فَانتَشِرُوا فِي الأَرْضِ وَابْتَغُوا مِنْ فَضْلِ اللَّهِ وَاذْكُرُوا اللَّهَ} [الجمعة: 10]، وقرنه بالصوم فقال: {وَلِتُكْمِلُوا الْعِدَّةَ وَلِتُكَبِّرُوا اللَّهَ عَلَى مَا هَدَاكُمْ} [البقرة: 185]، وقرنه بالحج فقال: {فَإِذَا قَضَيْتُمْ مَنَاسِكَكُمْ فَاذْكُرُوا اللَّهَ كَذِكْرِكُمْ آبَاءَكُمْ أَوْ أَشَدَّ ذِكْرًا} [البقرة: 200]، وقرنه بالجهاد فقال: {يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا إِذَا لَقِيتُمْ فِئَةً فَاثْبُتُوا وَاذْكُرُوا اللَّهَ} [الأنفال: 45]، ولا يتقيد بزمن ولا حال، أمر الله به على جميع الأحوال فقال: {فَإِذَا قَضَيْتُمْ الصَّلاةَ فَاذْكُرُوا اللَّهَ قِيَامًا وَقُعُودًا وَعَلَى جُنُوبِكُمْ} [النّساء: 103].

-         Sise Haji naa jẹ ọkan ni ara awọn isẹ ti o ni oore julọ ni inu awọn ọjọ mẹwa yii.

-         Bakannaa ni bigba aawẹ ọjọ Arafa fun awọn ti ko se Haji.

-         Yiyan nafila ni ọpọlọpọ siwaju ati ni ẹyin awọn irun ọranyan. Apapọ awọn nafila yi jẹ mejila ni ojoojumọ; raka mẹrin siwaju irun Ayila pẹlu rak'at meji ni ẹyin rẹ, raka meji ni ẹyin irun Magrib, raka meji ni ẹyin irun 'Ishai, ati rak'at meji siwaju irun Asunba. Bakannaa ni nafila asiko iyalẹta (Ad-Duhah).

-         Mi maa se saara ni ọpọlọpọ, nitori pe oore ti o wa fun saara sise pọ rẹpẹtẹ.

-         Gbigba aawẹ ọjọ mẹsan ni inu osu Dhul-Hijjah, gẹgẹ bi o ti wa ni inu Sunnah pe Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) a maa gba aawẹ ọjọ kẹẹwa osu-kini ọdun musulumi ('Ashurah), ọjọ mẹsan ni osu Dhul-Hijjah, ati ọjọ mẹta-mẹta ni aarin osu oju-ọrun kọọkan.

Ni inu sunnah ọjọ mẹwa akọkọ osu Dhul-Hijjah nipe; ẹni ti o ba da aniyan ati pa ẹran ileya, ki iru ẹni bẹẹ ma ge eekanna rẹ, ki o si ma mu nkankan ni inu irun ara rẹ ni ati igbati osu ba ti le titi yoo fi pa ẹran rẹ ni ọjọ ọdun. Sugbọn ko si laifi ki awọn ara ile ẹni ti o fẹ pa ẹran se awọn nkan ti a ka si oke un. Tori Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ki i kọ fun awọn ara ile rẹ ki wọn ge ekannan tabi mu ni inu irun wọn.

Mi maa se asalatu fun Annabi (صلّى الله عيله وسلّم) ni ọpọlọpọ ni gbogbo asiko ati aaye, paapa julọ ni inu awọn ọjọ mẹwa yi.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun ni ododo! ẹ jẹ ki a se alapantete lọ si ibi awọn isẹ rere, ki a si se oju kokoro sise wọn, ki a si ma se ko ọlẹ rara.

Ọlọhun! Fi wa se kongẹ ọrọ ati isẹ ti o ni oore julọ, nitoripe ko si ẹni ti o le fi wa se kongẹ rẹ yatọ si Iwọ Ọlọhun. Ki Ọ si muwa jinna si gbogbo nkan ti kódàra ni inu ọrọ, isẹ, iwa ati ifẹ inu, nitoripe ko si ẹni ti o le mu wa jinna sii yatọ si Iwọ Ọlọhun.

فينبغي للمسلم أن يسابق في هذه العشر بكل عمل صالح، ويكثر من الدعاء والاستغفار، ويتقرب إلى الله بكل قربة، فدونكم الفضائل فاغتنموها، وإياكم والتواني والكسل، ولنعلم أن لله جل وعلا نفحات في أيامه، فلنهتبل الفرصة ولنستكثر من الحسنات، عل الله جل وعلا أن يعفو عن زلاتنا وسيئاتنا.

اللهم وفقنا لأرشد الأقوال والأفعال لا يوفق لأرشدها إلا أنت، اللهم جنبنا سيئ الأقوال والأفعال والأهواء والأدواء لا يجنبنا سيئها إلا أنت، اللهم اهدنا وسددنا.