Awọn erongba lori Khutuba naa:
1- Sise alaye wipe Isilaamu ikilọ ni o jẹ;
2- Sise alaye itumọ ati paapa sise-ikilọ ati ọla ti o wa fun un;
3- Sise alaye ifi-ọkantanni (Al-amanat) ati ọla ti o wa fun sisọ sọ amanat;
4- Sise ikilọọ fifi ọwọ yẹpẹrẹ mu sise-ikilọ (An-nasiha) ati ifi-ọkantani (Al-amanat).
Khutubah Alakọkọ (ogun isẹju):
الحمد لله ربّ العالَمين الذي فضّل هذه الأمة على غيرها بسبب قيامهم بالأمر بالمعروف والنّهي عن المنكر، والصّلاة والسّلام على نبيّنا محمّد القائل: (الدِّين النّصيحة)، وعلى آله وصحبه ومَن تبعهم بإحسانٍ إلى يوم الدّين، وبعد؛
Gbogbo ẹrunsin Ọlọhun! Koko khutuba toni ni ọrọ nla kan ti gbogbo wa ni bukaata si, koda Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) se apejuwe rẹ wipe ohun gaan ni ẹsin, ti gbogbo awọn Annabi Ọlọhun si fi sisẹ se, ọrọ naa ni mimaa se ikilọ.
Sise ikilọ jẹ ipilẹ ẹsin ati opoitilẹ rẹ. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ wipe: "ẹsin ni sise ikilọ! ẹsin ni sise ikilọ! ẹsin ni sise ikilọ". Wọn beere wipe: fun taa ni irẹ Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم)? O dahun wipe: "fun Ọlọhun, fun Tira Rẹ, fun Ojisẹ Rẹ, fun awọn asiwaju awọn Musulumi ati apapọ gbogbo Musulumi". Mumini ti o pe ni ẹniti o se ikilọ nitori awọn nkan wọnyi.
Itumọ sise ikilọ fun Ọlọhun ni sise afọmọ ẹsin fun Un, ati iwa- ojurere Rẹ, pẹlu ki eniyan jẹ ẹru rere ti yoo maa tẹle ti Ọlọhun lọkankan ati ni kọrọ.
Itumọ sise ikilọ fun Tira Ọlọhun ni didunimọ kikee rẹ, itẹle awọn asẹ rẹ, imaa jina si awọn eewọ rẹ, gbigba awọn iro rẹ gbọ, didaabo boo kuro nibi ete awọn obilẹjẹ, nini adisọkan ti o rinlẹ pe ọrọ Ọlọhun ni Tira naa, Ọlọhun sọọ ni ọrọ, O si fi ran Jibril si Annabi (صلّى الله عليه وسلّم).
Itumọ sise ikilọ fun Ojisẹ Ọlọhun ni nini ifẹ rẹ, titẹlee ni ọkankan ati ni ikọkọ, reran an lọwọ lẹyin iku rẹ, titaari ọrọ ati oju ọna rẹ siwaju gbogbo ọrọ ati oju ọna ti o yatọ sii.
Itumọ sise ikilọ fun awọn asiwaju awọn Musulumi ni gbigba fun wọn, ati imaa tọka wọn si oju ọna oore laye ati lọrun, gbigbọ, gbigba ati sise amulo awọn ikilọ wọn lopin igbati wọn ko bati pasẹ ki a sẹ Ọlọhun,sugbọn ti wọn ba pasẹ sisẹ Ọlọhun itẹlewọn di eewọ. Eleyi ni asẹ ti Ọlọhun pawa. Wo Al-kuran; suratul Nisais 4: 59.
{ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ وَأُولِي الأمْرِ مِنْكُمْ} [النّساء 4: 59].
Itumọ sise ikilọ fun gbogbo apapọ awọn Musulumi ni ki o maa fẹ funwọn iru nkan ti o n fẹ fun ara rẹ, ki o maa la ọna oore fun wọn, ki o si maa tọka wọn si, ki o si ti gbogbo ilẹkun aburu fun wọn ati sise ikilọ rẹ fun wọn, ki o maa fi ifẹ ba wọn lo, ki o maa polongo daada wọn, ki o maa bo wọn lasiri awọn asise wọn, ki o maa ran alabosi ati ẹni a bosi ninu wọn lọwọ, ran alabosi lọwọ pẹlu ki o kaa lọwọ abosi ko, ki o ran ẹni ti wọn bosi lọwọ pẹlu ki o gbaa lọwọ alabosi.
Bi gbogbo awujọ ba ri bayi igbesi aye wọn yoo rọrun, wọn yoo si maa gbe igbesi aye alaafia.
Ninu alaye yii, a o ri wipe ikilọ ko gbogbo ẹsin sinu, ipilẹ ati ẹtuntun rẹ, awọn ẹtọ ati iwọ Ọlọhun, ati iwọ awọn ẹda Rẹ.
Gbogbo ẹniti o ba n ra iwọ Ọlọhun lare, ti o n ra amanat lare, ti o si n jamba amanat, awọn ti wọn fẹ ki iroyin ibajẹ o maa tanka, awọn ti wọn n tọpinpin ihoho Musulumi, gbogbo awọn wọnyi jin-na si sise ikilọ fun Ọlọhun, Ojisẹ Rẹ ati gbogbo Musulumi.
Awọn nkan ti oluse-i ikilọ gbọdọ se amojuto rẹ, ki o si sọọ ni igbati o ba n se ikilọ:
1- Ki ikilọ jẹ titori Ọlọhun nikan soso, ki o ma jẹ ti sekarimi , wo suratul Bayina 98: 5.
{وما أمروا إلا ليعبدوا الله مخلصين له الدين} [البيّنة 98: 5].
2- Ki olusekilọ ni imọ nipa nkan ti o fẹ kilọọ rẹ.
3- Ki olusekilọ jẹ ẹniti o ni amanat, ti o se fi ọkan tan. Wo suraul Al-'Araaf 7: 68.
{أبلغكم رسالات ربي وأنا لكم ناصح أمين} [الأعراف 7: 68].
4- Ki ikilọ naa jẹ pipamọ ni ikọkọ fun olori ati fun ọmọẹyin, sugbọn ti o ba tulasi ati se ikilọ ni gbangba ko si laifi nibẹ.
5- Ko pan dandan rara ki ẹniti yoo se ikilọ jẹ ẹniti o ni imọjulọ, tabi ki o jẹ agbalagba, tabi gbajumọ, tabi ki o duro deede ju ẹni ti o nse ikilọ fun lọ.
ولله در الإمام إسحاق بن أحمد العلثي حيث قال في مقدمة نصيحة كتبها لأخيه الإمام ابن الجوزي رحمه الله: (ولو كان لا ينكر من قل علمه على من كثر علمه إذاً لتعطل الأمر بالمعروف، وصرنا كبني إسرائيل حيث قال الله تعالى: {كانوا لا يتناهون عن منكر فعلوه}، [المائدة 5: 79]
، [suratul Maidah 5: 79].
بل ينكر المفضول على الفاضل، وينكر الفاجر على الولي، على تقدير
معرفة الولي.
Awọn Khalefa (arole) Annabi mẹrẹẹrin ati awọn asiwaju ẹsin lẹyin wọn jẹ apejuwe rere fun sise ikilọ nitori Ọlọhun. Abu Bakiri (رضي الله عنه) Arole Annabi Alakọkọ sọ wipe: "ko si oore laraawa ti a ko ba gba ikilọ, bakan naa kosi oore lara tiyin naa ti ẹ ko ba se ikilọ". 'Umar (رضي الله عنه) Arole Annabi keji naa sọwipe: "Ọlọhun ki O bami kẹ ẹnikẹni ti o bari aleebu mi ti o si fi han mi".
الحمد لله، والصّلاة والسّلام على رسول الله؛ وبعد؛ فإن الأمانة مسئولية عظيمة وعبء ثقيل على غير من خففه الله عليه، {إنا عرضنا الأمانة على السموات والأرض والجبال فأبين أن يحملنها وأشفقن منها وحملها الإنسان إنه كان ظلوما جهولا} [الأحزاب 33: 72].
Sise alaye paapa amanat, ati ọla rẹ ni inu Isilaamu. Ojuse ti o tobi ni amanat jẹ, Ọlọhun sọ wipe:
{إنا عرضنا الأمانة على السماوات والأرض والجبال فأبين أن يحملنها وأشفقن منها وحملها الإنسان إنه كان ظلوما جهولا} [الأحزاب 33: 72].
"A gbe amanat fun awọn oke ati ilẹ sugbọn wọn kọ lati tẹri sẹẹ, ọmọ eniyan ni o se aya gbangba ti wọn si gba amanat, dajudaju alabosi ati alaimọkan ni ọmọniyan jẹ". [Al-Ahzaab 33: 72].
Ohun ti n jẹ amanat ni ki eniyan dunimọ sise asepe ẹtọ Ọlọhun ati ẹtọ awọn ẹru Rẹ bi o ti tọ ati bi o ti yẹ, gẹgẹ bi o ti fẹ ki wọn pe iwọ rẹ fun ọ. Ki a mọ daju wipe Ọlọhun yoo biwa nipa amanat ti a gba, iru esi wo ni a fẹẹ fun Oluwa wa?
Amanat duro lori nkan meji: pipe amanat ati sise dọgbandọgba lasiko idajọ laarin awọn eniyan. Ki a si ma wipe ko si ibi ti amanat ko wọ. Aminu (olufọkantan) ni Imamu tabi asiwaju, alasẹ ati olori jẹ lori awọn ọmọ ẹyin rẹ, bakannaa ni ọkọ si iyawo rẹ, bẹẹ naa ni obinrin lori titọju ile ọkọ rẹ, gbogbo onikaluku ni olufọkantan (aminu) lori nkan ti o wa nikapa rẹ ati labẹ asẹ, amojuto ati aabo rẹ.
Amanat ko pin lori gba-fipamọ nikan, igi imọ Ọlọhun lọkan ni o jẹ, ti o si tun jẹ eso igbagbọ.
Amanat jẹ sise amulo ati agbedide ofin Ọlọhun lori ilẹ laarin awọn eniyan. Ọlọhun se apejuwe awọn ti wọn ni amaat wipe:
{الذين إن مكنّاهم في الأرض أقاموا الصلاة وأتوا الزكاة وأمروا بالمعروف ونهوا عن المنكر} [الحجّ 22: 41]
(Awọn ti o se wipe ti A ba gba wọn laaye lori ilẹ, wọn yoo maa gbe irun duro, wọn yoo maa yọ Zakat, wọn yoo si maa pa eniyan lasẹ daada, wọn yoo si maa kọ aida fun awọn eniyan) [Al-Hajj 22: 41].
Nipabayi, amanat ni Irun kiki jẹ, ẹnikẹni ti o ba ra irun lare, o daju wipe yo ra nkan miran naa lare. Bukhari gba ẹgbawa wipe Anas (رضي الله عنه) bu si ẹkun ni igba ti o ri bi awọn eniyan se n fi irun rare lasiko Al-Hajjaji. (Iyẹn lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ko si laye mọ).
sakat yiyọ amanat ni, ti Abu Bakir (رضي الله عنه) titori rẹ gbe ogun ti awọn ti wọn ko yọọ lasiko rẹ.
Aawẹ Rọmadan amanat ni, ẹniti o ba n gba awẹ ko gbọdọ sọrọkọrọ, koda ti wọn ba buu ki o fun wọn lesi wipe: emi n gba awẹ.
Hajji paapa amanat ni o jẹ; Ọlọhun sọ pe:
{فمن فرض فيهنّ الحجّ فلا رفث ولا فسوق ولا جدال في الحجّ} [البقرة 2: 197]. والدعوة إلى الله أمانة.
(Ẹni ti o ba n se Hajji ko gbọdọ sere tabi sọrọ ifẹ, ko gbọdọ se pooki, kosi gbọdọ jiyan ni asiko Hajji). [Al-Bakọrah 2: 197].
Ipepe si oju ọna Ọlọhun amanat ni o jẹ.
Ki a duro lori asẹ Ojisẹ Ọlọhun ati lori nini- ifẹ- rẹ amanat ni o jẹ. wo ẹda khutubah yii ni ede larubawa.
Sisọ nkan ti wọn fun ni sọ daada amanat ni. Wo suratul Yusuf 12: 54, suratul Qasas 28: 26.
(إنك اليوم لدينا مكين أمين, قال: اجعلني على خزائن الأرض إنيّ حفيظٌ عليم) [يوسف 12: 54].
وقالت ابنة شعيب: (يا أبتِ استأجره إنّ خير مَن استأجرت القويّ الأمين) [القصص 28: 26].
Amanat ni sise daada si obi ẹni, titọju owo awọn Musulumi ati sisọ ẹsin pẹlu ijẹ ọmọluabi wọn. Itan awọn mẹta ti Al-kuran sọ fun wa ni inu suratul Kahf 18: 9, ni igbati oke pade mọ wọn, ododo amanat wọn ni Oluwa fi lawọn, Akọkọ wọn jẹ alamanat (olufọkantan) lori sise itọju awọn obi rẹ mejeeji, ti ẹnikeji si jẹ alamanat (olufọkantan) lori owo alagbase rẹ, ti ẹnikẹẹta si jẹ alamanat (olufọkantan) lori sisọ ihoho ati ijẹ ọmọluabi obinrin ti kii se iyawo rẹ.
Amanat ni sisọ eti, ahan ati oju. Wo suratul Israa 17: 36
والأمانة مراقبة ٌللسمع، ومحاسبةٌ للبصر, ومتابعة للفؤاد (إن السمع والفؤاد كلّ أؤلئك كان عنه مسؤولاً) [الإسراء 17: 36]، وحبسٌ للسان عن المهالك (وهل يَكبّ الناس على مناخرهم في نار جهنّم إلاّ حصائد ألسنتهم)، (يوم تشهد عليهم ألسنتهم وأيديهم وأرجلهم بما كانوا يعملون)، ولو تأمّلتَ الثلاثة الذين هم أول من تُسعّر بهم النار لألفيتهم قد ضيعوا أماناتهم: القارئ (ليقال قارئ وقد قيل), والمتصدّق، (ليقال جواد وقد قيل)، والمجاهد (ليقال مجاهد وقد قيل). لأن المرائي لا يحتسب عمله ولا يرجو له جزاءً عند الله (نسوا الله فأنساهم أنفسهم). ولذلك كانت الخيانة علامة على النفاق (إذا حدَّث كذب، وإذا وعد أخلف وإذا اؤتُمِن خان، وإذا عاهد غدر)!.
Amanat ni sisọ imọ ati sisọ ẹgbawa rẹ, gẹgẹ bi awọn onimimọ se maa n sọ wipe: "dajudaju imọ yi i ẹsin lo jẹ, ki ẹ yaa wo ọdọ ẹniti ẹ o ti mu ẹsin yin". Ni igbati awọn ara Yamen wa ba Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) wipe ki o fun awọn ni ẹniti yoo maa kọ awọn ni Sunnah ati Isilaamu, Annabi na ọwọ Abu 'Ubaidah (رضي الله عنه) soke ti o si wipe: "eleyi ni aminu ijọ yi".
Amanat ni imaa mojuto awọn iwọ ati ẹtọ awọn Musulumi, ati imaa dide si bukata wọn ati riranwọn lọwọ.
Ise asepe isẹ ni amanat jẹ fun gbogbo awọn asẹ Al-kuran ati Sunnah, ninu jijamba amanat ni imaa bu awọn saabe Annabi (صلّى الله عليه وسلّم), imaa pe Abu Bakir ati 'Umar ni keferi gẹgẹ bii asa awọn Shiah, eleyi tako nkan ti o wa ninu aayah Al-kuran ti n se alaye bi Ọlọhun ti yọnu si wọn, ti Ojisẹ Ọlọhun naa si tun se bibu wọn leewọ fun wa.
ورسول الله صلى الله عليه وسلم يقول: (لاتسبّوا أصحابي). ورحم الله أُمَّنا عائشة رضي الله عنها حيث قالت لعروة - كما في مسلم -: (يا ابن أختي أُمروا أن يستغفروا لأصحاب النبي صلى الله عليه وسلم فسبّوهم)، وما أعظم شهادة العلاّمة السيد حسين الموسَوى في كتابه القيّم "لله ثمّ للتاريخ" حيث قال: (لو سألنا اليهود، مَن هم أفضل الناس في ملّتكم؟ لقالوا: إنهم أصحاب موسى, ولو سألنا النصارى مَن هم أفضل الناس في أمتكم؟ لقالوا: إنهم حواريو عيسى, ولو سألنا الشيعة من هم أسوء الناس في نظركم وعقيدتكم؟ لقالوا: إنهم أصحاب محمد صلى الله عليه وسلم).
Amanat ni sise deede ati dọgba, ki a si gbe onikaluku si ipo rẹ ti o lẹtọ si. Wo suratul Nisaa 4: 135.
والأمانة إنصافٌ وتجرّدٌ وأن نُنزِل الناس منازلهم ولا نَبخَسهم حقّهم كما قال الله تعالى (يا أيها الذين آمنوا كونوا قوّامين لله شُهداء بالقِسط ولا يجرمنّكم شَنَآن قومٍ على ألاّ تعدِلوا. اعدلوا هو أقرب للتقوى) [النّساء 4: 135]، وقد قالت عائشة في زينب رضي الله عنهما: (هي التي كانت تُساميني منهنّ في المنزلة عند رسول الله صلى الله عليه وسلم، ولم أرَ امرأة قطُّ خيراً في الدين من زينب, وأتقى لله وأصدق حديثاً وأوصل رحماً وأعظم صدقةً وأشد ابتذالاً لنفسها في العمل الذي تصدّقت به وتقرّبت به إلى الله تعالى، ما عدا سَوْرَةً مِن حِدّة كانت فيها، تُسرِع منها الفَيْئَة).
Amanat ni ki a ran alailagbara lọwọ, ki a ma se afiti nkan si ọdọ ẹniti ko ni ẹtọ sii, ki a ma pọn alaimọkan le, ijamba amanat ni isesi bẹẹ.
Amanat ni ijẹri fun Ọlọhun, sise ikilọ fun awọn Musulumi, ati sise afihan ododo.
Amanat ni fifi ipepe irọ silẹ, nitoripe ẹnikẹni ti o ba n fi ara rẹ han pẹlu nkan ti koni, o da gẹgẹ bi ẹni ti o wọ ẹwu irọ ni.
Ẹbẹru Ọlọhun ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ki ẹ sọ awọn amanat yin, ki ẹ ranti ọjọ kan ti owo ati ọmọ ko ni wulo.
فاتقوا الله – عباد الله – ولينصح بعضكم بعضا، فإن الدين النصيحة، ولا خير في الأمة التي لا تناصح بينها، وأدوا الأمانات إلى أهلها، واعلموا أن الله سائلكم عما استرعاكم {يوم لا ينفع مال ولا بنون إلا من أتى الله بقلب سليم} [الشّعراء 26: 88]