islamkingdomfacebook


SISE AFỌMỌ ISẸ (AL-IKHLAAS)

SISE AFỌMỌ ISẸ (AL-IKHLAAS)

6159
Eko ni soki
Ise afomo ise (Ikhlaas)je ohun ti a fe ti o ga ti gbigbe jusile re si je ewu nla,Olohun ki yio gba ise ayafi ti o ba je ise daadaa,ti o si je eyi ti a fi wa ojurere Olohun alaponle, eniyiowu ti o ba sise kan ti o wa pa nkan miran ti o yato si Olohun alekeola mo, Olohun ki yio gba ise naa botiwule ki o po to, enikeni ti o si sise kan ti o se afomo re fun Olohun oba ti ola re ga julo,Olohun yio gba a lowo re botiwule ki o kere to

 

            Awọn erongba lori khutubah naa

1          Dandan ni sise afọmọ ninu ijọsin fun Ọlọhun ti Ọla Rẹ ga julọ.

2          Alaye lori wipe Ikhlaas wa ninu awọn origun ti Ọlọhun fi ngba isẹ ẹda.

3          Alaye Patakii rẹ, ati ewu ti o wa nibi aimọ Al-Ikhlaas.  

4          Isọra ninu ohun ti o le ba sise afọmọ isẹ jẹ.

5          Alaye awọn èrè ati anfaani ti o wa ni ibẹ< class="Apple-style-span">

عباد الله : حديثنا اليوم عن أمر عظيم، أمر لا يقبل الله سبحانه وتعالى العمل بدونه، أمر به يرفع الدرجات، وينزل به الدرجات، إنه الإخلاص.

الإخلاص يا عباد الله - مطلب عظيم، وهو أحد أركان قبول العمل، فلا يقبل الله العمل إلا إذا كان عملا صالحا، وخالصا لوجهه الكريم، فمن عمل عملا أشرك فيه غير الله سبحانه وتعالى فلا يقبله الله مهما كان العمل كثيرا أو حسنا.

Al-Ikhlaas jẹ ohun ti o tobi julọ ti o jẹ ọkan ninu awọn origun ti Ọlọhun fi ma ngba isẹ lọwọ ẹda, o si jẹ ohun ti o ma ngbe ipo ẹda ti o ba nii ga, o si maa nrẹ isẹ ẹni ti ko ba nii silẹ, isẹ ti Ọlọhun ma ngba lọwọ ẹda ni eyi ti o ba ni afọmọ kuro ninu ẹbọ. Ọlọhun ko nii gba isẹ eyi ti ko ba si afọmọ ni ibẹ, kódà bi o se leèwù ki isẹ naa dara to, bi o si se wu ki isẹ naa pọ to.

Orisirisi awọn itọka lo wa ninu Al-kuran Alapọnle ti o njuwe pataki sise afọmọ isẹ. Ọlọhun Allah sọ bayii 

قال تعالى: {فادعوا الله مخلصين له الدين ولو كره الكافرون} [غافر : 14]

وقال {إنا أنزلنا إليك الكتاب بالحق فاعبد الله مخلصا له الدين. ألا لله الدين الخالص}. [الزمر : 2 – 3].

 وقال :

" pe Ọlọhun Allah lẹni ti o nse afọmọ ẹsin fun Un, kódà bi awọn alaigbagbọ ba kọ jalẹ"( surat Gaafir : 14) Allah tun sọ bayi wipe:" Dajudaju awa ni a sọ tira kalẹ fun ẹ pẹlu ododo, jọsin fun Ọlọhun pẹlu sise afọmọ ẹsin fun un, ti Oluwa ni ẹsin ti a ba se afọmọ rẹ" suratu Zumar: 2-3.

Ọpọlọpọ ọrọ Anabi Muhammad r ni o njẹri ọrọ yii, ara rẹ ni eyi ti o jẹ ki a mọ pe:

وَيُؤْتَى بِصَاحِبِ الْمَالِ، فَيَقُولُ اللَّهُ لَهُ : أَلَمْ أُوَسِّعْ عَلَيْكَ، حَتَّى لَمْ أَدَعْكَ تَحْتَاجُ إِلَى أَحَدٍ، قَالَ : بَلَى يَا رَبِّ، قَالَ : فَمَاذَا عَمِلْتَ فِيمَا آتَيْتُكَ، قَالَ كُنْتُ أَصِلُ الرَّحِمَ، وَأَتَصَدَّقُ، فَيَقُولُ اللَّهُ لَهُ : كَذَبْتَ، وَتَقُولُ لَهُ الْمَلاَئِكَةُ : كَذَبْتَ، وَيَقُولُ اللَّهُ تَعَالَى : بَلْ أَرَدْتَ أَنْ يُقَالَ فُلانٌ جَوَادٌ، فَقَدْ قِيلَ ذَاكَ. وَيُؤْتَى بِالَّذِي قُتِلَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ، فَيَقُولُ اللَّهُ لَهُ: فِي مَاذَا قُتِلْتَ؟ فَيَقُولُ أُمِرْتُ بِالْجِهَادِ فِي سَبِيلِكَ فَقَاتَلْتُ حَتَّى قُتِلْتُ، فَيَقُولُ اللَّهُ تَعَالَى لَهُ كَذَبْتَ، وَتَقُولُ لَهُ الْمَلاَئِكَةُ كَذَبْتَ، وَيَقُولُ اللَّهُ : بَلْ أَرَدْتَ أَنْ يُقَالَ فُلاَنٌ جَرِيءٌ، فَقَدْ قِيلَ ذَاكَ. ثُمَّ ضَرَبَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ عَلَى رُكْبَتِي فَقَالَ : يَا أَبَا هُرَيْرَةَ : أُولَئِكَ الثَّلاَثَةُ أَوَّلُ خَلْقِ اللَّهِ تُسَعَّرُ بِهِمُ النَّارُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ. أخرجه الترمذي. وقال : هَذَا حَدِيثٌ حَسَنٌ غَرِيبٌ.

Ẹni mẹta akọkọ ti yoo kọkọ wọ ina lọ ni ọjọ ajinde ni: ẹni ti o mọ Al kuran ke ti o si fi kọ ẹlomiran, ẹnikeji ni ẹni ti o ni owo ti o si na si oju ọna Ọlọhun Allah , ẹni kẹta ni ẹni ti o jagun si ọna ti Ọlọhun.  Sugbọn ẹni kọọkan ninu awọn ti a wi yii ko se awọn isẹ naa bi o ti dara to pẹlu sise afọmọ isẹ fun Ọlọhun Allah (Al-ikhlaas). Hadith yi ni alaafia ti o jẹ pe Tirimidhi lo gbaa wa.

Al-kuran ti o yẹ ki o sipẹ ẹni ti o kee ni ọjọ Al-kiyamọh, ko ri bẹẹ, toripe ko si Al-Ikhlaas nibẹ, olowo ko jẹ anfani owo ti o na si ọna ti Ọlọhun, tori pe ko si Al-Ikhlaas nibẹ, ẹni ti o jagun ti osi ku si ibẹ ko se oriire jihad tori pe ko si Al-ikhlaas nibẹ. O yẹ ki a yẹ ara wa ati isẹ wa wo, njẹ Al-ikhlaas wa nibẹ tabi ko si nibẹ? Ti a ko ba se akolekan Al-Ikhlaas ewu nla to tobi pupọ ni eleyii.

  • Ninu awọn ohun ti o maa nba isẹ jẹ  ni:

1.         Ẹbọ to tobi; ohun naa ni sise afiti orogun pẹlu Ọlọhun lori isẹ ti a ba nse, eleyii ma nyọ eniyan kuro ninu Isilaamu patapata, ti yoo si ba gbogbo isẹ rẹ jẹ, ti iru ẹni bẹ yoo si pẹ kanrin kese ninu ina.

2.         Ẹbọ kekere: ohun naa ni gbobgo ọrọ tabi isẹ ti Sariaah Isilaamu pe ni ẹbọ; sugbọn ti ko mu eniyan jade kuro ninu Isilaamu, gẹgẹ bi asehan tabi sise karimi, o maa nba isẹ jẹ, ni tori pe ko si Al-ikhlaas ni ibẹ . Annọbi r sọ bayii pe:

فعَنْ مَحْمُودِ بْنِ لَبِيدٍ أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ : إِنَّ أَخْوَفَ مَا أَخَافُ عَلَيْكُمْ الشِّرْكُ الأَصْغَرُ قَالُوا : وَمَا الشِّرْكُ الأَصْغَرُ يَا رَسُولَ اللَّهِ؟ قَالَ : الرِّيَاءُ، يَقُولُ اللَّهُ عَزَّ وَجَلَّ لَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ إِذَا جُزِيَ النَّاسُ بِأَعْمَالِهِمْ، اذْهَبُوا إِلَى الَّذِينَ كُنْتُمْ تُرَاءُونَ فِي الدُّنْيَا، فَانْظُرُوا هَلْ تَجِدُونَ عِنْدَهُمْ جَزَاءً" أخرجه أحمد.

bọ kekere ni ohun ti mo nbẹru julọ fun un yin, wọn si bere wipe kini ẹbọ kekere irẹ Ojisẹ Ọlọhun? o sisọ pe: se karimi ni. Ọlọhun yoo sọ fun awọn ti wọn ba nsee ni ọjọ ikẹhin nigba ti onikaluku ba gba ẹsan isẹ rẹ pe: ẹyin, ẹ lọọ ba awọn ti ẹ nse asehan fun laye, njẹ ẹ ri ẹsan kankan lọdọ wọn bi? (Ahmad lo gba Hadith yii wa).

1.         Ti eniyan ba nwa aye pẹlu awọn isẹ ọrun, ti o nfi awọn isẹ laada ti a o gba ẹsan rẹ lọrun wa anfani aye ati adun rẹ, eleyii na ma nba isẹ jẹ fun ẹda, nitori ko si Al-ikhlaas nibẹ.

2.         Itẹle ifẹ inu: ti eniyan ba se isẹ ọrun kan, ti ọ jẹ pe ifẹ inu lo mu un se isẹ naa, bi isẹ itẹle asẹ Ọlọhun tabi ijinna si ohun ti Ọlọhun se ni eewọ, eleyii le ba isẹ naa jẹ, tori aisi Al-ikhlaas nibẹ. Bakanna ni ijọra-ẹni-loju, motómotó, ati girimọnkai lori isẹ ọrun le baa jẹ, tori aisi Al-ikhlaas nibẹ.

Sugbọn ti eniyan ba nfi isẹ ọrun wa Aljannah Ọlọhun ati lila kuro ninu  ina Ọlọhun, eleyii ko ba isẹ eniyan jẹ o. Ti awọn eniyan ba nyin Musulumi latari isẹ ti o ba se, ti kii se pe ohun se isẹ yẹn ni tori ki awọn eniyan fi le yin in, ko ba isẹ rẹ jẹ o. Bakanna bi eniyan ba lọ se ise Haji nitori ti Ọlọhun, ti o si ra ọja ti yoo se anfani nibẹ bọwa si ile, eleyii ko ba isẹ rẹ jẹ, bakanna ẹni ti o ba gba aawẹ lati fi wa ojurere Ọlọhun, afọrijin ati isunmọ Ọlọhun, ko si àáyẹ tabi laifi nibẹ.


 

 

 

Ẹniti o ba n se Al-Ikhlaas yoo wọ Aljanah Ọlọhun, yoo si la kuro ninu ina, yoo jẹ ki Ọlọhun gba isẹ rẹ, yoo si tun fun un ni ẹsan àdìpèlé, sise alabapade amojukuro Ọlọhun, jijẹ èrè pẹlu isipẹ Annabi Muhammad, riri igbadun, jijẹ ẹru ti n jọsin fun Ọlọhun, riri ifọkanbalẹ ati itọsọna laye yii, ibanujẹ yoo jinna si ẹni ti o ba ni Ikhlaas, iru ẹni bẹẹ yoo si la kuro ninu ọgbọn arekereke shaitọn (Esu), ọkan iru ẹni bẹẹ yoo mọ kuro ninu idọti- motómotó, Ijọra ẹni loju ati  keeta.

O Pataki lati maa se adua ti Annabi kọ awa ijọọrẹ ti a kofi ni bọ si inu ẹbọ kekere tabi ẹbọninla.

Ẹni ti o ba fẹ se oriire lọrun, ti o si fẹ gba lada isẹ rẹ lagbape, ti ko si fẹ wọ ina ni ọjọ ajinde; ki o yara se isẹ eyi ti yoo mu un jinna si ẹbọ, ti yoo si ni Al-ikhlaas ninu.

Ki Oluwa se Al-ikhlaas fun wa ninu ọrọ ati isẹ wa aamin.

اللهم إني أعوذ بك أن أشرك بك و أنا أعلم، و أستغفرك لما لا أعلم".  اللهم ارزقنا الإخلاص في القول والعمل.

أيها المسلمون : هذا، واعلموا رحمني الله وإياكم أن الله جل جلاله أمرنا بالصلاة على نبيه وقال جل وعلا قولاً كريماً: إن الله وملائكته يصلون على النبي يا أيها الذين آمنوا صلوا عليه وسلموا تسليماً [الأحزاب:56].

اللّهُمَّ أَعِزَّ الإسْلاَمَ وَالْمُسْلِمِينَ، وَدَمِّر أَعَدَاءَكَ أَعَدَاءَ الدِّينِ، وَانْصُرْ عِبَادَكَ الْمُوَحِّدِينَ، اللّهُمَّ عَلَيْكَ بِالْكَفَرَةِ الْفَجَرَةِ فَإِنَّهُمْ لاَ يُعْجِزُونَكَ يَارَبَّ الْعَالَمِينَ.

رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَدَابَ النَّارِ.