islamkingdomfacebook


TITẸLE SUNNNAH ANỌBI MUHAMMAD

TITẸLE SUNNNAH ANỌBI MUHAMMAD

21850
Eko ni soki
Taani ninu wa ti ko nife ojise Olohun (Ki ike ati ola Olohun maa baa)? Niti amodaju, kosi enikankan ti ko nife re, nje olukuluku wa ni o je olododo nibi apemora re? Dajusaka, ipe apemora ife anabi(Ki ike ati ola Olohun maa baa) je ohun ti o rorun fun gbogbo eniyan, sugbon, kinni apere ijododo ipepe yi? Laisi tabisugbon, itele anabi ni, itele isesi anabi Muhammad(Ki ike ati ola Olohun maa baa) ati iteramoo, lodiwon idunnumo isesi re lodo re ni yio je odiwon ododo ipepe re.

Awọn erongba lori Khutubah naa:

1.      Alaye papa ifẹ Annabi Muhammad ki ike ati ola Olohun maa baa

2.      Alaye wipe Ọlọhun koni gba Ijọsin lọwọ ẹda ayafi eyi ti o ba se dede SunnahAnabi Muhammad r .

3.      Alaye itumọ ijẹri pe Annabi Muhammad jẹ ọjisẹ Ọlọhun naa ni ki a tẹle Ilana rẹ patapata ninu ijọsin.

4.      Alaye awọn anfani ti o wa ninu itẹramọ sunnah Annabi Muhammad r

عباد الله ، من منا لا يحب رسول الله صلى الله عليه وسلم؟

من منا لا يحب ما يحبه ومن يحبه رسول الله صلى الله عليه وسلم؟

من منا لا يرجو معية رسول الله صلى الله عليه وسلم في الآخرة ؟

من منا لا يرجو شفاعة المصطفى صلى الله عليه وسلم ؟

كلنا ذلك الرجل الساعي لإحراز القرب من رسول الله صلى الله عليه وسلم ونيل شفاته يوم القيامة، والتقرب إلى الله بمحبته ، لكن ما هو السبيل لذلك ، وما هي الطريق الموصلة إلى تحصيل هذه المطالب ؟

إنها طريق واحدة، وسبيل واحد لا ثاني له، ألا إنه لزوم طاعته صلى الله عليه وسلم ،فحب رسول الله صلى الله عليه وسلم أوجبه اللهُ الذي بعثه بالهدى ودين الحق ، فلا إيمان لمن لا يحبه ... وأول علامات الصدق في محبته طاعته واتباع سنته.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun! Tani ẹni naa ninu wa ti ko fẹran Annabi Muhammad r?  Tani ẹni naa ninu wa ti ko fẹran ohun ti Anabi fẹ ati awọn ti Annabi Muhammad nifẹ r ? Tani ẹni naa ninu wa ti ko nifẹ lati wa lẹgbẹ Annabi Muhammad r ni ọjọ Al-kiyamah? Tani ẹni na ninu wa ti ko nifẹ isipẹ Annabi Muhammad r ? Gbogbo wa ni  a n fẹ sunmọ Annabi lọjọ ẹsan, ọna wo ni a o tọ de ibẹ?

Ọna kan soso ni a o fi ni anfaani awọn nkan wọnyi, oun naa ni: ki a tẹra mọ Sunnah Annabi Muhammad r , ki a si ni ifẹ Annabi, tori pe dandan ni ifẹ Annabi jẹ fun gbogbo ẹni ti o ba gba Ọlọhun gbọ. Ko si igbagbọ (Iman) fun ẹni ti ko ba ni ifẹ Annabi Muhammad r. Ọlọhun sọ wipe:

وقال : {يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا أَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ وَلَا تُبْطِلُوا أَعْمَالَكُمْ} وقال : وقال : {وَأَطِيعُواْ اللّهَ وَالرَّسُولَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ}... وقال : {قُلْ إِن كُنتُمْ تُحِبُّونَ اللّهَ فَاتَّبِعُونِي يُحْبِبْكُمُ اللّهُ وَيَغْفِرْ لَكُمْ ذُنُوبَكُمْ وَاللّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ}.

"Ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun gbọ, ẹ tẹle ti Ọlọhun ati Annabi, ki ẹ ma se ba isẹ yin jẹ (Surat Muhammad 47:33) "  Ọlọhun tun sọ wipe:  "Ẹyin ti ẹ gba Ọlọhun gbọ, ẹ tele ti –Ọlọhun ati ti ọjisẹ Rẹ!! (Surat Nisai 59) ". Ọlọhun tun sọ wipe: sọ (fun wọn) pe ti ẹ ba fẹran Ọlọhun ki ẹ tele ti emi Annabi Ọlọhun yo fẹran yin yoo si fi ori awọn ẹsẹ yin jin yin, Ọlọhun ni ọba Alaforijin onikẹ (Al-Imaran:31). Ọlọhun tun sọ wipe: "Ko lẹtọ fun ẹni ti ọ gba Ọlọhun gbọ lọkunrin ati lobinrin ki o ni ki o ni ọhun miran lati se lẹhin ti Ọlọhun ati Annabi Rẹ ba ti pasẹ , ẹni ba sẹ Ọlọhun ati Annabi Rẹ ti sọnu gidigidi" (Surat Ahzaab: 36)

Iribadu ọmọ Saariyah t sọ wipe:

عن العرباض بن سارية رضي الله عنه قال : وعظنا رسول الله صلى الله عليه وسلم موعظة وجلت منها القلوب وذرفت منها العيون فقلنا يا رسول الله كأنها موعظة مودع فأوصنا قال :

أوصيكم بتقوى الله والسمع والطاعة وإن تأمر عليكم عبد وإنه من يعش منكم فسيرى اختلافا كثيرا فعليكم بسنتي وسنة الخلفاء الراشدين المهديين عضوا عليها بالنواجذ وإياكم ومحدثات الأمور فإن كل بدعة ضلالة)

Annabi Muhammad r  se waasi fun wa, waasi ti o jẹ ki ọkan wa gbọn riri, ti o si jẹ ki omi jade loju wa. A sọ fun Annabi pe isiti yi jọ ti idagbere, tori naa sọ asọọlẹ fun wa. Annabi sọ wipe: Mo nsọ asọọlẹ aaya Ọlọhun fun yin, bakannaa ki ẹ si gbọ ọrọ Ọlọhun ni agbọtẹle kódà bi o jẹ pe ẹru ni wọn fi jẹ ọga leyin lori. Amọsa ẹni ti ẹmi rẹ ba gun ninu yin yoo ri ọrisirisi iyapa ẹnu (àìsedédé) torinaa, o di ọwọ yin lati tẹle Sunna emi Annabi ati ti awọn arole lẹhin mi ti wọn mọ ọna, ẹ gbá ohun ti wọn ba se mu gidigidi, ki ẹ si sọra fun  adaadalẹ (bida'h); tori pe gbogbo adaadalẹ (bida') ọna anu ni ".

Abu Hurayrah ki Ọlọhun yọnu si sọ bayi pe: Annabi Muhammad r  sọ pe:

عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه و سلم قال : ( كل أمتي يدخلون الجنة إلا من أبى ) قالوا : ومن يأبى ؟ قال : ( من أطاعني دخل الجنة ومن عصاني فقد أبى ) . أخرجه البخاري.

“Gbogbo ijọ emi Annabi ni yoo wọ Al-jannah, ayafi ẹni ti ọ ba kọ! Wọn bere pe: tani yoo ko lati wọ Al-Jannah? Annabi sọ pe:

 “Ẹni ti o ba tẹle temi Annabi yoo wọ Al-Jannah, nigba ti ẹni ti ko ba tẹle temi Annabi kọ lati wọ Al-jannah. (Bukhari lo mu Hadith naa jade)

Bayi ni o se jẹ dandan ki a tẹle ọrọ, ise ati ilana Annabi Muhammad r ninu gbogbo isesi wa. Umar bin Khattab t sọ bayi nigba ti o fẹ pọn okuta Hajarul Asiwadi la ni Mọkka:

وعن عابس بن ربيعة قال : رأيت عمر بن الخطاب رضي الله عنه يقبل الحجر يعني الأسود ويقول : (إني لأعلم أنك حجر لا تنفع ولا تضر، ولولا أني رأيت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقبلك ما قبلتك ) رواه البخاري

"Emi mọ wipe okuta lasan ni ẹ, ko si inira ti o le se fun mi bẹẹ ni ko si anfaani kan ti o le da se pẹlu, bi kii ba se pe mo ri (Annabi)" ojisẹ Ọlọhun r  ti o npọn ọ la ni mi ki ba ti se bẹẹ” Bukhari logba wa.

Ọpọlọpọ isẹlẹ  ati iyapa, ọpọlọpọ àìsedédé ati darudapọ ni yoo maa sẹlẹ, nigbati ọna abayọ jẹ itẹle sunnah Annabi Muhammad r . Musulumi gbọdọ dimọ sunnah Annabi, ki o si mu dani sinsin ti a ba se eleyi a o ri awọn orisirisi anfani ti o pọ. Lara rẹ ni iwọn yii:

1-                 Itẹle sunnah jẹ Isọ ti Musulumi ko fi ni ko sinu panpẹ iyapa ẹnu ti ko

dara, ti o le mu eniyan jinna si ẹsin Ọlọhun.

2-                 Itẹle sunnah jẹ ọlá ati ọlà ti Musulumi ko fi ni jẹ ọkan ninu awọn ti wọn

kii se Musulumi. Annabi Muhammad r sọ wipe:

قال: رسول الله صلى الله عليه وسلم "إن بني إسرائيل افترقت على إحدى وسبعين فرقة وإن أمتي ستفترق على اثنين وسبعين فرقة كلها في النار إلا واحدة وهي الجماعة " .

"Dajudaju awọn ọmọ Isirẹli pin si ọna mọkanlelaadọrin (71), awọn ijọ emi Annabi yoo pin si ọna metalelaadọrin (73), gbogbo won ni yoo wọ ina ayafi ẹyọ kan; oun naa ni Jamah- apapọ Musulumi" Hadith yi ati awọn ti o tun ri bẹẹ ntọka si wipe idunnimọ sunnah Annabi ni yoo la wa kuro ninu ijọ ti Ọlọhun ko fẹ, ti o si se adehun ina fun un.

3-                 Itẹle Sunnah pẹlu idunnimọ ni yoo jẹ imọna kuro ni ọna anu. Annabi r sọ

pe:                                                  

عن أبي هريرة رضي الله عنه قال : قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : "إني قد تركت فيكم شيئين لن تضلوا بعدهما كتاب الله وسنتي ولن يتفرقا حتى يرد عليَّ الحوض" أخرجه الحاكم والدارقطني والبيهقي.        

“Dajudaju mo fi nkan meji silẹ fun yin, ẹyin ko ni sọnu ti ẹ ba mu mejeeji dani daradara; tira Ọlọhun ati Sunnah  emi  Annabi, ẹyin ko si ni yapa titi ti a o fi pade ni abata Al-Jannah " (Haakim, Daaru kutni ati Baehaki lo gbaa wa). Hadith yi njẹ ìró idunu fun ẹni ti o ba tẹle Sunnah Annabi  r  ti o si mu lọwọ dada pe yoo wa ninu awọn ti yoo mu ninu omi amusẹmi pẹlu Annabi r ni ọjọ Al-kiyaamọ.

Imam Malik    رحمه اللهsọ wipe:

قال مالك رحمه الله: "السنة مثل سفينة نوح من ركبها نجا ومن تخلف عنها هلك".

 "Sunnah Annabi Muhammad da gẹgẹ bi ọkọ oju omi Annabi Nuh u, ẹni ba wọ inu rẹ ti la, ẹni ti ko ba wọ inu rẹ ti parẹ.

4-                 Ẹni ba tẹle Sunnah ti jẹ ọmọ lẹhin Annabi, ẹni ba fi sunnah silẹ ti jade  

kuro ninu ọmọlẹhin rẹ. Ninu Hadith ti Bukhari ati Musilimu gba wa Anas t sọ wipe:

أخرج الشيخان واللفظ للبخاري عن أنس بن مالك رضي الله عنه يقول : جاء ثلاثة رهط إلى بيوت أزواج النبي صلى الله عليه وسلم يسألون عن عبادة النبي صلى الله عليه وسلم فلما أخبروا كأنهم تقالوها، فقالوا أين نحن من النبي صلى الله عليه وسلم قد غفر له ما تقدم من ذنبه وما تأخر ، قال أحدهم : أما أنا فإني أصلي الليل أبداً وقال آخر : أنا أصوم الدهر ولا أفطر ، وقال آخر : أنا أعتزل النساء فلا أتزوج أبداً  فجاء رسول الله صلى الله عليه وسلم إليهم فقال : أنتم الذين قلتم كذا وكذا أما والله إني لأخشاكم لله واتقاكم له لكني أصوم وأفطر وأصلي وأرقد وأتزوج النساء فمن رغب عن سنتي فليس مني ".

“Awọn ẹni mẹta kan wa si ilé Annabi lati beere gẹgẹ bi Annabi se njọsin fun Ọlọhun, ni igba ti wọn gbọ alaye bi Anabi se njọsin fun Ọlọhun, wọn ro wipe okere, wọn si sọ wipe njẹ a le fi ara we Annabi bi? Dajudaju Ọlọhun ti fi ori ẹsẹ ti Annabi ti sẹ ati eyi ti yoo sẹ jin in, Alakọkọ sọ wipe: ẹmi yoo maa fi gbogbo òru mi jọsin fun Ọlọhun laini oju oorun, ẹnikeji sọ wipe: emi yoo ma gba aawẹ, ni gbogbo ọjọ aye mi. Nigba ti ẹni kẹta si sọ wipe: Emi ko ni fẹ iyawo! ni igba ti Annabi de o si bere wipe: Se ẹyin ni ẹ sọ bayi bayi? Ki ẹ lọ mọ wipe emi ni mo paya Ọlọhun ju yin lọ, sugbọn ti mo ba gba awẹ, mo ma nsinu (mo ma nsinmin fun awẹ ni igba miran), mo ma nse nafila lóru, mo si ma n sun pẹlu, bakanaa mo si fẹ awọn iyawo, ẹni ti o ba kọ ẹyin si sunnah emi Annabi, koni si ninu ijọ mi.

 

إذا تركتها إعراضاً عنها وإنكاراً لها وانتقاصاً لها فأنت انتقصت الدين وانتقاص الدين نوع من الكفر والإعراض عن الدين نوع من أنواع الكفر والعياذ بالله.

أما إذا تركت السنة تهاوناً وكسلاً لا عن اعتقاد القصور فيها واعتقاد النقص فيها، فأنت بحسب هذه السنة التي تركتها إن تركت واجباً فأنت عليك إثم الواجب وإن تركت مستحباً فأنت قد فاتك فضل المستحب.

Ẹniti o ba fi sunnah silẹ ni ti ikorira  tabi ni ti atako, iru ẹni bẹ ti din nkan ku ninu ẹsin, ẹni ti o ba nyọ nkan kuro ninu ẹsin ti nse keferi si Ọlọhun Ẹlẹda rẹ.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ẹni ti o ba fi sunnah silẹ latari oroju, iru ẹni bẹẹ ti da ẹsẹ ti o ba jẹ sunnah ọranyan tabi ki iru ẹni bẹ padanu laada ti o tobi ti o ba jẹ sunnah ti a fẹ ki a se (yatọ si ọranyan). Ninu ọla ti o wa fun sunnah ni wipe, o ma nyọ eniyan kuro lẹhin Saitọn. Ibn Mas'ud ki Ọlọhun yọnu si sọ wipe.

عن ابن مسعود رضي الله عنه قال : (خط لنا رسول الله صلى الله عليه وسلم خطاً فقال : هذا سبيل الله ثم خط خطوطاً عن شماله وعن يمينه ثم خط خطوطاً صغيرة عن شمال هذا الخط  وعن يمينه ثم قال رسول الله صلى الله عليه وسلم : هذا سبيلي أشار إلى الخط الطويل وقال : هذا سبيلي وهذه سبل على كل سبيل منها شيطان يدعوا إليه ثم تلا { وَأَنّ هَذَا صِرَاطِي مُسْتَقِيماً فَاتّبِعُوهُ وَلاَ تَتّبِعُوا السّبُلَ فَتَفَرّقَ بِكُمْ عَن سَبِيلِهِ ذَلِكُمْ وَصّاكُمْ بِهِ لَعَلّكُمْ  تَتّقُونَ }

“Annabi Muhammad  r  fa ila kan fun wa; o si sọ wipe eleyi ni oju ọna Ọlọhun, lẹhin naa o si fa ila miran si ọtun ati osi, o si tun fa ila keekeeke miran si ọtun ati osi bakanna. Lẹhin naa ni Annabi sọ wipe: Eleyi ni ọna ti emi Annabi ti o si tọka si ila ti o gun yẹn, o tun sọ wipe: eleyi ni ọna mi, awọn ọna ti o sẹku wọnyin ni ti Saitọn ti o si ma npepe si. Lẹhin eleyi ni o wa ke Aayah ti o sọ pe: " eleyi ni ọna mi ti o lọ taara; oun ni ki ẹ tẹle, ẹ ma se tẹle awọn ọna miran ki ẹ ẹsin ma wa pin si yẹlẹyẹlẹ mọ yin lọwọ, eleyi ni asọsilẹ fun yin in, ki ẹ le jẹ ẹni ti yoo paya Ọlọhun.

Ibn Taimiyah رحمه الله sọ wipe:

قال ابن تيمية رحمه الله: "وعامة هذه الضلالات إنما تطرق من لم يعتصم بالكتاب والسنة كما  كان الزهري يقول: كان علماؤنا يقولون الاعتصام بالسنة هو النجاة.

“Ọpọlọpọ awọn ti wọn sọnu se bẹẹ nitori aidirọ mọ Al-Qur'aan ati sunnah Annabi Muhammad r . Alfa Zuhri ma nsọ wipe: "Awọn alfa wa ma n kiwa nilọ wipe ki a gba sunnah mu gidigidi ohun ni eniyan fi le jere".

5-        Ẹni ti o ba tẹle sunnah ni yoo maa lo ofin Ọlọhun, ti yoo si maa jọsin fun Ọlọhun pẹlu, ẹni ti o ba tẹle sunnah yoo gbagbọ pe ijọsin ohun ti a ko le da se ni; Sugbọn a o ma se gẹgẹ bi Ọlọhun se la kalẹ fun wa ni. Annabi Muhammad r se aluwala lọjọ kan o si sọ wipe:

توضأ رسول الله صلى الله عليه وسلم وقال : " هذا وضوئي ووضوء الأنبياء من قبلي، فمن زاد أو أنقص فقد أساء وظلم" .

وصلى رسول الله صلى الله عليه وسلم، وهو الذي قال: "صلوا كما رأيتموني أصلي"!

“Eleyi ni aluwala temi ati aluwala awọn Annabi Ọlọhun ti o ti re kọja siwaju mi, ẹni ba se alekun tabi iyọkuro ti huwa buburu, o si ti se abosi bakanaa. Annabi tun sọ wipe: "Ẹ ki irun gẹgẹ bi ẹ ti se ri ti emi Annabi n kirun" bayi ni ẹni ti o nse sunnah yoo se maa se ẹsin rẹ ni ibamu pẹlu ohun ti Ọlọhun ati Annabi rẹ sọ.

6-        Ẹni ba n se sunnah ni ongbe ẹsin ga ti o si nrẹ bidi'ah satani nilẹ. Igba yoowu ti a ba ntẹle sunnah iyi ati apọnle ni eleyi jẹ fun Musulumi tori pe a nse igbọran si Ọlọhun ati Annabi rẹ ni. Annabi Muhammad r  sọ wipe:

ابن عمر قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول : " إذا تبايعتم بالعينة وأخذتم أذناب البقر ورضيتم بالزرع وتركتم الجهاد سلط الله عليكم ذلاً لا ينزعه حتى ترجعوا إلى دينكم" والعودة إلى السنة عودة إلى الدين .

" Ti ẹ ba gbe gbogbo ọkan yin le tita a ti ati rira, bakanaa ti ẹ ba n se akolekan awọn ohun ọrọ oloowoyebiye ati awọn ohun ere oko, ti ẹ si fi jihad kalẹ ti ẹ ko ya si, Oluwa yoo dẹ iyẹpẹrẹ si yin ti ko nii ya pẹlu yin titi ti ẹ o fi pada si ibi ẹsin yin." Ipada si sunnah ni ipada si ẹsin.

فهل نتعلم الدين بدون أن نتعلم كيف نصلي ؟!

هل نتعلم الدين من غير أن نتعلم الطهارة التي هي مفتاح الصلاة؟!

هل نتعلم الدين من غير أن نعلم نساءنا وبناتنا وحريمنا أحكام الحيض وأحكام النفاس وهي أمور تمر عليهم دائماً؟ هل نكون تعلمنا الدين بغير ذلك؟ هل نتعلم الدين ونحن لا نعرف نعبد الله على الطريقة التي تقول: إن صلاتي أنا كما صلاها الرسول صلى الله عليه وسلم، حجي أنا كما حج الرسول صلى الله عليه وسلم، صومي أنا كما صام الرسول صلى الله عليه وسلم؟ هل عرفنا الدين؟! إذاً من ثمرات اتباع السنة ومن فضل اتباع السنة أن فيها رفع سمة الذل والهوان عن المسلمين.

Ti a ba nkọ ara wa ni imọra, aluwala, irun kiki, ti a si nkọ awọn ọbinrin ni idajọ ẹsin awọn ọbinrin gẹgẹ bi ẹjẹ nkan osu ati ti ibimọ, ti a si nkirun gẹgẹ bi Annabi se nkirun, ti a se Haji gẹgẹ bi Annabi se se Haji, ti a si ngba awẹ gẹgẹ bi Annabi se ngba awẹ, dajudaju eleyi yoo jẹ apọnle ati iyi fun Musulumi.

7-        Itẹle sunnah ni yoo jẹ ki a mọ arun tin se wa ati iru ogun ti a le lo si. Annabi Muhammadr  sọ wipe:

" Ẹyin Musulumi laipẹ ni awọn ọta yoo pe bo yin gẹgẹ bi awọn eniyan se ma npe bo ọpọn onjẹ, ẹni kan si bere wipe: se onka (awa Musulumi) yoo kere ni ọjọ naa bi? Annabi sọ wipe:" ẹyin yoo pọ ni akoko na gẹgẹ bi pipọ koriko, awọn ọta yin ko ni bẹru yin mọ lọjọ naa, ikọlẹ yoo si wọ inu ọkan yin, ẹnikan si bere pe : kini a npe ni ikọlẹ? Annabi sọ wipe: ohun ni ifẹ aye ati ikorira iku" Ahmad ati Abu Daud lo gba Hadith yi wa. "

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ẹyin ko wa ri bi Musulumi se lẹ to loni? Ti awọn Ijọba Amunisin si jẹ gàba lewọn lori ni gbogbo ilu kaakiri, ti onka wa ko si kere. Oogun ti Annabi fẹ ki a fi tọju arun yi ni ki a ma jẹ ki ifẹ aye gbe wa lọ, ki a si ma se korira iku, tori ohun ni yoo gbẹhin gbogbo wa. Tori naa, sunnah ni o le mu ni mọ pataki irú arun yi, ati oogun yi ti a le se pẹlu.

8-        Sunnah ni o nkọ wa ni iwa daradara. Annabi Muhammad r sọ wipe : "

أخرج أحمد عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ قَالَ : قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: (إِنَّمَا بُعِثْتُ لِأُتَمِّمَ صَالِح الْأَخْلَاق)

"Oluwa gbe emi Annabi dide lati wa pe awọn iwa daradara fun yin" Awọn iwa daradara wọnyi jẹ ohun ti sunnah se akolekan rẹ, ara anfani sunnah ni pe a o ni iwa daradara lati fi jọ Annabi wa Muhammad r  ẹni ti Ọlọhun fi iwa  daradara royin rẹ.

9-        Itẹra mọ sunnah ni o le jẹ ki a se orire, ki a si la kuro ni nu fitinah ati iya ẹlẹta elero. Ọlọhun sọ wipe:

{فَلْيَحْذَرْ الَّذِينَ يُخَالِفُونَ عَنْ أَمْرِهِ أَنْ تُصِيبَهُمْ فِتْنَةٌ أَوْ يُصِيبَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ

تصيبهم فتنة فيدخل الكفر في قلوبهم أو النفاق في قلوبهم أو يدخلوا في البدع فيلحقهم بذلك عذاب أليم! فمن فضل اتباع سنة الرسول أنها تحفظك من الفتنة .

 "Ki awọn ti wọn nyapa asẹ rẹ (Annabi) sọra ki fitinah ma bawọn, ki wọn si le ma ba tọ si iya ẹlẹta ẹlero." Fitinah ti yoo ba wọn ni kikọ ti Ọlọhun silẹ, ti yoo wa ni ọkan wọn (Kufur) tabi aiduro deede (Nifaaqh) tabi fifi nkan kun ẹsin (Bid'ah) ti ikọọkan ninu awọn nkan wọn yi yoo sọ wọn di ẹni ti yoo wọ ina, ẹni ti o ba ntẹle sunnah yoo la ninu iru isoro bayi.

وثق أنك إذا ما مشيت على هذا فصلحت نفسك وأصلحت أهلك وأسرتك وصلاح النفس صلاح الأسرة .

وصلاح الأسرة صلاح المجتمع ... وصلاح المجتمع صلاح المدينة ... وصلاح المدينة صلاح الدولة ..وصلاح الدولة صلاح الأمة ...وصلاح الأمة صلاح الكون جميعه بإذن الله؛ فأحرص وأبدا بنفسك ثم أدناك فأدناك، واعلم أن السنة هي الطريق ، واتباع هو الكفيل لتحقيق كل ذلك ... .

Ti o ba ntẹle ilana Annabi fi ọkan balẹ wipe o nse atunse ẹmi rẹ niyẹn ati awọn ara ile rẹ, ati gbogbo eniyan lapapọ, ti ẹbi ba dara awujọ yoo dara, ti awujọ ba dara, ilu yoo dara, ti ilu ba dara, orilẹ ede yoo dara, ti orilẹ ede ba dara gbogbo aye yoo dara. Lọọ mọ wipe sunnah ni oju ọna, itẹle oju ọna naa ni a o fi se oriire.

هذا، قال الله تعالى : "إن الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى عن الفحشاء والمنكر والبغي يعظكم لعلكم تذكرون  "

اللَّهُمَّ لاَ تَدَعْ لَنَا فِي مَقَامِنَا هَذَا ذَنْبًا إِلاَّ غَفَرْتَه، وَلاَ دَيْناً إِلاَّ قَضَيْتَه، وَلاَ مَرِيضاً إِلاَّ شَفَيْتَه، وَلاَ مُسَفِّراً إِلاَّ رَجَعْتَه وَلاَ ضَالاً إِلاَّ هَدَيْتَه وَلاَ دَاعِيًا فِي سَبِيلِكَ إِلاَّ  وَفَقْتَه، وَلاَ حَاجَتًا مِنْ حَوَائِجِ الدُّنْيَا وَالآخِرَةِ هِيَ لَكَ فِيهَا رِضَا وَلَنَا فِيهَا صَلاَح إِلاَّ قَضَيْتَهَا وَيَسَّرْتَهَا لَنَا يَا رَبِّ الْعَالَمِينَ.

رَبَّنا هَبْ لَنَا مِنْ لَدُنْكَ رَحْمَةً وَهَيِّئ لَنَا مِنْ أَمْرِنَا رَشَدَا. رَبَّنَا هَبْ لَنَا مِنْ أَزْوَاجِنَا وَذُرِيَاتِنَا قُرَةً أَعْيُنِ وَجَعَلْنَا لِلْمُتَقِينَ إِمَامًا.

رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَدَابَ النَّارِ.