islamkingdomfacebook


SISE DÁÀDA SI AWỌN ÒBÍ MEJEEJI ATI WIWANI NISỌRA NIBI SẸYÁSẸBABA

SISE DÁÀDA SI AWỌN ÒBÍ MEJEEJI ATI WIWANI NISỌRA NIBI SẸYÁSẸBABA

4824
Eko ni soki
Iwo awon obi mejeeji je ohun ti o si nseku, atipe ibalopo won pelu daadaa je oranyan, koda bi awon mejeeji ba je keeferi, A ko se ise daadaa si won ni adanyanri pe ki won je musulumi, bikosepe, daadaa sise siwon je dandan koda bi won ba je keeferi.Dajudaju, Esin Islam ti kiwalilo nibi iyapa awon mejeeji ni ikilo ti o lagbara, O si se iyapa obi mejeeji ni okan ninu awon ese nla kabairi leyin ebo sise si Olohun Oba ti ola re ga, paapaa julo, Islam gbola fun isiboisin awon obi lori ijakun si ojuona Olohun ti ola re ga eleyi ti oje asonso iwaju Islam..

Awọn erongba Khutuba

1.         Pipanilasẹ ibẹru Ọlọhun to ga julọ ati sise dada sobi mejeeji

2.         Pipanilasẹ bíbáwọnlòpọ pẹlu dáàda kòdà ki wọn jẹ kèfèri

3.         Alaye lori bi a se lese dáàda si awọn obi mejeeji

4.         Alaye nipa ipò ti dáàda sise siwọn wa ati ẹsan dáàda sise siwọn pẹlu ọla to wa nibẹ.

Akoko Khutubat: Iseju Marundinlogoji

Khutuba Alakọkọ: Ogun iseju

الحمد لله رب العالمين على جزيل نعمه وواسع فضله  أوجب على الأولاد طاعة أبائهم بالمعروف وبرّهم والإحسان  إليهم   في مقابل تربيتهم أولادهم التربيّة  الحميدة " وقل رب ارحهما كما ربّيانى صغيرا  وأشهد أن لاإله إلا الله وحده لا شريك له سبحانه وتعالى عما يقولون علوا كبيرا, أشهد أن محمدا عبده ورسوله  أرسله بين يدي الساعة بشيرا ونذيرا وداعيا إلى الله بإذنه  وسراجا منيرا,  صلّى الله عليه وعلى آله وأصحابه وسلم تسليما كثيرا. أما بعد

 

A dupẹ lọdọ Ọlọhun, ọba to pase sise daada sobi ẹni, Ọlọhun sọ pe:

Atipe Oluwa rẹ palasẹ pe: “Ẹ ko gbọdọ sin kini kan ayafi on nikan ati ki ẹ si maa se rere fun awọn obi mejeeji” suratul Israi: 23.

Mo jẹri pe Ọlọhun nikan ni isin ododo yẹ, ko lorogun bẹẹni mo si gbà pé Annọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni, ojisẹ Rẹ si ni, Ikẹ Ọlọhun ki o maa baa, ati awọn ara ile rẹ ati awọn sahabe rẹ, to fi dori gbogbo ẹlẹsin Isilaamu patapata.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun ibanisọrọ wa toni da lori ọrọ kan to pataki pupọ ati iwọ nla to si jẹ dandan lori ẹnikookan wa lati pe e, ani iwọ to se pe Ọlọhun fi kẹgbẹ iwọ rẹ lori wa, leyi to se pe ẹniyowu to ba raa láre ko ni jere bẹni ko ni la, iwọ ti a nfọrere rẹ naa ni iwọ awọn obi mejeeji. O yẹ ki o di mimọ fun wa pe ibasepo to mbẹ laarin eeyan ati Ọlọhun ni ibẹru Ọlọhun  ati pípé awọn iwọ rẹ, ki ẹ si ma da nkankan pọ mọ Ọ, ki ẹ si maa se rere si awọn obi yin mejeeji ati awọn ibatan ti o sunmọ yin ati awọn ọmọ orukan: Suratul Nisai : 36.

{وَاعْبُدُوا اللَّهَ وَلا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئاً وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَاناً وَبِذِي الْقُرْبَى وَالْيَتَامَى وَالْمَسَاكِينِ وَالْجَارِ ذِي الْقُرْبَى وَالْجَارِ الْجُنُبِ وَالصَّاحِبِ بِالْجَنْبِ وَابْنِ السَّبِيلِ وَمَا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ إِنَّ اللَّهَ لا يُحِبُّ مَنْ كَانَ مُخْتَالاً فَخُورا}.

"Ki ẹ si maa sin Ọlọhun, ki ẹ si ma da nkankan pọ mọ Ọ, ki ẹ si maa se rere si awọn obi yin mejeeji ati awọn ibatan ti o sunmọ nyin ati awọn ọmọ-orukan ati awọn alaini ati awọn aladugbo ti o sunmọ nyin ati awọn aladugbo ti o jinna ati awọn ọrẹ alabarin ati ọmọ oju ọna ati awọn ti ọwọ ọtun nyin ni (ni ikapa), dajudaju Ọlọhun kò fẹ awọn onigberaga ati afannu".

O jẹ dandan lati se dáàda sobi ẹni kódà bi awọn mejeeji jẹ kèfèrí, ko si ninu majẹmu sise dáàda siwọn: pe wọn gbọdọ jẹ musulumi. Asimọu sọ pe ire Ojisẹ Ọlọhun mọmọ mi wa bámi, o si fẹ ki nfun oun nikan, se mo le dabi pọ kin se dàáda sii bi? “O ni bẹni, da okun ibi rẹ pọ”, kódà bi wọn ni ki o sẹbọ sọlọhun, eleyun ko sọ pe ki o má se dáàda siwọn mọ. Ọlọhun sọ pe:

"ووصّينا الإنسان بوالديه إحسانا حملته أمّه وهنا على وهن وحمله وفصاله فى عامين أن اشكر لي ولوالديك إلي المصير"

“Atipe Awa sọ asọtẹlẹ fun enia nipa obi rẹ, iya rẹ gbee e (ninu oyun) pẹlu ailera lori ailera atipe jija omu rẹ gba ọdun meji pe: Dupẹ fun Mi ati fun awọn obi rẹ mejeeji. Ọdọ Mi ni ipadasi” Suratul Lukman. Bi nwọn ba ngba o ni iyanju pe ki o wa orogun pẹlu Mi eyiti irẹ ko ni imọ rẹ, ma se tẹle ti awon mejeeji, ki o si ma ba wọn rẹ ni aiye yii niti daradara, ki o si tẹle ọna ẹniti o sẹri si ọdọ Mi, lehinna ọdọ Mi ni ipadasi nyin, nigbana Emi yoo fun nyin niro ohunti ẹ se nisẹ”. Suratul Lukman: 14

Bi a ba gbọ ọrọ Ọlọhun  ati ọrọ Ojisẹ rẹ lagbọye, a o ri pe dandan ni ki a se dáàda si obi eni, kódà ki wọn pani lasẹ iwa buruku, atipe yiyapa wọn ẹsẹ to tobi ni. To ba jẹ pe asẹ Ọlọhun niyi lori obi to jẹ keferi, to tun npani lasẹ ẹbọ sise sọlọhun, tọlọhun si ni ki a se dáàda si wọn, bawo lo se ro pe asẹ dáàda yoo se lagbara to bi obi mejeeji ba jẹ ẹnirere? Mo fi Ọlọhun bura pe iwọ wọn yoo tobi pupọ gaan ni. Abdullohi bun Mosud tilẹ bi Ojisẹ Ọlọhun  leere pe: Isẹ wo ni Ọlọhun nifẹ si julọ? O dahun pe: kikirun ni akọkọ àkókò rẹ. Mo tun bere pe: lẹhin rẹ nkọ? O dahun pe sise dáàda sobi mejeeji ni. Mo tun bi leere pe: Lẹhin rẹ nkọ? O ni: lẹhinna jijagun soju ọna Ọlọhun ni. Buhari ati Musilimu lo gba a wa.

Ninu adisi Abdullohi bun Amru, o sọ pe: ojisẹ Ọlọhun so fun arakunrin kan ti o ntọrọ lọdọ rẹ lati kopa ninu ogun pe: Se alàyè ni obi rẹ mejeeji? O sọ pe bẹẹni. Ojisẹ Ọlọhun si sọ fun un pe: Ọdọ wọn ni ki o ti wayọnda jijagun”. Buhari lo gba waa.

Abdullohi bun Amru tun gba adisi miran ti ojisẹ Ọlọhun ti sọ pe: Iyọnu Ọlọhun mbẹ nibi iyọnu obi mejeeji, bẹni ibinu rẹ mbẹ nibi ibinu wọn”. Tirimisiyu lo gba a wa. Muawiyatu bun Jahimọtu sọ pe: Arakunrin kan wa ba ojisẹ Ọlọhun, o si sọ fun ojisẹ Ọlọhun pe: mo gbero lati jagun, sugbọn mo fẹ ki o fun mi nimọran. Ojisẹ Ọlọhun ni sebi o ni iya? O sọ pe bẹẹni. Ojisẹẹ Ọlọhun sọ pe: lọọdunimọ isẹ rere sise fun-un, toripe alujanna ọmọ nbẹ labẹ gigisẹ obi rẹ mejeeji”. Nọsahi ati ibun Mọjaha  lo gba a wa.

Ninu adisi miran ẹwẹ, ojisẹ Ọlọhun sọ pe ki Ọlọhun yẹpẹrẹ ẹniti o ba obi re mejeeji tabi enikan ninu wọn dagba si lọwọ, ti ko wa tara wọn sisẹ ti yoo fi wọ alujanna. Sise dáàda sobi mejeeji jẹ ọkan ninu awọn isẹ ti ẹda le fi di ẹni asunmọ lọdọ Ọlọhun, kódà ninu awọn ilana to tobi julọ ti a le fi tẹle asẹ Ọlọhun lo wa, anisẹ sise dáàda siwọn, maa nsọ anu Ọlọhun kalẹ sori ẹda, ti o si maa nse isipaya aburu ati isoro. Sebi a ranti itan awọn eniyan mẹta ti òkè pade mọ, lapakan wọn ba nsọ fun apakeji pe: Ẹ jẹki a ronu si isẹ rere ti a ba tise siwaju, ki a fi tọrọ lọdọ Ọlọhun , ki Ọlọhun  le yọwa ninu àjàgà yii. Ni ọkan ninu wọn ba sọ pe: Irẹ Ọlọhun mi, mo ni awọn obi meji ti wọn ti dagba bẹẹni mo ni awọn ọmọ kekere kan, mo si jẹ ẹniti o maa nkọkọ fun awọn obi mi mejeeji ni wàrà mu siwaju awọn ọmọ naa, o sẹlẹ pe mo daranjẹ ni ọjọ kan, o wa pẹ mi pupo ki n to de, nigbati mo de, mo ba awọn obi mi ti wọn sun lọ, ni mo ba gbe wàrà naa lọwọ nibi igberi wọn, mo nreti ki awọn mejeeji ji. N o fẹ ẹ da oorun mọ wọn loju, bẹni mo si ko rira ki nfun awọn ọmọ mi lonjẹ siwaju wọn, lawọn ọmọ ba bẹrẹ si ẹkun ni sunsun lẹsẹ mi, n o yẹ lori ìnàró, bẹni awọn ọmọ naa ko si ye ẹkun sun, titi ti alufajari fi la (ti asunba fi to).

To ba se pe mo se isẹ rere yii, lẹniti o fi n wa iyọnu irẹ Ọlọhun ni, jọwọ tuwa silẹ, ki a le ri sanmọ, Ọlọhun si tuwọn silẹ, o yọwọn lọfin.

Ninu ojuse awọn obi mejeeji ni ki a tẹle asẹ wọn, ti ko yapa asẹ Ọlọhun.

"وَإِنْ جَاهَدَاكَ عَلَى أَنْ تُشْرِكَ بِي مَا لَيْسَ لَكَ بِهِ عِلْمٌ فَلا تُطِعْهُمَا وَصَاحِبْهُمَا فِي الدُّنْيَا مَعْرُوفاً وَاتَّبِعْ سَبِيلَ مَنْ أَنَابَ إِلَيَّ ثُمَّ إِلَيَّ مَرْجِعُكُمْ فَأُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ".

Ọlọhun sọ pe: ki o si maa ba wọn rẹ ni aiye yii niti daradara”. Suratul Lukmanu: 15.

2.         Lara rẹ naa ni: Ninawo lewọn lori ati dida asọ siwọn lọrun, ti wọn ba jẹ alaini.

3.         Sise adua fun wọn lasiko ti wọn sẹmi ati lẹhinti wọn ba ku tan.

4.         Dida okun ibi awọn alabatan wọn pọ.

قال تعالى: { وَقَضَى رَبُّكَ أَلاَّ تَعْبُدُواْ إِلاَّ إِيَّاهُ وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَاناً إِمَّا يَبْلُغَنَّ عِندَكَ الْكِبَرَ أَحَدُهُمَا أَوْ كِلاَهُمَا فَلاَ تَقُل لَّهُمَآ أُفٍّ وَلاَ تَنْهَرْهُمَا وَقُل لَّهُمَا قَوْلاً كَرِيماً }.

Ọlọhun sọ pe: “Atipe Oluwa rẹ pa lasẹ pe : "E kò gbọdọ sin kinnikan ayafi oun nikan ati ki ẹ maa se rere fun awọn obi mejeeji. Bi ọkan ninu wọn ba dagba si ọ lọwọ, a bi awọn mejeeji o ko gbọdọ se siọ wọn, bẹẹ si ni o ko gbọdọ jagbe mọ wọn. sugbọn ki o maa ba wọn sọrọ alapọnle. Ati ki o rẹ ara rẹ nilẹ fun wọn niti aanu ati ki o si maa sọ pe: Oluwa (ba mi) kẹ awọn mejeeji gẹgẹ bi nwọn ti rẹ (kẹ) mi ni kekere”. Suratul Israi 23 – 24.

Ọrọ yii ni Abdullohi bun Umaru gbọye nigbati o fi kẹtẹkẹtẹ rẹ ati lawani rẹ ta larubawa oko kan lọrẹ, lehin ti o ti bii leere pe: Se bi iwọ ni ọmọ lagbaja. O si da lohun pe bẹẹni. Wọn bi Abdullohi leere pe kini o faa to fi fun un. O dahun pe: ọrẹ baba mi ni, mo si ti gbọ ti ojisẹ Ọlọhun  sọ pe: Dajudaju ninu dáàda to dara ju lọ ni ki a se dáàda sọrẹ baba eni lehin ti obi naa ti ku tan.

Ẹyin musulumi ododo, se bi ẹ ti gbọ nipa arakunrin ti orukọ re njẹ Uwaesi bun Amir ti ojisẹ Ọlọhun  pa awọn sahabe lasẹ ki wọn se dáàda sii, ki wọn si bẹẹ ki o ba wọn tọrọ idarijin ẹsẹ lọdọ Ọlọhun , se bi to ri dáàda rẹ to nse pẹlu iya rẹ ni.

Ẹ jẹki a dabi awon ẹni isaaju nibi sise dáàda si obi, awọn bii Aewatu ọmọ Suraei, ọkan pataki lo jẹ ninu awọn agba afa, nibiti awọn ọmọ keu ba ti pejọ biba, ti o n gba keu fun wọn, ni iya rẹ yoo ti paa lasẹ ki o lọọ fun awọn adiẹ lonjẹ, yoo si dide lọọ se bẹẹ, agbalagba ni o, awọn agba agba si pọ ninu awọn akekọ rẹ.

Bẹẹ naa ni Abul Asani Aliyu bun Usain ti njẹ Saenul Abidina, eekan pataki lo jẹ ninu awọn tabiina, latari dáàda rẹ sobi rẹ ni wọn fi sọọ ni Oluse dáàda sobi rẹ julọ. Melo la fẹẹ ka ninu eyin adépèlé, Nirotinaa mo rọ ẹyin ọdọ asiko yii, ẹ mura si dáàda sise si obi yin, ki ẹ sapa lori bi ẹ o se yọwọn ninu ati bi ẹ o se ko orire bawọn laye yii.

Ko si ohun ti obi nwa ju pe ki o wa ni tosi rẹ, to ba ti bukata si ọ, sọrọ gidi fun wọn pẹlu irẹlẹ ati aanu, se wọn ni: Idunnu ni onjẹ àgbà.

Ẹyin musulumi, ẹ jẹ ka jinna si isẹya sẹ baba toripe ninu awọn ẹsẹ nlanla lo wa. Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: Se ki nfun yin niro nipa awọn ẹsẹ ninla? Wọn dahun pe: Bẹni irẹ ojisẹ Ọlọhun. Lanabi ba sọ pe: Isẹbọ sọlọhun, ati isẹya sẹ baba …” Buhari ati Musilimu lo gba a wa. O tun sọ pe: Awọn eniyan mẹta kan Ọlọhun ko ni siju anu wo wọn; olusẹya sẹ baba …”. Nọsai lo gba a wa.

O tun sọ pe : ko si ẹsẹ kan to yẹ kọlọhun kanju jẹ ẹniti o ba dẹsẹ naa niya pẹlu awọn ìyà to ti toju fun lalukiyamọ, bi sise agbere ati jija okùn ìbí”. Imam Ahmodu lo gba a wa.

Orisirisi ọna lẹda ngbaa sẹya sẹbaba;

1.         Ki a riwọn ki a fajuro, to si jẹ pe, o maa ntujuka si elomiran lọrẹ.

2.         Gbigbe ohun soke lalala, nigbati o ba n ba wọn sọrọ

3.         Kike ọrọ mọwọn lẹnu

4.         Jijagbe mọwọn

5.         Fifi ìròrí ẹni bori tiwọn

6.         Mimọ ọ wo wọn, ni wiwo ẹniti o n binu si ọta rẹ tabi ẹniti o fẹ ba ọmọ rẹ wi.

7.         Lilọra bíìyá bukata wọn ati didagba sii debi pe wọn yoo fi ko súsú. Wo suratul Israi: 23.

{ وَقَضَى رَبُّكَ أَلاَّ تَعْبُدُواْ إِلاَّ إِيَّاهُ وَبِالْوَالِدَيْنِ إِحْسَاناً إِمَّا يَبْلُغَنَّ عِندَكَ الْكِبَرَ أَحَدُهُمَا أَوْ كِلاَهُمَا فَلاَ تَقُل لَّهُمَآ أُفٍّ وَلاَ تَنْهَرْهُمَا وَقُل لَّهُمَا قَوْلاً كَرِيماً }.

Nitorinaa, bẹru Ọlọhun, ma se yapa obi rẹ, ki o si sọra nibi gbigbe elomiran loju, tabi pipataki rẹ ju obi rẹ lọ, ẹ ma se gbagbe pe ko si ẹsẹ tọlọhun le tete kanju jẹda niya lori rẹ bi sisẹya sẹ baba. Ẹ gbọ itan yii, ki ẹ fi se arikọgbọn: ọmọ mu baba rẹ jade lọjọ kan, o gbe e sori ẹsin rẹ, wọn nlọ, nigbati wọn debi apata kan, baba rẹ bii leere pe: nibo lo nmumi lọ?

Ọmọ ni, mo fẹ dumbu (pa) yin ni, toripe, mo ti ko súsú nipa rẹ, Baba sọ pe, to ba se pe o saa fẹẹ pami ni, mumi lọ sibi apata tọ wa lọhun un, ki o pami sibẹ, ibẹ ni emi naa pa baba mi si, sugbọn mọ amọdaju pe, ibẹ ni ọmọ tirẹ naa yoo pa ọ si. Nitorinaa, ẹbẹru Ọlọhun “Asesilẹ ladeba”

 

Nitori idi eyi ẹ bẹru Ọlọhun, ẹ sapá lori bi ẹ o se ri idunnu obi yin ki Ọlọhun le yọnu si yin, nidakeji ẹwẹ, ẹ sọra fun iwa sẹya sẹ baba, ki Ọlọhun sewa ni itutu oju fun awọn obi wa laye ati ni alukiyamọ, ki o si forijinwa ati awọn obi wa lapapọ.

فاتقوالله عباد الله - وأحسنوا  إلى آبائكم  واحذروا العقوق فإنه من كبائر الذنوب . ثم اعلموا أن الله سبحانه أمرني  وإيّاكم  بأمر بدأ به نفسه  الكريمة  وبملائكته الكرام  وقال عز من قائل ( إن الله وملائكته يصلّون على النّبي  يا يها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلموا تسليما) , اللهم صلّ وسلم على عبدك ونبيك محمد بن  عبد الله  وارض اللهم  عن الخلفاء الراشدين  أبي بكر وعمر و عثمان وعلي وعن سائر  أصحاب نبيك  وعنا معهم برحمتك , وفضلك  يا أرحم الراحيمن. اللهم  أعزّ الإسلام والمسلمين وأذلّ الشرك والمشركين ودمّر أعداء الإسلام  اللهم اجعل هذا البلد آمنا مطمئنا  سخاء  رخاء  وسائر بلاد المسلمين يا  ربّ العالمين