Awọn erongba lori khutubah naa:
1- Sise daradara si aladugbo pẹlu sisọ ẹtọ wọn.
2- Alaye ẹtọ aladugbo.
3- Alaye lori ọla ti o wa fun sise daradara si aladugbo.
4- Sisọra fun aida sise si aladugbo.
ẹyin ẹrusin Ọlọhun aladugbo ni ẹtọ ti o tobi lọdọ wa, ti a ko gbọdọ ma moju to, ti a ko si gbọdọ ra lare; eleyi ni o fa Hadiisi ti Annabi Muhammad (r) sọ wipe:
حديث عن أمر عظيم ما زال جبريل يوصي النبي r به حتى ظن أنه سيورثه
Gbogbo igba ni jubriilu wa nran emi Annabi leti ọjuse mi si aladugbo mi, titi ti mo fi wa nro pe;yoo fun un logun jẹ ni .
Bukhari ati Muslim lo gbaa wa.
Aladugbo ni ẹni ti ẹ jijọ ngbe lẹgbẹ araa yin, yala musulumi ni tabi keferi, ẹni rere ni tabi ẹni buburu, elede rẹ ni, tabi ede ko payin pọ. Isilaamu fun ikọọkan ninu awọn wọnyi ni ẹtọ ọrisirisi ti o yatọ si ara wọn, latari jijẹ ẹbi, sisunmọ ara ẹni, ẹsin rẹ ati iwa rẹ pẹlu.
Jijẹ aladugbo tun tumọ si ẹni ti ẹ ba jọ wa lẹgbẹ ara yin yala ni ibi isẹ ni tabi lọja, yala ni Mọsalasi tabi ni aaye ikẹkọ, ni ori irin ajo tabi ni ile gbigbe, koda laarin adugbo kan si adugbo miran laarin orilẹ- ede kan si orilẹ ede miran.
Ọlọhun sọ wipe:
قال تعالى : {واعبدوا الله ولا تشركوا به شيئا وبالوالدين إحسانا، وبذي القربى واليتامى والمساكين والجار ذي القربى والجار الجنب والصاحب بالجنب وابن السبيل وما ملكت أيمانكم إن الله لا يحب من كان مختالا فخورا} [النساء : 36].
“ẹ jọsin fun Ọlọhun, ẹ maa se baa wa orogun Kankan, ki ẹ si se daradara si awọn obi yin mejeji, ati awọn ẹbi, ati awọn ọmọ orukan ati awọn alaini ati awọn aladugbo ti ọ sunmọ yin ati awọn aladugbo ti o jinna ati awọn ọrẹ alabarin ati ọmọ oju-ọna ati awọn ti ẹ ni ikapa le lori. Dajudaju Ọlọhun ko fẹ awọn ọnigberaga ati oni faari” Suratun-Nisai: 36
Ki a sọ ẹtọ aladugbo jẹ ojuse gbogbo Musulumi, koda awọn ti wọn lo aye ki Isilaamu to de mọ Pataki aladugbo wọn ti wọn si maa nse nkan meremere fun wọn. Annabi Muhammad (r) sọ wipe: "
قَالَ «مَنْ كَانَ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الآخِرِ فَلْيَقُلْ خَيْرًا أَوْ لِيَصْمُتْ، وَمَنْ كَانَ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الآخِرِ فَلْيُكْرِمْ جَارَهُ، وَمَنْ كَانَ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الآخِرِ فَلْيُكْرِمْ ضَيْفَهُ» متفق عليه.
"ẹni ba gba Ọlọhun gbọ ti ọ si gba ọjọ ikẹhin gbọ, ki o sọ ohun ti o dara tabi ki o dakẹ, ẹni ba gba Ọlọhun gbọ ati ọjọ ikẹhin ki o se apọnle fun aladugbo rẹ, ẹni ba gba Ọlọhun gbọ ati ọjọ ikẹhin ki o pọn alejo rẹ le “ Bukhari ati Muslim lo gbaa wa.
Musulumi ko gbọdọ se idaamu fun aladugbo rẹ bi o se wu ki o kere mọ. Annabi Muhammad (r) sọ wipe:
عن أبي شريح : أن النبي صلى الله عليه و سلم قال : "والله لا يؤمن، والله لا يؤمن، والله لا يؤمن" قيل : ومن يا رسول الله؟ قال : "الذي لا يأمن جاره بوائقه" أخرجه البخاري.
“ Mo fi Ọlọhun bura pe ko gba Ọlọhun gbọ, Mọ fi Ọlọhun bura pe ko gba Ọlọhun gbọ, Mo fi Ọlọhun bura pe ko gba gbọdọ fi ọkọ dii lọwọ lati wọle tabi lati jade, ko gbọdọ fi omi dii lọwọ, tabi awọn oorun ti ko dara, ko gbọdọ bu ninu ilẹ rẹ, ko gbọdọ jaa lole, ko gbọdọ di awọn ọmọ rẹ lọwọ, ko gbọdọ dii lọwọ pẹlu gbigbe ohun orin ti o ngbọ soke ju bi o ti se yẹ lọ,ni pataki julọ ni akoko ti araadugbo ba n sun.
Gbogbo ohun ti o ba le ko inira ba aladugbo pata ni a gbọdọ jinna si koda bi a ba ni ilẹ ti a fẹ ẹ ta Annabi Muhammad (r) fẹ ki a fi lọ ẹni ti o ba ngbe lẹgbẹ ilẹ naa. ọ sọ wipe:
فعن ابن عباس رضي الله عنهما عن النبي أنه قال: ((من كانت له أرض فأراد أن يبيعها فليعرضها على جاره)).
“ẹni ba ni ilẹ ti o fẹ ẹ ta, ki iru ẹni bẹẹ fi ilẹ naa lọ ẹni ti o ba ngbe lẹgbẹ ẹ rẹ”
gbogbo eleyi ara irọrun fun aladugbo wa ni.
A ko gbọdọ ko inira ba aladugbo pẹlu ọna yowu ki o le jẹ; a ko gbọdọ jamba a rẹ, a ko gbọdọ se ifimu finlẹ si ọrọ rẹ, a ko gbọdọ baa jẹ, ako gbọdọ yọju wo ẹ bi rẹ latoke tabi lati oju ferese; gbogbo awọn iwa jakujaku wọnyi jẹ ise ayakoko nnaki si Ọlọhun ẹlẹda ati ikọja aala si ẹtọ aladugbo.
Dajudaju iya ti o le koko wa fun ẹni ti o ba nse ohun kotọ si aladugbo rẹ. ibnu Mọsuud (t) sọ pe:
فعن ابن مسعود رضي الله عنه قال: قلت: يا رسول الله، أي الذنب أعظم؟ قال: ((أن تجعل لله ندًّا وهو خلقك))، قلت: ثم أي؟ قال: ((أن تقتل ولدك مخافة أن يطعم معك))، قلت: ثم أي؟ قال: ((أن تزاني حليلة جارك))، وعن المقداد رضي الله عنه قال: قال رسول الله : ((ما تقولون في الزنا؟)) قالوا: حرام حرّمه الله ورسوله، فهو حرام إلى يوم القيامة، فقال رسول الله : ((لأن يزني الرجل بعشر نسوة أيسر عليه من أن يزني بامرأة جاره)).
“Mo bi Ojisẹ Ọlọhun leere pe Ẹsẹ wo io tobi julọ O si dahun pe wiwa Orogun pẹlu Ọlọhun, Mo sọ pe : lẹhinnaa nkọ? Annabi sọ pe: ki eniyan pa ọmọ rẹ nitori ibẹru onjẹ ti yoo maa fun jẹ. Mo sọ pe: lẹhina nkọ?O sọ pe sise Agbere pẹlu iyawo aladugbo-ẹni. Annabi tun sọ ninu Hadiisi miran wipe: “Kini ẹ mọ nipa idajọ Sina Awọn sahabe dahun wipe: eewọ lọ jẹ, ti Ọlọhun ati Annabi Rẹ se ni eewọ, eewọ ni ti ti di ọjọ Ali-kiyaamah. Annabi wa sọ pe: “ Ti eniyan ba se sina pẹlu obinrin mẹwa ẹsẹ rẹ ko to ti ẹni o ba se sina pẹlu obinrin aladugbo rẹ.”.
ẹni ti o ba ngba ọna kan se idiwọ fun aladugbo rẹ gbọdọ paya Ọlọhun ẹlẹda ni tori pe iya nla mbẹ fun iru ẹni bẹẹ Ọlọhun sọ wipe:
يقول الله سبحانه وتعالى : {وَالَّذِينَ يُؤْذُونَ الْمؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ بِغَيْرِ مَا اكْتَسَبُوا فَقَدِ احْتَمَلُوا بُهْتَانًا وَإِثْمًا مُبِينًا} [الأحزاب:58].
“Atipe awọn ti wọn n ni awọn onigbagbọ ododokunrin ati obinrin lara laijẹ nipa ohun ti wọn se, dajudaju wọn ru ẹru irọati ẹsẹ ti o han.
Isẹju Mẹẹdogun Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, ọna ti awọn eniyan ngba lati fi se idilọwọ fun aladugbo wọn pọ ninu rẹ ni, bii ki o gbin igi ti ẹka igi yii yoo napa si ile aladugbo rẹ, tabi ki o maa lo irinsẹ kan ti ariwo rẹ tabi eruku rẹ maa di aladugbo lọwọ, tabi ki o kọ ile giga ti yo di atẹgun tabi orun lọwọ lati wọ ile aladugbo rẹ, iru ẹni bẹ gbọdọ mu iru nkan bẹẹ kuro.
Bakannaa gbigbe ile (rẹnti) fun ẹni ti kii kirun, ti yo ma kọ awọn ọmọ aladugbo ni ikọkukọ, tabi fifi ile rẹnti fun ẹni ti ọ ba nta ọti, siga ati bẹẹbẹlọ.
Aladugbo ko gbọdọ di aladugbo rẹ lọwọ nipa omi ti o nsan kọja ni ẹgbẹ ile rẹ. ko si gbọdọ jẹ ki omi darogun si ẹgbẹ ile aladugbo rẹ. ki aladugbo jẹ ki aladugbo oun se anfani lara nkan ti o ba ni gẹgẹ bii omi, iyọ ati koriko fun awọn ẹran rẹ.
Gẹgẹ bi aladugbo ko se gbọdọ gbe nkan ti o lẹ se eniyan lese si oju ona fun aladugbo rẹ, tabi ohun ti o le fa ipayin keke ati ajalu fun aladugbo rẹ. gbogbo nkan wọn yi jẹ eewọ. Ọlọhun sọ wipe:
قال تعالى : {وتعاونوا على البر والتقوى ولا تعاونوا على الإثم والعدوان واتقوا الله إن الله شديد العقاب} [سورة المائدة:2].
“ẹ fọwọ so ọwọ pọ lori ohun rere ati ibẹru Ọlọhun, ẹ ma se papọ da ẹsẹ ati iwa ikọja ala, ẹ paya Ọlọhun, Dajudaju iya lati ọdọ Ọlọhun le pupọ”Suratul Maidah: 2.
Ti a ba ranti ohun ti a ka ninu ọrọ Ọlọhun ati ọrọ Annabi Muhammad (r) latari ojuse aladugbo si ara wọn, a o ri ọpọlọpọ apejuwe daradara lara awọn ti o ti siwaju wa ti wọn gbọ ọrọ Ọlọhun ati Annabi Rẹ ti wọn si muu lo pẹlu ti wọn jẹ apejuwe rere, o yẹ ki a tẹ le wọn ninu ihuwa si i wa lojojumọ si aladugbo wa. Imam Ahmadu bun Hambal sọ nipa walid bin Kọsim bin Walid bin Al-hamdaani pe:
سُئِلَ عَنْهُ أَحْمَدُ بنُ حَنْبَلٍ، فَقَالَ :ثِقَةٌ، كَتَبْنَا عَنْهُ، وَكَانَ جَاراً لِيَعْلَى بنِ عُبَيْدٍ، فَسَأَلْتُ يَعْلَى عَنْهُ، فَقَالَ: نِعْمَ الرَّجُلُ، هُوَ جَارُنَا مُنْذُ خَمْسِيْنَ سَنَةً، مَا رَأَينَا إِلاَّ خَيْراً. [المصدر السابق 17/ 463].
“ ẹni daradara ni , mo kọ hadiisi rẹa a si jọ jẹ aladugbo papọ fun adọta ọdun, iwa daradara ni mo mọ pẹlu rẹ!! Njẹ wọn le jẹri daradara nipa wa bayi bi ? ẹ jẹ ki a yi ara pada ki a le tara aladugbo wa gba laada.”
هذا، قال الله تعالى : "إِنَّ اللهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيْتَاءِ ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَالْبَغِيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَرُونَ. وَأَوْفُوا بِعَهْدِ اللهِ إِذَا عَهَدْتُمْ وَلاَتَنْقُضُوا الْأَيْمَنَ بَعْدَ تَوْكَيدِهَا وَقَدْ جَعَلْتُمُ اللهُ عَلَيكُمْ كَفِيلاً إِنَّ اللهَ يَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونٍَ"
اللَّهُمَّ أّرِنَا الْحَقَّ حَقًا، وَارْزُقْنَا اتِّبَاعَه، وَأَرِنَا الْبَاطِلَ بَاطِلاً ، وَارْزَقْنَا اجْتِنَابَه.
اللَّهُمَّ وَلِّ أُمُورَنَا خِيَارَنَا، وَلاَ تُوَلِّ أُمُورَنَا شِرَارَنَا، اللَّهُمَّ اصْلِحْ وُلاَةَ أُمُورَنَا، وَلاَ تُوَلِّ عَلَيْنَا بِذُنُوبِنَا مَنْ لاَ يَخَافُكَ فِيْنَا وَلاَ يَرْحَمُنَا. اللَّهُمَّ اغْفِرْ جَمِيعَ أَمْوَاتِ الْمُسْلِمِينَ الَّذِينَ شَهِدُوا لَكَ بِالْوَحْدَانِيَةِ وَبِنَبِيِّكَ بِالرِّسَالَةِ وَمَاتُوا عَلَى ذَلِكَ. اللَّهُمَّ اغْفِرْلَهُمْ وَارْحَمُهُمْ وَاعَفْ عَنْهَمْ وَاكْرِمْ نُزُلَهُمْ، وَوَسِّعْ مُدْخَلَهُمْ وَاغْسِلْهُمْ بِاْلَماَءِ وَالثَّلْجِ وَالْبَرَدِ، وَنَقِّهِمْ مِنَ الُّذنُوبِ وَالْخَطَايَا كَمَا يُنَقَّى الثَّوْبُ الْأَبْيَضُ مِنَ الدَّنَسِ وَارْحَمْنَا اللَّهُمَّ إِذّا صِرْنَا إِلَى مَا صَارُوا إِلَيْهِ بِرَحْمَتِكَ يَا أَرْحَمَ الرَّاحِمِينَ.