islamkingdomfacebook


AWỌN OHUN TI O WA LẸYIN IKU

AWỌN OHUN TI O WA LẸYIN IKU

6666
Eko ni soki
Awon alaimokan maa ndapara wipe leyin iku saare ni, oro yi ko ri be rara bikose wipe ohun ti o nbe leyin efa oju eje lo gegebi owe Yoruba, nibo ni won yio fi ibeere awon Malaika inu saare si? iya ti ko ni afiwe fun awon alaigbagbo, oniwaabi eniyan, paapaajulo, saare le je abata alijanna fun eniyan, o si le je ogbun kan ninu ogbun ina fun-un, eleyii ni ti saare o, ki a maa ti menuba eyi to ku.

Awọn erongba lori Khutuba naa:

1-     Sise alaye awọn nkan ti yoo sẹlẹ lẹyin iku, ati isesi ọjọ igbende;

2-     Siseni loju kokoro lori awọn isẹ daadaa, ati kikilọ awọn isẹ aida.

3-     Pipeni lọ si bi tituuba ẹsẹ ati isẹri pada si ọdọ Ọlọhun ki asiko o tooju.

الحمد لله ربّ العالَمين، والصّلاة والسّلام على نبيّنا محمّد وآله وصحبه ومَن والاهم بإحسانٍ إلى يوم الدِّين، وبعد؛ أيّها المسلمون اعلموا أنّ من تمام الإيمان باليوم الآخر الإيمان بما بالموت وما بعد الموت من نعيم القبر وفتنته أعاذنا الله منها، والبعث والحشر، وماذا يجب علينا أن نعدّه له؛ فاليوم عملٌ وغداً حسابٌ.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun lododo, pipọ ninu awọn eniyan ni wọn mọ n ro wipe ti awọn ba ti ku, ti wọn si gbe awọn si inu sare awọn, ko tun si nkankan mọ, asise nla gbaa ni eyi, nkan ti o sẹku lẹyin ẹfa o ma ju eje lọ! Isẹmi tuntun miran ma tunwa lẹyin iku! Ohun naa ni isẹmi inu sare, lati bẹ lọ si isẹmi igbẹyin.

Ẹrusin Ọlọhun lododo! ẹ jẹ ki a jọ wo inu tira Ọlọhun ati ilana (suna) ojisẹ Rẹ lati mọ nkan ti o tun wa lẹyin iku.

Ninu awọn nkan ti yoo sẹlẹ si olugbagbọ ododo (mumini) ati alaigba (kafiri) ni: igbe-dide, iduro siwaju Oluwa fun isiro, sise isiro, gbigba tira, osunwọn, afara Asirati ati bẹẹbẹ lọ.

Tira Ọlọhun ati Sunna ojisẹ Rẹ jẹ ki o yewa pe, ti eniyan ba ku ti wọn si gbe si inu sare rẹ, akọkọ nkan ti yoo kọ koju rẹ ni: ibere (fitina) inu sare. O wa ninu Sahih Bukhari ati Musilimui lati ọdọ Anas ibn Malik (رضي الله عنه) o ni: Annabi Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ wipe:

"Dajudaju ni igbati wọn ba gbe ẹru – eniyan si inu sare rẹ, ti wọn si pada lẹyin rẹ; dajudaju ohun yoo maa gbọ ohun bata awọn eniyan rẹ. Annabi ni:  awọn Malaika meji yoo de ba, ti wọn o si gbe joko, ti wọn o wi fun pe:  kini iwọ mọ nipa ọkunrin naa -Ojisẹ Ọlọhun? Annabi ni: sugbọn olugbagbọ ododo (mumini) ni ti ẹ yoo dahun wipe: mo n jẹri wipe ẹru Ọlọhun ati ojisẹ Rẹ ni. Annabi ni: wọn o bawi fun pe: wo ibujoko rẹ ni inu ina, dajudaju Ọlọhun ti fi ibujoko kan parọ rẹ fun ọ ni inu Al-jannah. Annabi Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ wipe: yoo si ri awọn aye mejeeji. Ọkan lara awọn onimimọ ti n jẹ Qatadah sọ pe: wọn yoo fẹ sare rẹ ni ondiwọn aadọrin igbọnhọ, ti yoo si kun fun awọn nkan alawọ eweko titi di ọjọ agbende alukiyamo.

Sugbọn munafiki ati alaigbagbọ; wọn o wi fun pe: kini iwọ mọ nipa ọkunrin naa -Ojisẹ Ọlọhun-? Yoo si dahun pe: emi o mọ, emi ma n wi bi awọn eniyan ti ma n wi ni. Wọn yoo wi fun pe: iwọ ko mọ, o ko ka? wọn yoo si naa ni odurọ irin ni nina kan, ti yoo si pariwo ni ariwo kan ti gbogbo awọn nkan ti mbẹ ni agbegbe rẹ yoo gbọ yatọ si awọn eniyan ati alijanu.

Lẹyin naa wọn yoo fi iya jẹ alaigbagbọ ati munaafiki, ti wọn yoo si kẹ olugbagbọ ododo.

Lẹyin eyi ni Ọlọun yoo gbe awọn ẹda dide lati inu saare fun isiro. Ọlọhun sọ bayi pe:

{أو لم ير الإنسان أنا خلقناه من نطفة فإذا هو خصيم مبين. وضرب لنا مثلا ونسي خلقه قال من يحي العظام وهي رميم. قال يحيها الذي أنشأها أول مرة وهو بكل خلق عليم} [يس : 77 – 79].

ثم يحشر الله الخلق للحساب قال : {ولقد جئتمونا فرادى كما خلقناكم أول مرة وتركتم ما خولناكم وراء ظهوركم وما نرى معكم شفعاءكم الذين زعمتم أنهم فيكم شركاء، لقد تقطع بينكم وضل عنكم ما كنتم تزعمون} [الأنعام : 94]. وقال : {ونحشرهم يوم القيامة على وجوهم عميا وبكما وصما مأوهم جهنم كلما خبت زدناهم سعيرا} [الإسراء : 97].

Dajudaju ẹyin ti de wa bawa ni ọkọọkan gẹgẹ bi A ti se dayin ni akọkọ igba, ti ẹ si fi awọn nkan ti A fun yin silẹ lẹyin yin, ti A ko si ri awọn olusipẹ ti ẹ n lero wipe akẹgbẹ Ọlọhun ni wọn pẹlu yin, agbọkanle tabi irankan yin ti ja, awọn nkan ti ẹ n lero si ti sọnu}. [Al-'anam: 94]. Ati (suratu Yasin: 77-79), (Israi: 97).

Ni ọjọ nla yii, olukuluku ni yoo damu, ti ẹnikan ko si ni sọrọ a fi pẹlu iyọnda Ọlọhun, ododo si ni yoo sọ. Ọjọ naa se deede ẹgbẹrun lọna aadọta ọdun.

Lọjọ yii ni wọn yoo ko awọn eniyan jọ siwaju Ọlọhun fun isiro. (Suratul Zalzala 6-8).

{يومئذ يصدر الناس أشتاتا ليروا أعمالهم...} [الزلزلة: ٦ – ٨].

Ti Ọlọhun yoo si ba onikaluku sọrọ ti ko ni si ongbifọ. Nitori naa, ki ẹ bẹru ina, kódà bose pẹlu gbolohun ti o dara. Lẹyin naa ni wọn yoo pin awọn tira. (Suratul Kahf: 49).

{ووضع الكتاب فترى المجرمين مشفقين مما فيه....الخ}، [الكهف: ٤٩].

Meji ni awọn eniyan yoo pin si ni ọjọ naa, awọn ti wọn yoo gba tira wọn pẹlu ọwọ ọtun wọn, ati awọn ti wọn yoo gba tira wọn pẹlu ọwọ osi wọn. (suratul inshiqoq: 7-15).

وهنا ينقسم الناس إلى قسمين فمن آخذٌ كتَابَه بيمنيه، وآخذ بشماله، {فأما من أوتي كتابه بيمنيه...إلخ} [الانشقاق: ٧ – ١٥].

Lẹyin naa ni Ọlọhun yoo gbe osunwọn isẹ kalẹ. (suratul Anbiyai: 47).

ثم يوضع الميزان {ونضع الموازين القسط ليوم القيامة} الأنبياء: ٤٧]

Lẹyin naa ni yoo kan Afara Asirati, ko si ẹni ti ko ni gun-un. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) sọ pe: "wọn yoo mu afara naa wa, ti wọn yoo gbe lori Jahannamah. Afara naa jẹ nkan ti ẹsẹ yoo maa yọ lori rẹ, ti o si ni ẹgun. Yoo maa bẹ ninu awọn olugbagbo ododo (mumini) ti yoo kọja lori rẹ gẹgẹ bi mọnamọna, ti awọn miran yoo kọja gẹgẹ bi atẹgun, awọn miran gẹgẹ bi ẹsin ti o le sare, awọn miran yoo kọja lai fara pa, awọn miran yoo farapa, awọn miran yoo jasi inu ina Jahannamah, titi ti ẹni igbẹyin yoo fi kọja, ti wọn yoo wọ ni wiwọ. [Sahih Bukhari].

Lẹyin naa ni o wa ku idajọ ati gbigba ẹsan, akọkọ ẹjọ ẹsan ni ti ipaniyan larin awọn eniyan. Gbogbo musulumi, iwọ onimimọ, olowo, olori, gomina, minisita awọn alaye nkan ti o wa lẹyin iku ni ati gbọ yi, ko si nkan ti o le la eniyan a fi aanu Ọlọhun lori isẹ rere ti a gbe ile aye se, ki a ronu pa iwa da, ki a sẹri wa lọsi ọdọ Ọlọhun fun tituba, ki Ọlọhun gba tituba wa.

 

 

Khutubah Ẹlẹẹkeji: (isẹju mẹdogun)

الحمد لله ربّ العالَمين، والصّلاة والسّلام على نبيّنا محمّد، وآله وصحبه ومَن تبعهم بإحسانٍ إلى يوم الدِّين، وبعد؛

Ẹyin musulumi ododo, ile meji ni o wa: ọgba idẹra (Alijana) ati ina.

Ọlọhun ti Ọla Rẹ ga sọ ni awọn ọna ti o pọ ni inu Al-Quran. Wo (suratul Shurah: 7), (Hudu: 103-108), (Al-zumaru: 71-72).

{وكذلك أوحينا إليك قرآنا عربيا لتنذر أم القرى ومن حولها وتنذر يوم الجمع لا ريب فيه فريق في الجنة وفريق في السعير} [الشورى : 7]. وقال : {إن في ذلك لآية لمن خاف عذاب الآخرة ذلك يوم مجموع فيه الناس وذلك يوم مشهود...إلى قوله : {وأما الذين سعدوا ففي الجنة خالدين فيها ما دامت السموات والأرض  إلا ما شاء ربك عطاء غير مجذوذ} [هود : 103 - 108]. وقال : {وسيق الذين كفروا إلى جهنم زمرا حتى إذا جاءوها فتحت أبوابها...الى قوله تعالى : سلام عليكم طبتم فادخلوها خالدين} [الزّمر: 71 – 73].

Ki onikaluku mura kalẹ fun ọgba alijannah pẹlu igbagbọ ti o mọ kanga si Ọlọhun, ki a tuba lọsi ọdọ Ọlọhun, ki a ti ọpọ isẹ rere siwaju lati de ba. Ki a lọ mọ pe dajudaju ẹni o ni ọla ju ni ọdọ Ọlọhun ni ẹni ti n bẹru ti o si n paya Ọlọhun. Atipe dajudaju ẹnikẹni ti isẹ daada rẹ gbe larugẹ, ẹbi rẹ kan ko lee gbee larugẹ. Ki a mọ dajudaju pe gbogbo awọn isẹ wa ni o wa ni akọsilẹ ni ọdọ Ọlọhun, ẹniyowu ti o ba de ba isẹ daada ki o da ọpẹ fun Ọlọhun, ẹniyowu ti o ba de ba nkan miran yatọ si daada ara rẹ ni ko yaa bawi.

فاتقوا الله يا عباد الله واعلموا أن أكرمكم عند الله أتقاكم، وأن من بطأ به عمله لم يسرع به نسبه، وإنما هي أعمالكم يحصيها الله تعالى، فمن وجد خيرا فليحمد الله تعالى، ومن وجد غير ذلك فلا يلومن إلا نفسه.

وصلّى الله على نبيّنا محمّد وآله وصحبه ومَن والاهم بإحسانٍ إلى يوم الدّين.