islamkingdomfacebook


SÍSE IKILỌ ABÚRÚ AWỌN ÀSISE AHÁN

SÍSE IKILỌ ABÚRÚ AWỌN ÀSISE AHÁN

8114
Eko ni soki
Ahon je idera kan ninu awon idera Olohun lori eru, o je dandan lori eru lati maa dupe idera yii pelu imaa so eto ti Olohun nibe, yio maa so kuro nibi ohun ti yio bi Olohun ninu, yio si maa tu sile nibi ohun ti yio yoo Olohun ninu. Atiwipe akolekan anabi(Ki ike ati ola Olohun maa baa) lori abala yii koja ohun ti a le fi enu so tan, dajudaju anabi ka siso ahon si ini gbogbo oore patapata, O si maa nse atenumo re fun awon ara ile re, paapaa julo, ohun ti o po julo ti o maa nmu awon eniyan wo ina ni itasegere ahon won, E yaa je ki a sora, E je ki a sora.

Awọn erongba lori Khutuba naa:

 

1-     Titọju ọkan lori awọn ọrọ ati isẹ ti o dara ti o le mu eniyan ri iyọnu Ọlọhun;

2-     Wiwa iyọnu Ọlọhun;

3-     Jijinna si awọn nkan ti kó dàra.

الحمد لله الذي خلق الإنسان فأحس خلقه وجعل له الجوارح لتكون له عوناً على ذكر الله وشكره وحسن عبادته، وحذّر من استعمالها فيما يغضب الله، والصّلاة والسّلام على رسول الله القائل: (كفّ عليك هذايعنِي: اللّسان، وعلى آله وصحبه ومَن تبعهم بإحسان إلى يوم الدّين. وبعد.

 

Dajudaju ibẹru Ọlọhun ni O ga julọ, ohun naa ni okunfa orire aye ati ọrun.

Ọlọhun rọkirika gbogbo nkan pẹlu imọ Rẹ. Ko si nkankan ti o le pamọ fun Ọlọhun ni inu sanm tabi ni ori ilẹ, ni titori naa ẹ jẹ ki a sọra ki a ma se nkan ti yoo mu wa ri ibinu Ọlọhun. Wo awọn sura wọnyi: Al-kurani [Talaq: 2-3, An'am: 80, Saba: 3].

{ومَن يتق الله يجعل له مخرجا و يرزقه من حيث لا يحتسب ومَن يتوكل علي الله فهو حسبه إن الله بالغ أمره قد جعل الله لكل شئ قدرا}[الطّلاق: 2-3]. وقوله: {وسع ربي كل شىء علما أفلا تتذكرون} [الأنعام: 80]. وقوله تعالى: {رلا يعزب عنه مثقال ذرة في السماوات ولا في الأرض ولا أصغر من ذلك ولا أكبر إلا في كتاب مبين}[السّبأ: 3].

Idẹra nlanla kan ni ahan jẹ ni inu awọn ọpọlọpọ idẹra ti Ọlọhun se fun ẹda Rẹ. Ọlọhun da ahan fun itọwo ati fun alaye. [suratul Balad: 8-10].

{ألم نجعل له عينين ولسانا وشفتين، وهديناه النجدين} [البلد: 8-10].

Ahan ni akọle ẹkọ, ohun ni atọka lakaye ati oye. Sugbọn sibẹsibẹ melo-melo ni awọn ti ahan wọn ti jẹ okunfa iparun wọn!

Ti o ba ri bẹẹ, ọranyan ni sisọ ẹnu ati ahan wa kuro ni ibi ọrọ ẹyin, ẹgan, ofofo ati oni ranran ọrọ kọrọ. Ki mumini ododo maa ranti ni gbogbo igba pe Ọlọhun pawa ni asẹ sisọ ahan wa. [suratul Hujuraat: 12].

{ولا يغتب بعضكم بعضا أيحب أحدكم أن يأكل لحم أخيه ميتا فكرهتموه} [الحجرات: 12].

Abu Barzah Al-aslami (رضي الله عنه) gba ẹgbawa ni ati ọdọ ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) pe: "Mo pe ẹni ti o gbagbọ pẹlu ahan rẹ lasan, ti igbagbọ naa ko de inu ọkan rẹ! ma se sọrọ musulumi ni aida, ma si maa tọ pinpin ihoho awọn musulumi, nitoripe ẹnikẹni ti o ba tọ pinpin ihoho wọn Ọlọhun yoo tọ pinpin ihoho tiẹ naa" [Abu Dauda]. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) tun se ikilọ ofofo ni inu hadith miran wipe ofofo a maa se okunfa iya inu saare. [Sahih Bukhari ati Musilimu]. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) tun se alaye wipe ọrọ isọkusọ ati èpè sisẹ ti awọn obinrin maa n wi jẹ okunfa fun pupọ ti wọn yoo pọ ni inu ina. [Sahih Bukhari].

Sugbọn ọrọ ti o dara eyi ti o maa n yọ Ọlọhun ninu jẹ okunfa ipo giga fun ẹrusin Ọlọhun.

Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) se akolekan mi maa sọ ahan, ti o si fi kọ awọn saabe rẹ. Eleyi ri bẹẹ ni titori wipe sisọ ahan jẹ okunfa gbogbo oore.

Kódà Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) tun kọ awọn iyawo rẹ ni sisọ ahan. Gẹgẹ bi iya nla wa 'Aishah (رضي الله عنها) ti gbaa wa. [Sunanu at-Tirmidhi].

O wa seni ni aanu pe isesi ọpọ awọn musulumi ni fifi oju kere sisọ ahan wọn, ti wọn ko si bikita ati maa sọ ọrọ isọkusọ, ọrọ ti ko kan wọn ati mi maa sọ ọrọ ẹyin.

Eyi ti Isilaamu si pawa ni asẹ rẹ ni mi maa dunim ọrọ daada, fifi ọrọ ti ko kan eniyan silẹ. Gbogbo eleyi wa ni inu hadith.

Ni inu awọn isesi ti Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) tun se ikilọ rẹ fun wa ni mi maa barajẹ pupọ ni igba aburu (musiba), ti o si pa wa lasẹ mi maa se suru ni asiko ti aluba tabi musiba ba sẹlẹ. Kódà eleyun gangan ni suru. [Ahmad, Bukhari ati Musilimu].

Ẹyin ọmọ iya mi musulum! Irọ pipa ma ni ewu pupọ fun ẹni ti n paa. O si jẹ ọkan ni inu awọn ẹsẹ nlanla. Ti igbẹyin rẹ ko si dara ni aye ati ni ọrun, ni aye, yoo sọ opurọ di ẹni yẹpẹrẹ ni aarin awọn eniyan, ni ọrun yoo se okunfa ina wiwọ, ki Ọlọhun sọwa ni bẹ. Irọ ki i si tun nkan se rara.

Ti o ba ri bayi, o se pataki ki a maa wadi ohunkohun ki a to maa sọ. [suratul Hujuraati: 6].

{يا أيها الذين آمنوا إن جاءكم فاسق بنبإ فتبينوا أن تصيبوا قوما بجهالة فتصبحوا على ما فعلتم نادمين} [الحجرات: 6].

Ikan ni ara awọn oni imọ tafsiri Agba Afa As-Sa'adi se alaye ni ẹkurẹrẹ ni ori aaya naa.

 

 

الحمد لله ربّ العالَمين وليّ المتّقين. والصّلاة والسّلام على رسول الله الصّادق المصدوق الأمين. وبعد؛

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun ni ododo! Ẹ jẹ ki asọ ara wa o, ki a mọ amọdaju wipe Ọlọhun, O ni awọn malaika ti wọn n kọ gbogbo nkan ti eniyan n fi ẹnu rẹ wi o, yálà daada tabi ni aburu, ti yoo si se isiro gbogbo rẹ ni ikọọkan. Wo [suratul al-'Anaam: 16, al-Infitar: 10, Qaaf: 17-18, az-Zukhruf: 80].

{ويرسل عليكم حفظة} [الأنعام: 16]. وذكر أن مما يحفظونه جميع أعماله من خير وشر بما فيها من الأقوال، بقوله: {وإن عليكم لحافظين, كراما كاتبين يعلمون ما تفعلون}[الإنفطار: 10].  وقوله: {إذ يتلقى المتلقيان عن اليمين وعن الشمال قعيد, ما يلفظ من قول إلا لديه رقيب عتيد} [ق: 17-18]. وقوله: {أم يحسبون أنا لا نسمع سرهم ونجواهم بلى ورسلنا لديهم يكتبون} [الزّخرف: 80].

Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) naa tun wi pe: "awọn malaika kan wa ti wọn yoo maa wa bayin ni alẹ ati ni ọsan, wọn yoo maa ko jọ ni asiko irun asunba ati irun alaasari, ti wọn yoo si maa gun oke lọ pẹlu awọn ti wọn sun, ti Oluwa wọn yoo maa beere ni ọwọ wọn, Ohun - Oluwa wọn- si ni imọ juwọnlọ; bawo ni ẹ se fi awọn ẹru mi si? Ti wọn yoo si maa fesi bayi pe: afi wọn silẹ ni ẹniti n ki irun , bẹẹ naa ni a bawọn ni ori irun ni igbati a de wa bawọn".

Ọlọhun rọrọ ju ki O sẹsẹ maa wa akọwe lọ, sugbọn O ran awọn malaika ki o le jẹ aanu fun awọn ẹda ni. Atipe ti wọn ba ranti pe awọn kan wa ti wọn n sọ wọn, yoo ran wọn lọwọ lati sọ ara ati ahan wọn.

Ẹjẹki a ranti pe Ọlọhun pa wa ni asẹ ibẹru Ọlọhun ati mi maa sọ ọrọ daada, ọrọ rere, ọrọ otitọ, ki awọn isẹ wa le dara, ki O si le se aforijin fun wa. Atipe ẹnikẹni ti o ba tẹle ti Ọlọhun ati Ojisẹ Rẹ ti jẹ ere ti o tobi. [suratul Ahzab: 70].

{يا أيها الذين آمنوا اتقوا الله وقولوا قولا سديدا .  يصلح لكم أعمالكم ويغفر لكم ذنوبكم ومن يطع الله ورسوله فقد فاز فوزا عظيما} [الأحزاب: 70].

Ọrọ sisọ jẹ oju ọna ti o tobi, o le jẹ oju ọna oore, o si le jẹ oju ọna aburu. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) jẹ ki o ye wa wipe "awọn nkan afi ẹnu wi jẹ ọkan ni ara nkan ti o le mu eniyan wọ ina". O tun sọ ni ibomiran pe: "ẹnikẹni ti o ba n gba Ọlọhun ati ọjọ-ikẹyin gbọ ki o yaa maa sọ ọrọ rere, ọrọ ti o dara, tabi ki o yaa dakẹ ti ko ba ni ọrọ rere ni ẹnu".

Ni inu awọn ọrọ rere ni kika Al-Kuran Alapọnle ati fifi kọ awọn eniyan, mi maa se alaye ọrọ Annabi (صلّى الله عليه وسلّم), ati ọrọ awọn onimimọ fun awọn eniyan. Ojisẹ Ọlọhun (صلّى الله عليه وسلّم) se adua pe: "ki Ọlọhun kẹ ẹni ti o gbọ ọrọ mi –Annabi- ti o si sọọ, ti o si fi jisẹ gẹgẹ bi o ti se gbọọ". Ọlọhun sọ pe: "Ọdọ Rẹ - Ọlọhun- ni awọn ọrọ ti o dara n gun lọ". [suratul Faatir 10].

{إليه يصعد الكلم الطيب } [فاطر: 10].

Ni inu ọrọ rere ni mi maa pa eniyan ni asẹ daada, ati mi maa kọ isẹ aburu fun awọn eniyan.

أسأل الله تعالى أن يجعلنا من { الذين يستمعون القول فيتبعون أحسنه أولئك الذين هداهم الله } [ الزمر : 18 ]، فمدحهم لحسن استماعهم، وصلّى الله وسلّم على رسولنا الكريم وآله وصحبه ومَن تبعهم بإحسانٍ.