Awọn erongba khutubah naa.
1- Itumọ ọdun ninu ede ati agbe kalẹ ẹsin.
2- Ibamu ọdun si adamọ ọmọ eniyan.
3- Itumọ ọdun gẹgẹ bi i idupẹ fun Ọlọhun latari awọn idẹra Rẹ, bii gbigbe orukọ Ọlọhun tobi ati irun kiki, sise abẹwo ati pinpin ẹbun ọdun.
4- Alaye awọn idajọ ti o wa fun ọdun.
ọdun jẹ ibamu si adamọ ẹda eniyan , bakannaa o si njẹ ọpẹ fun Ọlọhun Allah. Ọlọhun sọ wipe :
"فطرة الله التي فطر الناس عليها لا تبديل لخلق الله".
“Adamọ Ọlọhun eyiti o da mọ ẹda eniyan , ko si ohun ti a le fi paarọ ẹda Ọlọhun ” Suratur ruum: 30
Ọdun tumọ si nkan mẹrin; pipe jọ , aye ti a o pẹ jọ si, akoko ti ipe jọ naa yoo jẹ ati iru ijọsin ti a o se ni akoko ọdun. Oluwa ti Ọla Rẹ ga sọ wipe :
قال الله تعالى:"و لكل أمّةٍ جعلنا مَنْسَكا ليَذكروا اسم الله على ما رزقَهم من بهيمة الأنعام، فإلهكم إله واحد، فله أَسْلِموا، و بشِّرِ المخبتين". سورة الحج :34
“ Gbogbo ijọ kọọkan lo ni ijọsin, ki ẹ (ẹyin musulumi) ranti Ọlọhun latari awọn ẹran ti ẹ o fi jọsin fun Ọlọhun , Ọlọhun tiyin jẹ ẹyọkan soso Ọlọhun yii ni ki ẹ gba fun, ẹ fun awọn ti wọn rẹ ara wọn nilẹ fun Ọlọhun ni iro idunu.
Anasi jẹ ki a mọ wipe :
رواه أنس أن قدم النبي المدينة، و لهم يومان يلعبون فيهما. فقال قد أبدلكم الله بهما خيرا منهما: يوم الأضحى، و يوم الفطر".
Nigba ti Annabi Muhammad (r) de ilu Mẹdinah, awọn ara ilu naa ni ọjọ meji ti wọn fi n nsere , Annabi sọ wipe : Ọlọhun ti paarọ ọjọ mejeeji yii pẹlu eyi ti o dara juu lọ : ọjọ ọdun ileya ati ọjọ ọdun aawẹ .”
ọjọ ọdun ileya jẹ ọjọ ọdun ti a maa n kirun fun Ọlọhun Allah gẹgẹ bi Ọlọhun se pa Annabi Rẹ lasẹ ninu Al-kur’an wipe :
"فصل لربك وانحر".
“ Ki irun fun Ọlọhun rẹ ki o si pa ẹran ileya rẹ ”. suratul-kaothar.
قال ابن عمر:"الأضحية سنة"- أخرجه عبد الرزاق في المصنف قال الإمام الشعبي:"لم يكونوا يرخصون في ترك الأضحية إلا لحاج، أو مسافر". قال أبو أيوب الأنصاري،:"كان الرجل في عهد النبي يضحي بالشاة عنه، و عن أهل بيته، فيأكلون، ويُطعمون. ثم تباهى الناس، فصار كما ترى"- أخرجه ابن
ماجه
Ibn Umar sọ wipe : ọdun ileya jẹ Sunnah .Awọn alfa sọ wipe : Ko lẹtọ lati fi ileya silẹ ayafi fun ẹni ti o ba wa ni Haji lo sẹku. A rigbọ lati ọdọ Sahabe Agba yẹn : Abu Ayyub Al-ansari wipe : ni aye Annabi Muhammad (r) eniyan kan ma npa ẹran ileya kan fun ara rẹ ati awọn ara ile rẹ , wọn yoo si jẹ ninu rẹ , wọn yoo si fun ẹlomiran na jẹ ninu rẹ , lẹhinaa ni awọn eniyan yoo si maa dunnu, ki o to wa dabi o seda loni! Ibn majah lo gba a wa.
Annabi pa asẹ pe ki a pin ẹran ileya si ọna mẹta, ninu ọrọ rẹ ti o sọ wipe : ẹ jẹ ninu rẹ , ki ẹ si fi se saara ninu rẹ , ki ẹsi tun fi pamọ ninu rẹ.
ابن عباس قال: قال رسول الله:"ما من أيام أعظم عند الله، ولا أحب إليه العمل فيهن من أيام العشر، فأكثروا فيهن التسبيح، والتكبير، والتهليل"- أخرجه الطبراني في الكبير.
Ibn Abbas lo gbahadiisi miran wa wipe : Ko si ọjọ ti isẹ laada tobi ti o to awọn ọjọ yi, torinaa ki ẹ se afọmọ orukọ Ọlọhun nibẹ , ki ẹ sigbe orukọ Rẹ tobi nibẹ , ki ẹ si gbe o rukọ Rẹ ga nibẹ pẹlu” Tọbarani lo yọ Hadiisi yii jade .
Ẹyin ẹrusin Ọlọhun , akoko ọdun jẹ ,akoko ayọ , idunu ati abẹwo si awọn ẹbi ati araa wa. Aisa (رضي الله عنها) sọ wipe :
قالت عائشة-رضي الله عنها-:"كانت الحبشة يلعبون يوم عيد فدعاني رسول الله فكنت أطلع من عاتقه فأنظر إليهم، فجاء أبو بكر فقال النبي دعها، فإن لكل قوم عيدا، وهذا عيدنا"- أخرجه أحمد. و في رواية أخرى:"لتعلم اليهود أن في ديننا فسحة"- أخرجه أحمد.
“awọn ara Habasha nse ere ni ọjọ ọdun, Annabi si fi mi kalẹ , lati maa woran wọn lẹgbẹ ejika rẹ, nigbati Abubakari de, (o fẹ lati kọ fun Aisa) Annabi si sọ wipe : fi kalẹ ; gbogbo ijọ lo ni ọdun tirẹ , eleyi ni ọdun tiwa” Ahmad lo gba wa. Ninu ẹgbawa miran ti Ahmad tun gba wa . o ni Annabi sọ wipe : “ Ki awọn Yẹhudi lee mọ wipe akoko isinmi, idunnu ati ere wa ninu ẹsin tiwa naa ”.
Orisirisi awọn ohun kotọ kan ma nsẹlẹ ni akoko ọdun o yẹ ki awọn alfa pe akiyesi awọn eniyan si ibẹ , gẹgẹ bi didapọ laarin ọkunrin ati obinrin, wiwọ asọ ti o fi ihooho obinrin silẹ , kikọse Yẹhudi ati Nọsọra gẹgẹ bii sise (CARNIVAL), ijo kijo , ilu kilu, iwọ kiwọ , irun kirun ni didi ati irun kirun ni gigẹ .. ati awọn iwa jakujaku miran ti Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ko ni ifẹ si, gbogbo rẹ ni ki a pe akiye si awọn eniyan si ki a si jẹ ki awọn olupaya Ọlọhun naa rẹ oju wọn nilẹ .
Alfa wa Saori sọ wipe :
قال الإمام سفيان الثوري:"ينبغي للإنسان إذا كان يوم العيد أن يبدأ فيغض بصره، يهتم بذلك"- أخرجه وكيع في الزهد.
“O yẹ ki musulumi rẹ oju rẹ nilẹ ni akoko ọdun. Ki o si maa se akolekan eleyi, a o ri ọrọ yii ninu tira Suhudu ti wakii”.
Annabi Muhammad (r) sọ wipe :
روى أبو هريرة عن النبي يقول:"من حمل علينا السلاح فليس منا"- أخرجه ابن ماجه. وقال الإمام الحسن البصري:"نُهوا أن يحمِلوا السلاح يوم عيدٍ إلا أن يخافوا عدوا"- ذكره البخاري تعليقا.
“ẹni ti o ba gbe ohun ija dani ni akoko ọdun ko nii si ninu ijọ wa ni ọjọ Al-kiyamah” Bukhari se alaye wipe a kọ ki agbe ohun ija ni akoko ọdun ayafi ti a ba mbẹru awọn ọta.
Ti ọjọ ọdun ba se deede ọjọ Jimọh, a le ma ki Jimọh yẹn ti a ba ti ki irun yidi, sugbọn eleyi ko tumọ si wipe a ko nii ki irun aila (Suhuri) ọjọ yẹn . wọn ni Uswman bun ‘Afan ki irun yidi ti o papọ mọ Jimọh, lẹhin ti o ki irun tan o sise khutubah o wa sọ wipe :
قال أبو عبيد مولى ابن الأزهر: "شهدت العيد مع عثمان بن عفان، فكان ذلك يوم الجمعة فصلى قبل الخطبة ثم خطب، فقال: يا أيها الناس إن هذا يوم قد اجتمع لكم فيه عيدان، فمن أحب أن ينتظر الجمعة من أهل العوالي فلينتظر، ومن أحب أن يرجع فقد أذنت له"- أخرجه البخاري.
“ẹyin eniyan, oni yii jẹ ọjọ ti Jimọh ati irun yidi pade , ẹni ba fẹ lati reti asiko jimọh lee se bẹẹ ninu ẹyin ti ẹ wa lati ọna jinjin, sugbọn ẹyin ti ẹ ba fẹ pada wa, mo yọnda fun yin” Bukhari lo yọ Hadiisi naa jade .
Awọn Alfa se alaye wipe : o yẹ ki Imam ki irun yidi fun awọn eniyan ki o si tun ki Jimọh fun wọn pẹlu, tori pe eleyi ni yoo jẹ ki ọpọlọpọ eniyan ni anfaani pipe .
Ti a ba ki irun tan ni ọjọ ọdun o dara ki a ki ara wa wipe : ẹ ku ọdun, ki a se adura fun awọn eniyan wa, awọn ara ile wa, awọn ọmọ iyaawa ati awọn ara ilu wa pẹlu: (تقبل الله منا ومنكم) : Ọlọhun ki ọ gba ijọsin yii lọwọ wa ati ẹyin naa .
هذا، قال الله تعالى : "إِنَّ اللهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيْتَاءِ ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَالْبَغِيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَرُونَ. وَأَوْفُوا بِعَهْدِ اللهِ إِذَا عَهَدْتُمْ وَلاَتَنْقُضُوا الْأَيْمَنَ بَعْدَ تَوْكَيدِهَا وَقَدْ جَعَلْتُمُ اللهُ عَلَيكُمْ كَفِيلاً إِنَّ اللهَ يَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونٍَ"
اللَّهُمَّ أّرِنَا الْحَقَّ حَقًا، وَارْزُقْنَا اتِّبَاعَه، وَأَرِنَا الْبَاطِلَ بَاطِلاً ، وَارْزَقْنَا اجْتِنَابَه.
اللَّهُمَّ وَلِّ أُمُورَنَا خِيَارَنَا، وَلاَ تُوَلِّ أُمُورَنَا شِرَارَنَا، اللَّهُمَّ اصْلِحْ وُلاَةَ أُمُورَنَا، وَلاَ تُوَلِّ عَلَيْنَا بِذُنُوبِنَا مَنْ لاَ يَخَافُكَ فِيْنَا وَلاَ يَرْحَمُنَا. اللَّهُمَّ اغْفِرْ جَمِيعَ أَمْوَاتِ الْمُسْلِمِينَ الَّذِينَ شَهِدُوا لَكَ بِالْوَحْدَانِيَةِ وَبِنَبِيِّكَ بِالرِّسَالَةِ وَمَاتُوا عَلَى ذَلِكَ. اللَّهُمَّ اغْفِرْلَهُمْ وَارْحَمُهُمْ وَاعَفْ عَنْهَمْ وَاكْرِمْ نُزُلَهُمْ، وَوَسِّعْ مُدْخَلَهُمْ وَاغْسِلْهُمْ بِاْلَماَءِ وَالثَّلْجِ وَالْبَرَدِ، وَنَقِّهِمْ مِنَ الُّذنُوبِ وَالْخَطَايَا كَمَا يُنَقَّى الثَّوْبُ الْأَبْيَضُ مِنَ الدَّنَسِ وَارْحَمْنَا اللَّهُمَّ إِذّا صِرْنَا إِلَى مَا صَارُوا إِلَيْهِ بِرَحْمَتِكَ يَا أَرْحَمَ الرَّاحِمِينَ