islamkingdomfacebook


ỌLA TI O WA FUN ẸNI TI O BA MỌ ỌLỌHUN LỌKAN (TAOHEED)

ỌLA TI O WA FUN ẸNI TI O BA MỌ ỌLỌHUN LỌKAN (TAOHEED)

5461
Eko ni soki
Ki a mo Olohun lokan se pataki ninu isemi aye omoniyan paapaajulo eniti o ba je musulumi ododo. Awon alufa esin tumo gbolohun Attaoheed gegebi imo inu Alukurani Alaponle si ki a maa se Olohun lokan, Oba Aaso nibi ijosin re, eleyii tumo si wipe a ko gbodo sin ohunkohun ti o yato si, ola ti o po ni o wa fun eniti o ba se eleyii.

 

           Awọn ẹrongba lori khutubah:

1-     Alaye ati ọla lori pataki mimọ Ọlọhun lọkan soso.

2-     Alaye wipe: mimọ Ọlọhun lọkan ni okunfa iyege ati aforijin isẹ ẹda lọjọ ajinde.

3-     Alaye wipe: mimọ Ọlọhun lọkan ni okunfa ti o ma nti adanwo ati fitina jinna.

4-     Alaye Pataki lori nini imọ nipa mimọ Ọlọhun lọkan, ẹbọ ati ọna ti wọn pin si.

Khutubah Alakọkọ (ogun isẹju )

أوصيكم ونفسي بتقوى الله عز وجلّ في السر والعلن، واعلموا أن قلب المؤمن لا يصلح إلا بأمر عظيم، بينه الله تعالى في كتابه وبينه رسوله r في سنته بيانا شافيا كافيا، ولا ينجو أحد من الدنيا إلا بتحقيقه، ألا هو توحيد الله سبحانه وتعالى، وعبادته وحده لا شريك له، وإخلاص العمل له.

TAOHEED; (Imọ Ọlọhun lọkan) jẹ ohun ti o Pataki pupọ, ti Ọlọhun ati Annabi  Muhammad (r) se alaye lorii rẹ. Ni titori TAOHEED ni Ọlọhun fi se ẹda eniyan ati Alijanu, lo fida ina ati Aljanah, kódà torii rẹ lo fi se Jihad ni ọranyan. Annabi Muhammad (r) sọ wipe: "ẹni ba ku to si gbagbọ pe ko si ọba kan ti o lẹtọ ki a jọsin fun ayafi Ọlọhun yóò wọ Al-janah.

.   وقال رسول الله  r  "من مات وهو يعلم أنه لا إله إلا الله دخل الجنة".

TAOHEED ni ọla ti o pọ pupọ; o ma npa asise rẹ, ko nii jẹ ki eniyan

gbe inu ina gbere, o ma njẹ ki aburu ati adanwo jinna si eniyan. Ẹbọ sise ko nii jẹ ki eniyan ni ifọkan balẹ, ko si nii je ki eniyan ni imọna. Suratul An’am: 82.

وقال تعالى : {الذين آمنوا ولم يلبسوا إيمانهم بظلم أولئك لهم الأمن وهم مهتدون} [الأنعام : 82]

 

Nitorinaa, awọn ti wọn mọ ọna julọ ti wọn si pọ ni ifọkan balẹ ni

awọn Annabi Ọlọhun fun TAOHEED wọn, ati sise afọmọ isẹ wọn fun Ọlọhun Allah.

وينقسم التوحيد إلى ثلاثة أقسام : التوحيد الربوبية وهو توحيد الله بأفعاله، والتوحيد الألوهية وهو توحيد الله بأفعال العباد، وتوحيد الأسماء والصفات وهو تسمية الله تعالى بما سمى به نفسه أو سماه به رسوله r، ووصفه    بما وصف به نفسه أو وصفه به رسوله r من غير تحريف ولا تعطيل ولا تشبيه، ولا يتحقق التوحيد إلا بتحقيق هذه الأنواع الثلاثة

TAOHEED pin si ọna mẹta: TAOHEED sise Ọlọhun lọkan pẹlu isẹ Rẹ, TAOHEED sise Ọlọhun lọkan pẹlu isẹ awọn ẹda Ọlọhun, ati TAOHEED pipe Ọlọhun ni orukọ ti Allah pe ara Rẹ ati ti Annabi Rẹ Muhammad r pee, ati awọn iroyin ti Allah fi royin ara Rẹ ti Annabi Rẹ si fi royin Rẹ, laiko ni se afijọ Rẹ pẹlu awọn iroyin ọmọ Annabi Adama. TAOHEED mimọ Ọlọhun lọkan ko lo seese, ayafi ki awọn ọna mẹtẹẹta yi pé lara olugba Ọlọhun gbọ. Itọkasi fun ọna akọkọ wa ni suratu Ibrahim: 32-34 ẹlẹẹkeji wa ni suratu Maryam 65, ni gbati ẹlẹẹkẹta wa ni suratu Suura: 11.

{الله الذي خلق السموات والأرض وأنزل من السماء ماء فأخرج به من الثمرات رزقا لكم وسخر لكم الفلك لتجري في البحر بأمره وسخر لكم الأنهار... إلى قوله : إن الإنسان لظلوم كفار} [إبراهيم 32 – 34].

وقال : {رب السموات والأرض وما بينهما فاعبده واصطبر لعبادته هل تعلم له سميا} [مريم :65].

وقال : {ليس كمثله شيء وهو السميع البصير} [الشورى : 11

 

 

 

KHUTUBAH ẸLẸẸKEJI (ISẸJU MẸẸDOGUN)

Ọpọ awọn nkan ni o le ba TAOHEED jẹ mọ Musulumi lara, o di dandan ki musulumi mọ awọn nkan naa, ki o si yago fun wọn: ti eniyan ba npe ẹlomiran lẹyin Ọlọhun, bi iru eyi ti o gbajumọ lode onii, ti awọn kan nrọkirika sààréè (iboji) oku awọn eniyan Ọlọhun, ti eniyan ba nlọ si ile yẹmiwo (adanhunse) to si ngba ohun ti wọn sọ gbọ. Oluwa sọ wipe:

قال تعالى : {وإن يمسك الله بضر فلا كاشف له إلا هو. وإن يمسسك بخير فهو على كل شيء قدير}   [الأنعام:17]

"Bi oluwa ba fi inira kan ọ, ko si ẹlomiran ti o le si kuro fun ọ lẹyin Ọlọhun, bi o ba si fi ore kan ọ, Oluwa jẹ Alagbara lori ohun gbogbo. ( Al-an’am: 17).

Ti eniyan ba n se ijọsin nitori ti aye tabi se karimi, bakanna ti eniyan ba ntẹle ẹda ọmọniyan ti o fi wa n se eewọ ni ẹtọ, ti o si nse ẹtọ ni eewọ. Bakanna ti a ba fẹ ọmọ ẹda eniyan ni afẹju; ti a ba wa n lo gbogbo ohun ti o yẹ lati lo fun Ọlọhun fun ọmọ ẹda Adamọ, ẹlẹbọ ni iru eniyan bẹẹ. Oluwa sọ wipe:

قال تعالى : {ومن الناس من يتخذ من دون الله أندادا يحبونهم كحب الله والذين آمنوا أشد حبا لله} [البقرة:165]

“O wa ninu ọmọ ẹda eniyan ẹni ti o mu awon ẹda kan bii tiẹ naa (ọmọniyan) ni orogun Ọlọhun, ti o si fẹran wọn gẹgẹ bi ifẹ ti o ni si Ọlọhun…"AL- Baqarah: 165.

 

Oluwa ko fẹ ki a se ẹbọ pẹlu Oun Allah, ẹni ti o ba se bẹẹ ti o fi ku laiwa aforijin si ọdọ Ọlọhun, ina ni iru ẹni bẹẹ yo wọ, yoo si tun pẹ kanrin kese ninu ina. Oluwa sọ wipe:

قال تعالى : {إن الله لا يغفر أن يشرك به ويغفر ما دون ذلك لمن يشاء ومن يشرك بالله فقد ضل     ضلالا بعيدا} [النساء : 116].

"Dajudaju Oluwa ko ni fi ori jin ẹni ti oba wa orogun pẹlu Rẹ, sugbọn ti o si ma nfi ori jin ẹni ti O ba fẹ, ẹni ti o ba se ẹbọ pẹlu Oluwa iru ẹni bẹẹ ti sọnu ni isọnu ti o jinna” (suratu Nisa: 116”).

 

Ẹni ti o ba nfẹ alaafia ati ọla laye ati lọrun, ti o si fẹ wọ Aljanah lainise isiro isẹ rẹ, ti o si fẹ igbesi aye to dara, ki o tun la lọrun… gbọdọ mọ Ọlọhun lọkan, ki o si se afọmọ isẹ rẹ fun Ọlọhun Ẹlẹda, ki o kọ nipa TAOHEED, ki o si tun fi mọ ẹlomiran.

 jẹki a se akolekan TAOHEED gidigidi ki a maa ka ọrọ nipa rẹ ni gbobgo igba, ki a si ma fi mọ ẹlomiran tori pe eleyii ni yoo ma jẹ imọna fun ọkan wa ti yoo si fọ isẹ wa mọ tonitoni.

Ẹni ti TAOHEED rẹ ba duro daradara ni yo jere lọdọ Oluwa, ẹ ma se jẹ ki a da gẹgẹ bi awọn kan ti wọn ko ni akolekan rẹ ti isẹ wọn si ti bajẹ.

وعليكم بتحقيق التوحيد لله والإخلاص له وتعلم ذلك والاهتمام بما كتبه علماء الإسلام وأئمة السنة وأئمة هذه الدعوة في هذه المسائل العظام فإن مطالعة كتب التوحيد نور في الصدور وإن مطالعة كتب أهل العلم في ذلك في العقيدة والتوحيد وفي بيان الشرك وأسبابه ووسائله وأحكام ذلك وأدلته إن مطالعة ذلك وتعلمه نور وهداية في القلوب وصلاح للفرد وصلاح للمجتمع فلا تلهينكم الدنيا عن هذا الأصل العظيم الجامع الذي بعثت من أجله الأنبياء والمرسلون ومن أجله خلقت الجنة والنار فأعطوا هذه المسألة عظم حقها وما يليق بها وأقبلوا على ذلك من هذه الساعة إقبالاً فيه النية الصادقة في تعلم ذلك إجمالاً وتفصيلاً حتى لا تقع فيما وقع فيه الأكثرون من الجهل أو من ترك التوحيد وعدم رفع الرأس به والجهل بذلك أسأل الله جل وعلا أن يصلح لنا نياتنا وأن يصلح لنا ديننا وأن يصلح لنا دنيانا إنه جواد كريم.

 

 A bẹ Ọlọhun ti Ọla Rẹ ga, Ki o se atunse aniyan wa, ati isẹ wa, ki O jẹ ki aye ati ọrun wa dara, nitoripe Ọlọhun jẹ Alaanu ati Ọlọrẹ.

 

أيها المسلمون : هذا، واعلموا رحمني الله وإياكم أن الله جل جلاله أمرنا بالصلاة على نبيه وقال جل وعلا قولاً كريماً: إن الله وملائكته يصلون على النبي يا أيها الذين آمنوا صلوا عليه وسلموا تسليماً .[الأحزاب:56]

اللّهُمَّ أَعِزَّ الإسْلاَمَ وَالْمُسْلِمِينَ، وَدَمِّر أَعَدَاءَكَ أَعَدَاءَ الدِّينِ، وَانْصُرْ عِبَادَكَ الْمُوَحِّدِينَ، اللّهُمَّ عَلَيْكَ بِالْكَفَرَةِ الْفَجَرَةِ فَإِنَّهُمْ لاَ يُعْجِزُونَكَ يَارَبَّ الْعَالَمِينَ.

رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الأَخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَدَابَ النَّارِ.