islamkingdomfacebook


IBẸRU ỌLỌHUN ATI ORIPA RẸ NI IGBESI AYE MUSULUMI

IBẸRU ỌLỌHUN ATI ORIPA RẸ NI IGBESI AYE MUSULUMI

4194
Eko ni soki
Iberu Olohun ni asoole Olohun fun awon eni isaaju ati eni igbeyin, o si je ipepe awon anabi, ati idanimo awon aayo Olohun, paapaa iberu ni ki eru gbe gagaa di ara re nibi ohun ti o npaya ti o nsa fun. Eniti o npaya Olohun ni eniti o gbe odi isoo ti o lagbara ninu itele ase Olohun di ara re kuro nibi iya Olohun, O o ri ni eniti yio maa jinna si awon nkan eewo, yio si maa se alapantete nibi awon daadaa sise, yio wa maa semi ifayabale alayo, owo re yio si tee ipo nla ti o ga ni orun.

Awọn erongba lori Khutuba naa:

1.         Sise alaye pataki ibẹru Ọlọhun ati ọla rẹ.

2.         Paapa ibẹru Ọlọhun ati itumọ rẹ.

3.         Ọla awọn olubẹru Ọlọhun ati awọn nkan ti Ọlọhun tọju kalẹ fun wọn.

4.         Alaye ati iroyin awọn olubẹru Ọlọhun. 

الحمد لله الآمر بالتّقوى، وجعل التّقوى مقياس التكريم عند الله فقال: {إنّ أكرمكم عند الله أتقاكموالصّلاة والسّلام على نبيّنا محمّد وآله وصحبه وسلّم، وبعد؛

Dajudaju ibẹru Ọlọhun ni okunfa gbogbo oriire aye ati ọrun. Idi niyi ti Al-Kuran Alapọnle fi pariwo rẹ ni ọna ti o pọ.

Bakannaa ni ibẹru Ọlọhun jẹ asọtẹlẹ Ọlọhun fun gbogbo awọn ti o siwaju ati awọn ti wọn n bọ lẹyin. O si jẹ nkan ti awọn ojisẹ Ọlọhun pepe si, oun naa si ni ami ati apẹẹrẹ awọn olubẹru Ọlọhun, nitori pe Ọlọhun nikan ni a gbọdọ maa bẹru. Ọlọhun sọ bayi pe:

{وَلَقَدْ وَصَّيْنَا الَّذِينَ أُوتُواْ الْكِتَابَ مِن قَبْلِكُمْ وَإِيَّاكُمْ أَنِ اتَّقُواْ اللَّهَ} [ النساء:131].

{Dajudaju A ti se ikilọ fun awọn ti A fun ni tira siwaju yin ati ẹyin naa pe ki ẹ bẹru Ọlọhun} [Al-nisai: 132].

Paapa ibẹru ni ki eniyan mu gaga laarin oun ati nkan ti n baa lẹru, dajudaju Ọlọhun ni O too bẹru. 'Ali ibn Abi Talib (رضي الله عنه) se alaye ibẹru Ọlọhun bayi pe: "Pipaya nkan ti o tobi, sise isẹ pẹlu tira ti wọn sọ kalẹ, iyayo-ọkan pẹlu nkan ti o kere, ati ipalẹmọ de ọjọ-ikẹyin".

Ninu awọn iroyin ati ami ti a fi n da awọn olubẹru Ọlọhun mọ ni: gbigba ikọkọ gbọ, mimọ gbe irun duro, mi maa na owo si oju ọna Ọlọhun, pipe adehun, nini suru ni asiko inira, mimọ waa aforijin kuro ni ibi ẹsẹ, gbigba nkan ti Ọlọhun sọkalẹ gbọ, ati amọdaju nipa ọjọ-ikẹyin. Ọlọhun sọ bayi pe:

{ألم. ذلك الكتاب لا ريب فيه هدى للمتقين. الذين يؤمنون بالغيب ويقيمون الصلاة ومما رزقناهم ينفقون. والذين يؤمنون بما أنزل إليك وما أنزل من قبلك وبالآخرة هم يوقنون، أولئك على هدى من ربهم وأولئك هم المفلحون} [البقرة : 1 – 5].

{Alif, Laamu, Miimu. Tira naa kò sí iye meji ninu rẹ, imọna ni o jẹ fun awọn olubẹru Ọlọhun. Awọn ti wọn n gba ikọkọ gbọ, ti wọn si maa n gbe irun duro, ti wọn si maa n na arisiki wọn, awọn ti wọn gba nkan ti A sọkalẹ fun ọ gbọ, ati nkan ti A sọkalẹ siwaju rẹ, ti wọn si ni amọdaju nipa ọjọ-ikẹyin, awọn wọnyi ni wọn wa lori imọna lati ọdọ Oluwa wọn, awọn wọnyi ni awọn olujere} [Al-Baqarah 1-5].

Ninu awọn iroyin ati ami awọn olubẹru Ọlọun tun ni: pipe adehun, nini suru lasiko inira ati isoro. Ọlọhun sọ bayi pe:

{ولكن البر من آمن بالله واليوم الآخر والملائكة والكتاب والنبيين وآتى المال على ذوي القربى واليتامى والمساكين وابن السبيل والسائلين وفي الرقاب وأقام الصلاة وآتى الزكاة والموفون بعهدهم إذاعاهدوا والصابرين في البأساء والضراء وحين البأس أولئك الذين صدقوا وأولئك هم المتقون} [البقرة : 177].

{Sugbọn daada ni ẹniti o gba Ọlọhun gbọ, ati ọjọ-ikẹyin, ati awọn Maleka, ati Tira, ati awọn Annabi, ti o si na owo rẹ, ti oun paapa ni ifẹsi lori awọn alasunmọ (mọlẹbi) rẹ, ati awọn ọmọ orukan, ati awọn alaini, ati awọn ọmọ-oju-ọna, ati awọn olubeere (alagbe onibaara), ati fun irapada awọn ti n bẹ ninu igbekun ẹru. Ti iru ẹni bẹẹ si n gbe irun duro, ti o si yọ zaka, ati awọn olupe adehun nigbati wọn ba se adehun, ati awọn oluse suru ninu ipọnju ati inira, ati ni asiko isoro, awọn ni awọn ti wọn sọ ododo, awọn sini awọn olubẹru Ọlọhun } [Al-baqarah: 177].

Tun wo suratul (Al-'imran 133-135).

{وسارعوا إلى مغفرة من ربكم ... إلى قوله : والذين إذا فعلوا فاحشة أو ظلموا أنفسهم ذكروا الله فاستغفروا لذنوبهم ومن يغفر الذنوب إلا الله ولم يصروا على ما فعلوا وهم يعلمون} [آل عمران : 133 – 135].

Ninu awọn ọla ati anfaani ti o wa fun ibẹru Ọlọhun ni: sisipaya ọkan ati oju-ọna, ki Oluwa gba isẹ eniyan lẹsin, ifi aya balẹ, igbejinna si ina, ati wiwọ Alijanna. Wo Al-Kuran (Al-anfal: 29), (Al-hadid: 28), (Maryam: 63, ati 71-72), (Al-zumar 61).

{واتقوا الله ويعلمكم الله} [282]، {يا أيها الذين آمنوا إن تتقوا الله يجعل لكم فرقانا ويكفر عنكم سيئاتكم ويغفر لكم والله ذو الفضل العظيم} [الأنفال : 29].

وقال : {إنما يتقبل الله من المتقين} [المائدة: 27] وقال : {إن أكرمكم عند الله أتقاكم} وقال : {يا أَيُّهَا الَّذِينَ ءامَنُواْ اتَّقُواْ اللَّهَ وَءامِنُواْ بِرَسُولِهِ يُؤْتِكُمْ كِفْلَيْنِ مِن رَّحْمَتِهِ وَيَجْعَل لَّكُمْ نُوراً تَمْشُونَ بِهِ وَيَغْفِرْ لَكُمْ وَاللَّهُ غَفُورٌ رَّحِيمٌ} [الحديد:28]. وقال : {وَإِن مّنكُمْ إِلاَّ وَارِدُهَا كَانَ عَلَى رَبِّكَ حَتْماً مَّقْضِيّاً ثُمَّ نُنَجّى الَّذِينَ اتَّقَواْ وَّنَذَرُ الظَّالِمِينَ فِيهَا جِثِيّاً} [مريم:71-72].

وقال : {وَيُنَجّى اللَّهُ الَّذِينَ اتَّقَوْاْ بِمَفَازَتِهِمْ لاَ يَمَسُّهُمُ السُّوء وَلاَ هُمْ يَحْزَنُونَ [الزمر:61].

ولهم الفوز بدار الحبور {تِلْكَ الْجَنَّةُ الَّتِى نُورِثُ مِنْ عِبَادِنَا مَن كَانَ تَقِيّاً} [مريم:63].

الحمد لله ربّ العالَمين، والصّلاة والسّلام على نبيّنا محمّد وآله وصحبه ومَن تبعهم بإحسانٍ إلى يوم الدِّين، وبعد؛

Ninu ẹsan ibẹru Ọlọhun tun nipe: yoo se okunfa ifẹ Ọlọhun, ati ọpọ alubarika, sise igbesi aye ni irọrun, gbigbe gbogbo isoro kuro fun ni, ati jijere pẹlu Alijanna.

Ọlọhun ti Ọla Rẹ ga sọ pe:

{إن الله مع الذين اتقوا والذين هم محسنون} [النّحل: 128]، وقال : {ولو أن أهل القرى آمنوا واتقوا لفتحنا عليهم بركات من السماء والأرض ولكن كذبوا فأخذناهم بما كانوا يكسبون} [الأعراف : 96]. وقال : {ومن يتق الله يجعل له مخرجا} [الطّلاق 2].

{Dajudaju Ọlọhun n bẹ pẹlu awọn olubẹru Ọlọhun ati awọn oluse daada} [An-Nahl: 128]. Tun wo [Al'Araaf: 96], ati [At-Talaq: 2].

Bakannaa ni awọn eni isiwaju tun sọ asọ tẹlẹ lori ibẹrun Ọlọhun. Ni inu rẹ ni ọrọ apakan awọn olubani sọ ọrọ Ọlọhun (oniwaasi) ti o wipe: "Bẹru Ọlọhun Eyi ti O jẹ igbala rẹ ni ikọkọ rẹ. Ti O tunjẹ atẹgun rẹ ni ọkankan rẹ. Jẹ ki Ọlọhun jẹ ibalẹ ọkan rẹ ni ọsan ati oru. Si bẹru Ọlọhun ni ondiwọn bi O ti sunmọ ọ, ati bi O ti ni agbara ni ori rẹ".

Ẹyin olugbagbọ lododo! ẹ bẹru Ọlọhun, aye ati ọrun yin yoo dara. (suratul Hashri: 18-19).

{وتزودوا فإن خير الزاد التقوى} [البقرة: 197]، وقال : {ياأَيُّهَا الَّذِينَ ءامَنُواْ اتَّقُواْ اللَّهَ وَلْتَنظُرْ نَفْسٌ مَّا قَدَّمَتْ لِغَدٍ وَاتَّقُواْ اللَّهَ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ وَلاَ تَكُونُواْ كَالَّذِينَ نَسُواْ اللَّهَ فَأَنسَاهُمْ أَنفُسَهُمْ أُولَئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ} [الحشر:18-19].

وصلّى الله على نبيّنا محمّد وآله وصحبه وسلّم.