islamkingdomfacebook


Pataki Adua Síse ati Awọn Majẹmuu rẹ

Pataki Adua Síse ati Awọn Majẹmuu rẹ

6548
Eko ni soki
Gbogbo eda ni o ni bukaata si Oluwa won nibi gbigba ohun ti yio se won ni anfaani ati titi ohun ti yio niwon lara danu, lati tun esin ati aye won se, awon eru ki pasofo nibi adanwo ti yio so won di eniti yio maa ni bukaata si Oluwa won ni gbogbo igba, lati ara bee ni Olohun se se adua sise lofin,ti o si fi lele awon eko , mojemu ati awon asiko gbigba adua, ti o je wipe adua yio sumo gbigba nibe.

Erongba Lori Khutuba Naa:

1-     Sise alaye ohun ti n jẹ adua ati bi ọmọniyan ti ni bukaata sii to.

2-     Sise alaye awọn ofin, majẹmu ati ẹkọ adua sise.

3-     Ikilọ lori awọn erokero ati isọkusọ ti a ma n gbọ nipa adua sise.

                 

Khutuba Alakọkọ (fun ogún isẹju)

الحمد لله الواحد القهار، العزيز الغفار، أحمده تعالى حمداً يتجدد بالعشي والإبكار، وأشكره سبحانه على نعمه الغزار، وأسأله المزيد من فضله المدرار، وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له عالم الغيب والشهادة وكل شيء عنده بمقدار، وأشهد أن نبينا محمداً عبد الله ورسوله المصطفى المختار، صلى الله وسلم عليه وعلى آله البررة الأطهار، وصحبه الأئمة الأبرار، والتابعين ومن تبعهم بإحسان، صلاة تترى آناء الليل وأطراف النهار، وسلم تسليماً كثيراً.

 

Igba gbogbo ni ẹda ti Ọlọhun da ni bukaata si Oluwa ti O daa, yala lati ri oore kan tabi ekeji gba nio, tabi lati kọdi aburu kan tabi omiran.

Ọmọniyan tun ni bukaata si Ọba Adẹda lori bawo ni aye pẹlu ọrun yio se di irọrun.

Pípé ni ẹda ọmọniyan nbẹ ninu idirẹbẹ ati rirẹ ara ẹni silẹ fun ẹsìn Ọlọhun. Ati  wipe ki ẹda maa kepe Ọluwa ni igba gbogbo kiisu Ọlọhun, koda a tun maa dun mọ Ọ ni.

Oluwa a maa dan eniyan wo ni igbamiran, nitori ati jẹ ki iru ẹni bẹẹ le sunmọ Ọlọhun, ki o si ke pe E. Idi ni yi ti o fi jẹ wipe ẹni ti o ba n yẹpẹrẹ ara rẹ fun Ọlọhun ti o si n bẹ Ẹ lọsan loru oun gaan ni ọlọrọ ti  ọrọ aye kan ko lee ba. 

Saabe Annabi r tin jẹ Abu Dharri (ki Oluwa yọnu sii) gba hadiisi kudusi wa lati ọdọ Annabi r, o ni Ọlọhun Ọba ti O ga julọ sọ pe:

(با عبادي كلكم ضال إلا من هديته فاستهدوني أهدكم، يا عبادي كلكم جائع إلا من أطعمته فاستطعموني أطعمكم، يا عبادي كلكم عار إلا من كسوته فاستكسوني أكسكم .....) الحديث

"Ẹyin ẹru (ẹdà) mi, gbogbo yin ni alaimọ ọna (ọlà) ayafi ẹni ti Mo ba fi ọna mọ, nitorinaa, ẹ wa imọna wa si ọdọ Mi ki n le fi ọna mọ yin. Gbogbo yin ni ebi n pa ayafi ẹni ti Mo ba fun ni ounjẹ; nitorinaa, ẹ wa ounjẹ wa si ọdọ mi ki n le fun yin ni ounjẹ. Gbogbo yin, ihoho ni ẹ wa ayafi ẹni ti Mo ba da asọ bo; notorinaa ẹ wa ki n da asọ bo yin ki n le se bẹẹ".

Nkankan ko le sẹlẹ si eniyan yatọ si bi Oluwa ti kadara rẹ.  Ninu eto Oluwa naa ni pe bi eniyan yio se oriire, sababi kan ni yoo tọ de ibẹ; bi ẹniyan yio si se ori buruku pẹlu sababi kan naa ni yoo tọ de ibẹ.

Se bi Oluwa ba kuku fẹ, O le se ohunkohun ti o wu U, yala pẹlu sababi kan tabi lai si sababi kan rara. Ẹ gbọ bi Oluwa ti rohin ara rẹ ninu Al-Kur'ani :

فَعَّالٌ لِمَا يُرِيد [البروج:16]

"(Oun ni) O lagbara lati se ohunkohun ti o ba wu U" (Surat al-Buruj 85:16).

أَلَا لَهُ الْخَلْقُ وَالْأَمْرُ تَبَارَكَ اللَّهُ رَبُّ الْعَالَمِين [الأعراف : 54]

"Tirẹ ni dida-ẹda (ohungbogbo) ati asẹ (lorii wọn). Toto fun un Ọlọhun naa Oluwa gbogbo agbaye" (Surat al-A'raaf 7: 54)

 

Ki a se adua ko lodi si kadara ti Oluwa ti kọ, ara kadara naa ni adua wa.

Adua ni apọnle pupọ lọdọ Ọlọhun, O si mọọ mọ see ni okunfa oore fun awọn ẹda Rẹ. Oluwa sọ ba yi pe:

وَقَالَ رَبُّكُمُ ادْعُونِي أَسْتَجِبْ لَكُمْ إِنَّ الَّذِينَ يَسْتَكْبِرُونَ عَنْ عِبَادَتِي سَيَدْخُلُونَ جَهَنَّمَ دَاخِرِينَ [غافر : 60]

 "Atipe Oluwa yin wi pe: Ẹ ke pe Mi, Emi yoo si daa yin lohun. Ẹ o ri awọn ti wọn jọ ara wọn loju kọja ijọsin fun (kikepe) Mi, laipẹ wọn yoo wọ ina Jahanama ni ẹni yẹpẹrẹ"

 

Njẹ ti o ba waa ri bẹẹ, kinni ohun ti a n pe ni adua gaan?

Itumọ adua ni ki eniyan se ojukokoro oore lọpọlọpọ lọ si ọdọ Oluwa Asẹda; oore aye tabi ti ọrun. Bakannaa ki eniyan tun maa sa tọ Ọlọhun fun idaabobo kuro nibi aburu, ajalu, ibanujẹ tabi adanwo aye ati ọrun.

Ohun ti a n pe ni adua gbọdọ ko awon nkan wọn yi sinu:

1-     Kikepe Ọlọhun nikan soso, lai ni kepe nkankan tabi ẹni miran mọ.

2-     Amọdaju pe Oluwa ti a n pe yi Alagbara ni, ti ohunkohun wa ni ikapa rẹ lati se; Olumọ ni, ti ohunkohun ko pamọ fun; Ọba Alaaye, ti Otoo daduro funraa Rẹ, sugbon ti ohunkohun ko le duro laisi Oun; Alaanu, Onikẹ si ni pẹlu, Ọlọrẹ ni, ti ko si aala fun ọrẹ ati ẹbun Rẹ.

3-      Ẹni ti o fẹ se adua gbọdọ rẹ ara rẹ nilẹ fun Ọlọhun. A kii se faarri tabi sọ ọrọ afojudi nibi adua.

Ọla ti o pọ jantirẹrẹ ni o n bẹ fun adua sise. To bẹ gẹẹ ti Annabi r fi sọ wipe; "Adua gan ni ojulowo ijọsin fun Ọlọhun". Ojisẹ Ọlọhun r tun sọ ba yi pe; "Ko si Musulumi kan ni ori ilẹ aye yi ti yoo kepe Ọlọhun ayafi ki O daa lohun, ki O fun ni ohun ti o tọrọ tabi ki O fi adua naa gbe aburu kan kuro fun, lopin igba ti iru ẹni bẹẹ ko ba ti tọrọ ohun ti o jẹ ẹsẹ, tabi ki o fẹẹ fi adua ja okun ẹbi. Arakunrin kan ti o gbọ eleyi yara sọ pe: ti o ba ri bẹẹ, ajẹwipe ohun ti a o maa bere lọwọ Ọlọhun yoo pọ. Annabi r si daa lohun bayi: "Ọlọhun pọ ju bẹẹ lọ".

Musulumi ko gbọdọ maa pe ohun miran yatọ si Ọlọhun. Awọn ẹri lori eleyi pọ kanrin ninu Al-Kur'ani. Lapẹẹrẹ Ọlọhun Ọba sọ pe:

وَلَا تَدْعُ مِنْ دُونِ اللَّهِ مَا لَا يَنْفَعُكَ وَلَا يَضُرُّكَ فَإِنْ فَعَلْتَ فَإِنَّكَ إِذًا مِنَ الظَّالِمِينَ . وَإِنْ يَمْسَسْكَ اللَّهُ بِضُرٍّ فَلَا كَاشِفَ لَهُ إِلَّا هُوَ وَإِنْ يُرِدْكَ بِخَيْرٍ فَلَا رَادَّ لِفَضْلِهِ يُصِيبُ بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ" [يونس : 106-107].

 "Ma se ke pe ohun ti ko le da se anfaani kan fun ọ tabi ko ipalara kan ba ọ lẹyin Ọlọhun. Ti iwọ ba se bẹẹ, a jẹ wi pe ọkan ninu awọn alabosi ni iwọ jẹ. Atiwipe ti Oluwa ba tilẹ fi inira kan ọ, ko si ẹni naa ti o le muu kuro fun ọ lẹhin Oun Ọlọhun naa. Ẹwẹ, ti Oluwa yii ba gbero oore kan fun ọ, ko si ẹni naa ti o le kọ di ọlá Rẹ; a maa fifun ẹni ti o ba wu U ninu awọn ẹrú Rẹ, atipe Oun ni Oluforijinni Alaanu julọ".  (Surat Yunus 10: 106-107)

Oluwa tun sọ bayii pe:

وَمَنْ يَدْعُ مَعَ اللَّهِ إِلَهًا آخَرَ لَا بُرْهَانَ لَهُ بِهِ فَإِنَّمَا حِسَابُهُ عِنْدَ رَبِّهِ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الْكَافِرُون [المؤمنون : 117]

“Ẹnikẹni ti o ba nke pe ọlọhun miran pẹlu Ọlọhun Ọba (Allahu), leyi ti ko si (le) ni ẹri kankan fun, daju-daju, isiro iru ẹni bẹẹ di ọdọ Oluwa rẹ, daju-daju awọn alaigbagbọ ko nii la".

Ko si igba ti a ko le se adua. Sugbọn, awọn akoko kan wa ti adua a maa gba ju awọn igbamiran lọ. Ninu awọn akoko yi ni:

1-     Ni igba ti eniyan ba wa ni iforikanlẹ lori irun . Ojisẹ Ọlọhun r sọ bayi pe:

(أقرب ما يكون فيه العبد من ربه وهو ساجد فأكثروا الدعاء) أخرجه مسلم.

“Igba ti eda maa n sunmọ Oluwa rẹ julọ ni igba ti o ba wa ni iforikanlẹ; nitorinaa ẹmaa se ọpọlọpọ adua”.

 

2-     NI aarin ki wọn pe irun ọranyan si igbati wọn yoo gbe irun naa duro (se ikọọmọ). Ọrọ Ojisẹ Ọlọhun r lọ bayi pe:

(الدعاء لا يرد بين الأذان والإقامة) أخرجه الترمذي وقال: حديث حسن صحيح،

"Akii da adua pada (laiko gba) laarin Adaani ati Ikọọmọ".

3-     Ti a ba da oru si mẹta, idamẹta ti igbẹyin nibẹ.  Annabi r tun sọ bayii wipe;

"ينزل ربنا تبارك وتعالى كل ليلة إلى سماء الدنيا حين يبقى ثلث الليل الأخير فيقول: من يدعوني فأستجيب له، ومن يسألني فأعطيه، ومن يستغفرني فأغفر له" متفق عليه.

"Oluwa wa, titobi ati toto fun un, a maa sọkalẹ si sanma ti o sunmọ aye julọ (sanmọ akọkọ) ni gbogbo oru ni idamẹta oru ti o gbẹhin, yoo si maa sọ pe; ‘Taani yoo kepe Mi, kin daa lohun?’ Atipe, tani o ni ohunkohun lati tọrọ lọwọ Mi, kin si fuun? Atipe taani o fẹ wa aforijin ẹsẹ wa si ọdọ Mi, kin si fi ori jiin?".

4-     Akoko ti o gbẹyin ni gbogbo ọjọ Jimọ (lẹhin Alaasari). Abu Hurairah t gba hadiisi wa pe; Ojisẹ Ọlọhun sọrọ nipa ọjọ Jimoh, o sọ wipe: Wakati kan wa ninu ọjọ naa, ko si Musulumi ti yoo se kongẹ rẹ nigbati iru ẹni bẹẹ ba dide duro ti o nkirun ti o si n tọrọ nkan lọdọ Ọlọhun ayafi ki Ọlọhun fun un". O fi ọwọ rẹ juwe bi wakati ọwọ naa ti kere to. 

عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم: ذكر يوم الجمعة فقال: (فيه ساعة لا يوافقها عبد مسلم وهو قائم يصلي يسأل الله شيئاً إلا أعطاه إياه وأشار بيده يقللها)، متفق عليه.

 

5-     Bakanaa ninu awọn asiko gbigba adua ni Oru Lailatul kadiri, Ọjọ Arafa, adua lẹhin irun wakati maraarun, adua lasiko ti ojo ba n rọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

أقول ما تسمعون وأستغفر الله لي ولكم ولسائر المسلمين فاستغفروه إنه هو الغفور الرحيم.

 

 

الحمد لله مجيب الدعوات، وهو القائل في محكم تنزيله: "وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌ أُجِيبُ دَعْوَةَ الدَّاعِ إِذَا دَعَانِ فَلْيَسْتَجِيبُوا لِي وَلْيُؤْمِنُوا بِي لَعَلَّهُمْ يَرْشُدُونَ"  والصلاة والسلام على خير من دعا الله وأفضل من استجيب دعاؤه نبينا محمد وعلى آله وصحبه  ومن تبعهم بإحسان إلى يوم الدين.

Majẹmu ati awọn ẹkọ adua sise

Adua sise ni majẹmu ti eniyan gbọdọ mojuto bi o ba fẹ ki adua oun jẹ gbigbawọle lọdọ Ọlọhun Ọba.

 Akọkọ ninu awọn majẹmu naa ni, ki ẹni ti n se adua se afọmọ ẹsin ati adua rẹ kangá fun Ọlọhun. Ki o ma se se ẹbọ tabi pe ohun miran lẹhin Ọlọhun kan soso.

  •  Ninu majẹmu adua ni ki a jinna tefe-tefe si jijẹ, mimu, wiwọ tabi nina ohun eewọ (haraamu). Hadiisi Annabi (ki ike ati ola maa baa) ti Imam Muslim gba wa fi rinlẹ pe eniyan ko le kundun haraamu jijẹ ki o tun wa reti pe bi oun ba ti kepe Ọlọhun ni yoo da oun loun.
  •  Pipa ọkan pọ si ibi adua, majẹmu pataki ni o jẹ fun gbigba adua. Ọlọhun kii gba adua ẹni ti ọkan rẹ ko si nibi adua ti on se. Hadiisi ti Abu Hurairah t gba wa ni o jẹ ki a mọ bẹẹ. Akii fi adua dan Ọlọhun wo! Ohun ti eniyan ba fẹ ni ki o tọrọ, ki o si gbagbọ pe yoo ri bẹẹ.

 Bi eniyan ba fẹ se adua, ki o rii daju pe o kọkọ yin Ọlọhun Ọba, ki O si kiI ni mẹsan–mẹwa. Bakanaa ki o se asalatu fun Annabi r. Lẹhin eyi, ki o tọrọ ohun ti o ba fẹ.

  •  Wiwa ni imọtoto (pẹlu sise aluwala) nigbagbogbo ti a ba fẹ ke pe Oluwa, ẹkọ Pataki ni eyi jẹ ninu ẹkọ adua.

 Ninu ẹkọ adua sise ni ki eniyan gbe ọwọ rẹ soke lati fi tọrọ ohun ti o ba fẹ lọdọ Ọlọhun. Iru ọwọ bẹẹ ki yoo walẹ ni ofifo. Annabi r sọ bayi pe;

(إن ربكم حيي كريم يستحيي من عباده إذا رفعوا أيديهم إليه أن يردها صفرا) أخرجه الحاكم وصححه ووافقه الذهبي.

“Daju-daju Oluwa yin jẹ Onitiju Ọlọrẹ. A maa tiju ki awọn ẹru Rẹ gbe ọwọ wọn soke lati bẹ Ẹ, ki O si waa da ọwọ naa pada lofifo".

 

O dara pupọ ti a ba fẹ se adua ki a maa lo irufẹ adua ti Annabi r funraa rẹ ti fi kepe Ọlọhun ri, ati awọn adua ti o wa ninu Al-KuranilKarim. Ojisẹ Ọlọhun r gbọ ti arakunrin kan nki Ọlọhun ni mẹsan-mẹwa ti o n wi bayi pe; "Irẹ Oluwa ni ọpẹ ati iyìn tọ si. Ko si nkan tabi ẹnikan ti o tọ lati jọsin fun ayafi iwọ Oluwa nikan, Alailorogun. Ọba Ọlọpọ ọrẹ, Ẹniti O sẹda sanmọ ati ilẹ ni ọna ti ẹnikan ko se iru rẹ ri. Ọba ti O tobi ti O si kàyà, Alapọnle julọ ti I mọ da asọ apọnle bo awọn ẹru rẹ. Ọba Alaaye, Oludaduro funraa Rẹ, ti O tun jẹ pe Ọlá rẹ ni ouhn gbogbo fi duro.

v    " اللهم إني أسألك بأن لك الحمد، لا إله إلا أنت وحدك، لا شريك لك، المنان، بديع السموات والأرض، ذا الجلال والإكرام، يا حي يا قيوم"

Bi Annabi r ti gbọ iru adua ti arakunrin naa se ni o ba sọ pe: "Daju-daju iwọ ti fi orukọ Ọlọhun ti  o tobi julọ pe E; Ẹnikan kii si pee bẹ Ẹ ayafi ki O dahun; ko da ohun gbogbo ti a ba fi iru orukọ bẹẹ tọrọ Oluwa A maa fun ni".

Kii se igba ti ara ba n ni eniyan nikan ni a maa se adua. Jẹ olusunmọ Ọlọhun ti yoo maa ke pe E ni igba gbogbo. Annabi r sọ pe; "Ẹnikẹni ti o ba fẹ ki Ọlọhun da oun lohun ni igba ipọnju, ki o yaa ri daju pe oun n ke pe E lọpọlọpọ ni igba irọrun".  Allahu Akbar!

((من سره أن يستجيب الله له عند الشدائد والكرب فليكثر الدعاء عند الرخاء)) رواه الترمذي والحاكم وصححه.

Ki lo waa de ti pupọ eniyan kii fi kepe Ọlọhun ayafi nigba isoro?! Bi ara ba si ti tu wọn, wọn a tun pa adua ti. Eleyi ku diẹ kaato fun iwọ onigbagbo ododo.

Rii daju pe o n kepe Ọlọhun, ki o si dun ni mọ adua sise nigba gbogbo ati laaye kaaye. Nibi isẹ tabi ni ibugbe, ti a ba ji ati nigbati a ba fẹẹ sun, ni owurọ ati ni asalẹ, ni ori irin ajo tabi ni aarin ilu. Koda nibi akojọ, ipade tabi ayẹyẹ, ko yẹ ki Musulumi ko iyan adua kere rara.

Pupọ igba ni awọn eniyan maa n sọ pe; a ti se adua lọpọlọpọ sugbọn Oluwa ko dahun, laiko si fura pe  ai ko pe majẹmu ati ofin adua sise ni ko jẹ ki adua gba.

Ẹjẹ ki a fi igbesi aye awọn Saabe Annabi r se awokọse, lẹsẹkẹsẹ ti wọn ba kepe Ọlọhun, a si maa da wọn lohun.

اللهم صل على نبينا محمد ما ذكره الذاكرون الأبرار، وصل عليه ما اختلف الليل والنهار، وصل عليه وعلى المهاجرين والأنصار، وارض اللهم عن التابعين ومن تبعهم بإحسان إلى يوم الدين، وعنا معهم برحمتك وكرمك يا أكرم الأكرمين.