islamkingdomfacebook


IWANI NISỌRA NIPA AWỌN ADÀGBIGBA ATI ADAHUNSE

IWANI NISỌRA NIPA AWỌN ADÀGBIGBA ATI ADAHUNSE

4628
Eko ni soki
Melomelo omoniyan ti yio maa se opolopo ijosin fun Olohun sugbon ti o ba de iwaju Olohun, yio ri wipe ofo ni gbogbo ohun ti oun se ni ijosin, ohun ti o fa eleyi ni wipe ko je eniti o gbe ara le Olohun Oba ni ti tooto, O tun maa nlo bee awon alagbegba wo, awon ti won npe apemora imo koko eleyii ti kosi eniti o mo ayafi Olohun nikan.Oluwa pa Ojise re lase lati maa so fun awa erusin re wipe kosi eniti o ni imo koko ayafi Oun.

Awọn erongba khutuba:

-           Sìso okan musulumi mọ Oluwa wọn

-           Àlàyè nipa Idajọ idàn, didagbigba ati dídahúnsẹ.

-           Wiwani nisọra nibi lílọ sọdọ adágbigba adàhunsẹ ati awọn awòràwò

-           Àlayẹ nipa awọn ẹwu ati aburú ti didagbigba ati didahunsẹ yoo maa fa lawujọ.

-           Sisẹni lójú ọyìn nipa titẹlẹ ilana ofin Ọlọhun lọri gbogbo ohun ti a nwa

Akoko khutubat: ogun isẹju.

الحمد لله رب العالمين  أمرنا أن نعبده مخلصين له الدين , ونهانا عن طاعة الكفار  والمشركين , والانخداع بأعمال السحرة  والمشعوذين , وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له, وأشهد أن محمدا عبده ورسوله القائل "إن الله أنزل الداء والدواء, وجعل  لكل داء   دواء , فتداووا والاتداووا  بحرام " صلّ الله عليه وعل آله وأصحابه وسلم تسليما  كثيرا ... أما بعد

A da ọpẹ fun Ọlọhun, Ọba to ntọju wa tosi nrewa, o pawa lasẹ ki a maa sin oun nikan, lẹniti nse afọmọ ijọsin fun Un. Bẹẹni o se titẹle awọn keferi ati awọn ọsẹbọ leewọ fun wa, to si se kilọkilọ fun wa nipa idan awọn opidan ati iriran sini awọn adagbigba ki o ma baa ko ẹtanjẹ bawa. Mo jẹri pe kosi ẹnikankan ti o lẹtọ si ki a sin in lododo afi Ọlọhun nikan soso , kosi orogun fun un, bẹẹni mosi jẹri pe Annọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni, ojisẹ Rẹ sini ẹniti o sọ ninu ọrọ rẹ pe dajudaju Ọlọhun ti sọ arun ati oogun rẹ kalẹ , osi pese oogun kọọkan fun arun kọọkan , nitorinaa, ẹ ma lo ogun fi tọju arun to nse yin ,sugbọn ẹ ma lo ohunti Ọlọhun se ni eewọ” ikẹ ati igẹ Ọlọhun ki o maa baa ati awọn sahabe rẹ , ni ikẹ ati ọla ti o pọ.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, bi ẹ ba se akiyẹsi awujọ wa loni, ẹ o ri pe didagbigba ti gbalẹ bii ọwara òjò lasiko ti a wa yii, ti ọpọlọpọ eniyan si ngboju le awọn ti a daruko wọnyi. Eyi lo si fa ki awọn obilẹjẹ wọnyi rira wọn gẹgẹ bi olugbala fun ọmọ arayẹ ti wọn si nfi irọ pipa jẹ owo wọn lọna ti ko lẹtọ, wọn ni “O rẹsẹ wẹrẹ, o o buu ki fi se ògùn, igba wo lóó tóó ri tọlọgbọn”

            Ọpọ ninu awọn alasẹ ati onidajọ lọ gbara lewọn, asẹ ti wọn ba si pawọn di mimuşẹ, kódà ki o tako aşẹ Ọlọhun. Toripẹ ẹrò wọn ni pe ipo yii awọn ni wọn gbẹwọn debẹ wọn ti gbagbe pe Ọlọhun ni o nyanni sípò. Wo suratu Aliumrani: 26.

{قُلِ اللَّهُمَّ مَالِكَ الْمُلْكِ تُؤْتِي الْمُلْكَ مَنْ تَشَاءُ وَتَنْزِعُ الْمُلْكَ مِمَّنْ تَشَاءُ وَتُعِزُّ مَنْ تَشَاءُ وَتُذِلُّ مَنْ تَشَاءُ بِيَدِكَ الْخَيْرُ إِنَّكَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِير}.ٌ

“Wipe Ọlọhun olukapa ijọba, Irẹ lo maa n fi ijọba fun ẹniti oba fẹ Irẹ  ni o si maa n gba ijọba kuro lọwọ ẹniti oba fẹ, Irẹ ni n fun ẹniti o ba fẹ ni iyi Irẹ ni o si nyẹpẹrẹ ẹniti o ba fẹ, lọwọ Rẹ ni gbogbo oun rere wa Irẹ ni alagbara lori gbogbo nkan”

Bakanna lọrọ seri lọdọ awọn onisowo wọn ko le raja tabi taja ayafi pẹlu imoran wọn, iyawo ile to lori ọkọ rẹ nkọ? Sẹbi isẹ ọwọ wọn naa ni. Mẹlọ ni a fẹẹ ka ninu ẹyin adepele. Ọlọhun ti salayẹ wipẹ kikọ nipa idan iwa keferi ni. Wo Suratul Bakora: 102. Kódà keferi kò ni jere wo suratu Toha: 69.

"وَلا يُفْلِحُ السَّاحِرُ حَيْثُ أَتَى".

 Ojisẹ Ọlọhun sọ pe: ẹ jinna si awọn ẹsẹ apanirun meje, awọn sahabe sọ pe awọn ẹsẹ wo ni awọn ẹsẹ naa irẹ ojisẹ Ọlọhun? O si sọ pe: ẹbọ sise sọlọhun, idan pipa, jijẹ owo ọmọ orukan, sisagun, didirọ sina mọ obinrin ti o sọ abẹ rẹ, ti ko si mo nipa sina ti o tun jẹ onigbagbọ òdodo: Wọn tun bere nipa awọn adagbigba, o si dawọn lohun pe wọn ko jẹ nkankan, niwọn ba sọ pe: wọn ma ma nsọro lawọn àsìkò kan ti yoo si jẹ òdodo? Ojisẹ Ọlọhun ba sọ pe gbolohun òdodo yẹn jẹ ẹyiti alujannu jigbọ ni sanmo ti o si sọ fun orẹ rẹ, ni oun naa yoo ba pa ọgọrun irọ mọ ọ. Ojisẹ Ọlọhun tun sọ pe kosi ninu wa, ẹniti o ba nro ero buruku si eniyan, tabi wọn ro ero buruku sii, tabi o ndagbigba, o nwosẹ fun ẹniyan tabi wọn wo sẹ fun oun naa tabi o padan (sasi) eniyan, tabi wọn ba sa si eniyan, ẹniti o ba relé adagbigba to si gba ohun ti o sọ gbọ lódodo, onitọhun ti se keferi (aigbagbọ) si ohun ti Ọlọhun sọkalẹ fun anobi Muhammadi (Alkurani). Idajọ adagbigba, opidan ati aworawọ labẹ ofin Ọlọhun ni gígé ori rẹ pẹlu ida, gẹgẹ bi o se rinlẹ lati ọdọ ọpọlọpọ ninu awọn sahabe.

            Iwọnyi ni diẹ ninu awọn ewu, inira ati aburu ti didagbigba, wiwosẹ ati didahunsẹ nbi si awujọ.

1.         Jija ímánì gba kurò lọdọ awọn ti wọn nlọ si ọdọ wọn

2.         Pipọ ati fifọnka iwa ipaniyan laarin awujọ to fi dori jijinigbe, fifini soogun owo, tita ẹya ara eniyan.

3.         Gbigbilẹ sina sise ati awọn iwa kotọ.

4.         Jijẹ owo ọmọniyan lọna ti ko lẹtọ toripe gbogbo owo ti adagbigba ba gba lori isẹ rẹ owo ti ko lẹtọ ni gẹgẹ ojisẹ Ọlọhun se yanana rẹ.

5.         Sisọ awọn ẹniyan di ẹni anu, pokii ati obilẹjẹ.

6.         Bẹẹni o nse okunfa ibinu Ọlọhun si awujọ, wọn bi ojisẹ Ọlọhun leere pe: Njẹ Ọlọhun le run wa ti awọn ẹni rere si nbẹ ni aarin wa? O ni bẹẹni nigbati aburu yin ba ti pọju.

            Ẹyin ẹrusin Ọlọhun diẹ ni ẹyi ti ẹ gbọ tan yẹn ninu awọn ewu to rọ mọ didagbigba. Idi abajọ niyi ti o fi jẹ pe, o yẹ ki a dojukọ Ọlọhun olunikapa lori gbogbo nkan, ẹniti Ọlọhun ba fun, ko si ẹniti o le kọ fun un, ẹniti o ba si kọ fun-un kosi ẹniti o le fun un. Ọlọhun naa lo ni ki a maa ke pe Oun, o si se adẹhun pe Oun yoo maa jẹpe ẹniti o ba pe Oun pẹlu afọmọ ati ifọkansin. Oun koni ra isẹ rẹ lare, bẹni koni foju adua rẹ gbolẹ, sebi Oun ni o nse ijẹ-imu fun ẹyẹ ati ẹja wo suratu Ibrọhim: 32.

"اللّهُ الَّذِي خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالأَرْضَ وَأَنزَلَ مِنَ السَّمَاء مَاء فَأَخْرَجَ بِهِ مِنَ الثَّمَرَاتِ رِزْقًا لَّكُمْ وَسَخَّرَ لَكُمُ الْفُلْكَ لِتَجْرِيَ فِي الْبَحْرِ بِأَمْرِهِ وَسَخَّرَ لَكُمُ الأَنْهَار".

Ọlọhun ni Ẹniti o se ẹda sanman ati ilẹ O si n sọ omi kalẹ lati sanman Osi fi nmu awọn eso jade ni ipese fun nyin ki o le maa rin lori omi pẹlu asẹ Rẹ O si tun tẹ awọn odo sisan lori ba fun yin) 

  Torinaa, irẹ ti o nwa ijẹ imu irọrun, waa si ọdọ Ọlọhun, wo suratul Ankabuti: 17.

{إِنَّ الَّذِينَ تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ لا يَمْلِكُونَ لَكُمْ رِزْقاً فَابْتَغُوا عِنْدَ اللَّهِ الرِّزْقَ وَاعْبُدُوهُ}.

            (Dajudaju awọn ẹniti ẹnyin nsin lẹhin Ọlọhun koni ikapa arisiki kan fun nyin nitorinaa, ẹ wa arisiki (ese) lọdọ Ọlọhun ki ẹ si sin In).

Bẹeni iwọ ti o nwa ọmọ lọkunrin ati lobinrin fi adua anọbi Sakariyahu beere ọmọ lọdọ Ọlọhun, wo suratu Alimrani: 38.

{هُنَالِكَ دَعَا زَكَرِيَّا رَبَّهُ قَالَ رَبِّ هَبْ لِي مِنْ لَدُنْكَ ذُرِّيَّةً طَيِّبَةً إِنَّكَ سَمِيعُ الدُّعَاء}.

(Ibẹ naa ni Sakariya ti kepe Oluwa rẹ O wipe Oluwa mi! tami lọrẹ ọmọ daradara kan dajudaju Irẹ ni Olugbọ ipe)

 Tofi dori irẹ ti o nwa ipo bere rẹ lọdọ Ọlọhun. Wo suratul Bakorah: 186.

وَإِذَا سَأَلَكَ عِبَادِي عَنِّي فَإِنِّي قَرِيبٌ أُجِيبُ دَعْوَةَ الدَّاعِ إِذَا دَعَانِ فَلْيَسْتَجِيبُواْ لِى وَلْيُؤْمِنُواْ بِى لَعَلَّهُمْ يَرْشُدُونَ).

            (Nigbati awọn ẹrusin Mi ba bi ọ lere nipa Mi dajudaju Emi njẹ ipe nigbati o ba pe Mi ki nwọn si gba Mi gbọ ki nwọn le ba mọ ọna ti o tọ)

            Ojusẹ tolóri tẹlẹmu wa ni ki a wa bi a o se le awọn  ẹniyan buruku yii lawujọ, pẹlu fifunlẹ mọ wọn, yiyan wọn lodi, titakete si wọn, ki a ma yawọn  nile gbe tabi isọ itaja, ki a ma pọn wọn le, toripe ẹni ilẹ niwọn ti a kii tẹni fun. Ki awọn alasẹ si lo Idajọ Ọlọhun le wọn lori. Kikuna lati sẹ bẹẹ ibinu ati ìyà Ọlọhun la nwa o, wo suratu Maidati: 79.

            Ojisẹ Ọlọhun sọ pe bi awọn ẹniyan ba ri ohun ti kódàra ti wọn kosi kọọ (yii pada) o ku sátà ki Ọlọhun fiya kari gbogbo wọn.

            Ẹyin ẹrusin Ọlọhun ẹ tuba, ẹ ronu pawada, ẹ tọrọ idarijin ẹsẹ lọdọ Ọlọhun, ẹ gbara lee nibi gbogbo alamọri yin, ki ẹ si di awọn ilana ẹtọ tỌlọhun la kalẹ ati awọn  ti o jẹ ẹtọ ninu ẹtọ ile aye mun, ẹ jinna si ẹsẹ, ẹ maa tẹlẹ asẹ Ọlọhun, ki si ẹ daabo bo ẹsin yin ati igbagbọ yin, ilé aye, ilé isẹ ni, ti ko ni ìsirò ninu, sugbọn ọjọ alukiyamọ, ọjọ ìsirò ni, ti ko ni isẹ sise ninu.

Nitorinaa, ẹ bẹru Ọlọhun, ẹyin ẹrusin Ọlọhun , ki ẹ si mojuto igbagbọ yin ẹ sọ ọ daadaa ki ẹ si ma bajẹ, kódà ki ẹ mojutoo ju bi  ẹ se nmojuto alafia ara yin lọ ,Yoruba ni “Oore kinni ipa sedi” anfani wo ni o nbẹ fun eniyan to lalafia ninu ara sugbọn ti igbagbọ rẹ nsaarẹ. Bi ara ba ni alafia sugbọn ti igbagbọ ẹniti o nii nsaarẹ, ofo ni adanu si ni laye ati lọrun, toripe “Dajudaju Ọlọhun ki yoo se aforiji nipa ki a baa wa ẹgbẹ, o si nse aforiji ohun ti o yatọ sii, eyini fun ẹni ti o ba wu u ẹnikẹni ti o ba ba Ọlọhun wa ẹgbẹ, dajudaju o ti sina ti o jinna”.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun “Dajudaju Ọlọhun npa wa lasẹ ẹtọ sise ati isẹ rere ati ki a ma fun awọn ẹbi (ni ẹtọ wọn) o si nkọ fun ni iwa ibajẹ ati iwa buruku ati rukerudo .O nse ikilọ fun nyin ki ẹ le ba gba ikilọ ati ki ẹ maa mu adehun Ọlọhun sẹ nigbati ẹnyin ba se adehun, ati ki ẹ ma si tu ara bubu nyin palẹ lẹhin igbati ẹ ti se e, bẹ si ni ẹ ti se Ọlọhun ni ẹlẹri le ara nyin lori. Dajudaju Ọlọhun mọ ohun ti ẹ nse ni isẹ.

فاتقوا الله - عباد الله -  وعليكم بالتمسك بكتاب الله وسنة رسول الله  وما عليه جماعة المسلين ... فإن خير الحديث كتاب الله  وخير الهدي هدي محمد صلّى الله عليه وسلم, وشرّ الأمور محدثاتها وعليكم  بالجماعة فإن يد الله مع الجماعة , ومن شذ شذ في النار. إن الله وملائكته يصلّون على النّبي يا أيها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلموا تسليم اللهم صلّ على عبدك ورسولك محمد , وارض اللهم عن الخلفاء الراشدين أبي بكر وعمر وعثمان وعلي وعن الصحابة أجمعين.

عباد الله إن الله يأمر بالعدل والإحسان وإيتاء ذي القربى وينهى  عن الفحشاء  والمنكر والبغي يعظكم لعلكم  تذكرون وأوفوا بعهد الله إذا عاهدتم  ولاتنقضوا الأيمان  بعد توكيدها  وقد جعلتم الله عليكم  كفيلا إن الله يعلم ماتفعلون .