islamkingdomfacebook


IRUN JÀNMÓÒ, PATAKI RẸ, ỌLÁ (ẸSAN) RẸ,ẸKỌ RẸ ATI AWỌN IDAJỌ TO KÓ SINU

IRUN JÀNMÓÒ, PATAKI RẸ, ỌLÁ (ẸSAN) RẸ,ẸKỌ RẸ ATI AWỌN IDAJỌ TO KÓ SINU

6901
Eko ni soki
Irun janmoo je ohun ti laada re po jaburata ju irun ti eniyan ba da ki ninu ile tabi soobu re lo,Anobi ki ike ati ola Olohun maa ba se alaye ije oranyan irun janmoo o si tun gbe awa omoleyinyin longbe lati moju too debi wipe Anobi gba afoju ti o wa beere lowa fun ede ni imoran wipe ki O ma lo ki irun re ni janmoo lodiwon ti o ba ti ngbon ipepe iru.

1.         Àlàyé nipa pe irun janmọ jẹ àmì to pataki ninu awọn àmì ninu ẹsin Isilaamu.

2.         Àlàyé titori ti Ọlọhun fi fi irun janmọ lọlẹ (see lofin)

3.         Yiyànànà pipataki irun janmọ ati ọla (ẹsan) to mbẹ fun ati awọn anfani rẹ

4.         Àlàyé awọn ẹkọ irun janmọ ati awọn ẹkọ to rọ mọọ

5.         Àlàyé ipa rere ti irun janmọ yoo ko ninu igbesi aye ẹnikọkan ati awujọ lapapọ

 

KHUTUBA ALAKỌKỌ - Ogun Isẹju

  الحمد لله رب العالمين  أمرنا بالإجتماع على دينه والاعتصام  بحبله ونهانا عن التفرق والاختلاف , لما في الإجتماع من  القوّة  والألفة , وما في الافتراق من الضعف والنفرة , أحمده على نعمة الإسلام, وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له شهادة تنفتح لمن قالها صادقا دارا السلام, وأشهد أن محمدا  عبده ورسوله إلى جميع الأنام صلّى الله عليه وعلى آله وأصحابه البررة الكرام وسلم تسليما كثيرا على الدوام . أما بعد

A da ọpe fun Ọlọhun  ọba to da gbogbo ẹda, o pawa lasẹ pe ki a pejọ nidi ẹsin Rẹ, bẹni o si pawa lasẹ lati di okun Rẹ tii se Alkur’ani mun sinkun, bẹni o se pinpinya ati iyapa- ẹnu leewọ fun wa, o pawa lase isọkan, tori ki a le lagbara lori ọta, ki irẹpọ si le wa laarin wa, gẹgẹ bi o se se ipinyẹlẹyẹlẹ, se tirẹ ki n se temi leewọ, ki a mọ baa lẹ ni, se wọn ni: Àpọn sùn lọọri tara rẹ ni wọn nlọ fun un. Mo dupe lọwọ Ọlọhun fun ọga ore Rẹ lori wa, ti o sewa ni musulumi, mo jẹri pe ọkan soso ni Ọlọhun nibi ijọsin, ko lorogun ko lẹgbẹra, ni ẹri ti Ọlọhun yoo fi fi ẹniti o ba jẹẹ sinu ile ọla. bẹẹni mo jẹri pe Anọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun  ni, ojisẹ Rẹ si ni, o ran an si gbogbo ẹda lapapọ, ikẹ ati  ọla Ọlọhun ki o maa baa, ati ara ile rẹ ati awọn ẹmẹwa rẹ ti wọn jẹ enirere, eni apọnle ni ikẹ ati ọla ti o pọ, ti yoo si maa bẹ gbére.

Anọbi (SAW) sọ pe: “Wọn mọ Isilaamu lori òpó marun-un; afirinlẹ pe: ko si ẹlomiran ti a le jọsin fun-un lódodo ayafi Ọlọhun, ati pe anọbi Muhammed ojise Rẹ ni, gbigbe irunduro, yiyọ sàká owó, gbigbaa aawẹ Rọmadàna ati sise haji lọ si ile Oluwa.

Nitorinaa, irun kiki jẹ òpó pataki ninu ẹsin lẹyin ijẹri (ìgbàgbọ) mejeeji.

Ọlọhun pèsè oore nla fun ẹniti o ba nkirun, Anobi Muhammedi (SAW) sọ pe: “Kiki irun kan lẹhin ọkan, ti kosi ọrọ kọrọ larin wọn, Ọlọhun yoo fi ẹsan oluwa rẹ si àyè gìga.

Mọsalasi laa tii ki irun janmọ, kódà bi odidi ilu kan ba gbee silẹ lai kii ni janmọ sẹria ni ki a gbógun tiwọn, tabi awọn ara adùgbò kan lo ba gbee ju silẹ, sẹria ni ki a jewọn nipa léè lori, bẹẹ si ni ẹnu awọn afa àgbàágbà ko lori pe ki a ki janmọ ni mọsalasi ninu ohun to kanpa ju lati fi tẹle Ọlọhun tabi lati fi sun mọ Ọ ni.

O si jẹ okunfa irẹpọ, aanu ìsàkòlékàn ati ifẹ laarin musulumi, o si máa nfa ki wọn mọ ẹniti ti ara rẹ kọya ati ẹniti o bukaata si iranlọwọ lati se ẹtọ fun un.

Bakanna ni o nse afihan agbara musulumi, a maa jẹki wọn o mọ araawọn lati le pa ọwọ pọ diya jẹ keferi ati olojumeji nidi ẹsin.

Anọbi Muhammad sọ pe: Ẹ ma yapa ara yin ki iyapa ọkan ma baa sẹlẹ si yin.

Ọranyan ni irun janmọ jẹ fun musulumi lọkunrin, onile tabi alejo lasiko irọrun ati ipaya tori rẹ ni wọn se se agbekalẹ kikọ mọsalasi, yiyan aperun, asiwaju ninu irun ati pipe ìrun soke dárara, gẹgẹ bi ẹri sewa ni suratul Nisai: 102.

{ وَإِذَا كُنتَ فِيهِمْ فَأَقَمْتَ لَهُمُ الصَّلاَةَ فَلْتَقُمْ طَآئِفَةٌ مِّنْهُمْ مَّعَكَ وَلْيَأْخُذُواْ أَسْلِحَتَهُمْ فَإِذَا سَجَدُواْ فَلْيَكُونُواْ مِن وَرَآئِكُمْ وَلْتَأْتِ طَآئِفَةٌ أُخْرَى لَمْ يُصَلُّواْ فَلْيُصَلُّواْ مَعَكَ وَلْيَأْخُذُواْ حِذْرَهُمْ وَأَسْلِحَتَهُمْ وَدَّ الَّذِينَ كَفَرُواْ لَوْ تَغْفُلُونَ عَنْ أَسْلِحَتِكُمْ وَأَمْتِعَتِكُمْ فَيَمِيلُونَ عَلَيْكُمْ مَّيْلَةً وَاحِدَةً وَلاَ جُنَاحَ عَلَيْكُمْ إِن كَانَ بِكُمْ أَذًى مِّن مَّطَرٍ أَوْ كُنتُمْ مَّرْضَى أَن تَضَعُواْ أَسْلِحَتَكُمْ وَخُذُواْ حِذْرَكُمْ إِنَّ اللَّهَ أَعَدَّ لِلْكَافِرِينَ عَذَاباً مُّهِيناً }.

 Anọbi Muhammad (SAW) sọ pe: Wọn o ba lọ kódà bo se kànrà, mo ti pinnu ki enikan gberun duro ki enikan si kirun fun awọn eeeyan ki awọn kan si lọọ ko igi ìsépé tẹle mi, lati lọ dànà sun awọn ti nkirun ninu ile mọle”. O tun sọ pe: Ẹniba kirun Isai ni janmọ, bi igbati o fi idaji òru kirun ni, ẹniba kirun asunba ni janmọ bi igbati o fi gbogbo òru rẹ yan nofilat ni.

Mọsalasi ni aye ikojọ fun irun, kiki rẹ niwaju ile tabi sọọbu (isọ) itaja, yoo fa ki mọsalasi dahoro, ati ipinyẹlẹ-yẹlẹ musulumi eyi ti Isilaamu gbogun ti, ko da yoo fa ki laada Oluwa re kere jọjọ, Wo  Nuru 36 – 37 ati suratul Taoba:18.

"فِي بُيُوتٍ أَذِنَ اللَّهُ أَن تُرْفَعَ وَيُذْكَرَ فِيهَا اسْمُهُ يُسَبِّحُ لَهُ فِيهَا بِالْغُدُوِّ وَالأصَالِ (36) رِجَالٌ لا تُلْهِيهِمْ تِجَارَةٌ وَلا بَيْعٌ عَن ذِكْرِ اللَّهِ وَإِقَامِ الصَّلاةِ وَإِيتَاء الزَّكَاةِ يَخَافُونَ يَوْمًا تَتَقَلَّبُ فِيهِ الْقُلُوبُ وَالأبْصَار".

Gbogbo ohun ti o ba le sọ mọsalasi dahoro ni musulumi gbọdọ jinna si, tori ileri iya ti Ọlọhun se fun Oluwa rẹ, wo suratul Bakora 114 ati suratul Nuru 24.

{وَمَنْ أَظْلَمُ مِمّنْ مَنَعَ مَسَاجِدَ اللهِ أَنْ يُذْكَرَ فِيهَا اسْمُهُ وَسَعَى فِى خَرَابِهَا}.

 

Wọn ni isọrọọ-yan-rọ lo pa baalẹ ajẹkókóró to ni ibiti mo ba nju isu si ni ki ẹ maa gu-un.

Ko buru ko si lẹsẹ , ki awọn eeyan pejọ kirun laaye kan bi laluri ba faa.

Irun janmọ bẹrẹ lori eeyan meji, okunrin meji tabi okunrin kan obinrin kan. Anọbi Muhammad sọ pe: .. Taa ni yoo se sàára fun okunrin yii? Lokunrin kan ba dide, o si kirun pẹlu rẹ, lanọbi ba sọ pe awọn mejeeji yii janma ni wọn”.

Tokunrin meji ba fẹẹ kirun, olutẹle imamu yoo duro si apa ọtun-un rẹ. to ba si je okunrin kan obinrin kan, obinrin yoo duro si ẹyin, kódà ki o jẹ iyawo fun

Okunrin to siwaju. To rii adisi anasi to sọ pe: Ojisẹ Ọlọhun kirun fun wa lori itẹ ikirun kan, o si fi mi si apa ọtun rẹ, bẹẹni o ni ki Umu Sulaim ati Umu àràmù bọ si ẹyin wa.”

Títo sáfú yoo maa bẹrẹ ni ọgangan ẹyin lmamu lọ apa ọtun imam ,titi ti yoo fi pin, lẹhin naa, lati apa osi rẹ titi ohun naa yoo fi pin, bayi ni wọn yoo se maa to sáfú yoku . Sáfú alakọkọ yoo fi pe ,ki ẹ si fi iyọku tẹlee”.

Won fẹ  kọjẹpe awon Ọlọgbọn eeyan ti wọn si nimọ nipa ẹsin, ni won yoo wa ni safu alakọkọ ,ti awọn ọmọde yoo si wa ni ẹyin .

Obinrin lẹto lilọ mọsalasi, tọkọ rẹ ba yọnda fun-un, ti ko si lo lọfinda oloorun didun, ti ko sira silẹ, ti ko si si ìwọnubọnu (dàrúdàpọ), fidi gbọdi laarin wọn ati ọkunrin, ẹyin si ni safu ti wọn yoo wa, ti koba si gaga ni mọsalasi. Sugbọn ti gàgà bà wa, sáfu àkọkọ lẹyin lo fi n dára jùlo, toripe àwọn obinrin màa   nlọ si mọsalasi nigba ayé anọbi

1.         Awọn mọsalasi mẹta ni mọsalasi to lọla julọ ninu gbogbo mọsalasi aye: Mosalasi Àràmi ni mọkka, tanọbi ni mọdina ati mọsalasi akisọ ni Jerusalẹmu.

2.         Eyiti o dara julọ fun musulumi ni ko kirun ni mọsalasi to se pe bi wọn o rii, wọn o nii ki janmọ, ko le ni lada awọn ti wọn nmojuto mọsalasi Ọlọhun. Wo suratul Taoba: 18.

{إِنَّمَا يَعْمُرُ مَسَاجِدَ اللَّهِ مَنْ آمَنَ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ وَأَقَامَ الصَّلاةَ وَآتَى الزَّكَاةَ وَلَمْ يَخْشَ إِلَّا اللَّهَ فَعَسَى أُولَئِكَ أَنْ يَكُونُوا مِنَ الْمُهْتَدِينَ}.

3.         Lẹyin naa ni mọsalasi ti èrò ba ti maa npọ julọ, toripe ibẹ ni laada ti ma npọ ju. Anọbi (SAW) sọ pe ki ẹnikan ki irun pẹlu enikeji rẹ lọla ju ki o darun ki lọ, bẹẹni ki o kii pẹlu eeyan meji lọla ju ko kii pẹlu ẹnikan lọ, kosi kii pẹlu eeyan pupọ, lọlọhun nifẹ julọ.

Ati toripe aanu Ọlọhun ati ikẹ Rẹ maa jẹ ki adua tètè maa n gbà, àgàgà bi awọn onimimọ ati awọn  ẹni rere ba mbẹ ninu wọn,  wo Suratu Taoba 108.

4.         Lẹyin naa ni mọsalasi tọ ba sunmọ eeyan julọ, toripe, o lẹtọọ si iwọ aladugbo julọ, ati wipe fifi silẹ lọ si ibi to jinna le da họuhọu silẹ laarin awọn aladugbo rẹ, o si lee mu wọn dẹsẹ, to ri wọn yoo maa ro èrò buruku sii.

 

Ti musulumi ba nlọ si mọsalasi, o gbudọ sakiyesi awọn ẹkọ ti anọbi kọ wa, ninu rẹ ni:

1.         Pẹlẹpẹlẹ ati itẹriba, ibẹru Ọlọhun ati ìpayà Rẹ.

2.         Eewọ ni fun ẹnikẹni lati siwaju kirun, lalae jẹ pe oun ni Imam, ti imam ko si yọnda fun un lati se bẹẹ. Anọbi Muhammad sọ pe: “Enikẹni kò gbọdọ siwaju kirun laye alaye ayafi pẹlu iyọnda ẹni to laye. (Imam aye naa).

3.         Wọn fẹ ki ẹniti o darun ki tabi to kirun pẹlu janmọ kekere pada kirun pẹlu janmọ to pọ, anọbi sọ pe kirun ni àkókó rẹ, ti o ba si bawọn ni mọsalasi ti wọn nkirun, ki irun pẹlu wọn, masọ wipe  mo ti kirun”. A jẹ pe ẹlẹẹkeji yoo jẹ nọfila fun-un.

Anobi sọ pe: “toripe ẹẹkeji yoo jẹ Nọfila fun-un yin atipe jijoko rẹ le da wahala ati èrò buburu si ọkan awọn eeyan.

4.         Bi wọn ba ti gberun duro, ẹnikankan ko tun gbọdọ yan nọfilat mọ, ayafi ẹniti o ti nki irun lọ, to ku diẹ ti yoo kii tan. Anọbi sọ pe: Ti wọn ba ti gbe ìrun duro, wọn ko gbudọ kirun miran yatọ si eyiti wọn gbe duro-un.

5.         Ti ẹnikan ba si nyan nọfila lọwọ, ti wọn wa gberun duro, ki o yara pari rẹ, ko si gbudọ daa duro ayafi to ba mbẹru ki janmọ ma bọọ mọ oun lọwọ, toripe irun ọranyan lo pataki julọ. Wo surat Muhammad; 33.

6.         Sise asikiri siwaju tabi lẹyin ikamọ, bii lailha illa Allahu, tabi asalatu fun anọbi Muhammad, tabi wiwohin-wọhun lori irun gbogbo nkan wọnyi, lo yẹ ki olukirun jinna si.

Ni ipari, ka tara wa aforijin ati ikẹ Ọlọhun, ka si se alápàántèté lọ ibi isẹ oloore, ki a le ko Ọlọhun nifa. Ki ikẹ ati igẹ maa ba anọbi ati awọn ara ile rẹ, gbogbo awọn saabẹ rẹ ati gbogbo alatẹlee rẹ titi di ọjọ alikiyamọ.

Nipari, ẹ bẹru Ọlọhun nibi gbogbo alamọri yin, ki ẹ si sakolekan irun ni kiki, toripe opo ẹsin nii se, ẹ ma si pa mọsalasi laayun, ẹ maa loo fun ijọsin fọlọhun ati titele asẹ Rẹ ki ọlọhun le kẹyin, Alkurani ni ọrọ to dara julọ, ilana Anọbi si ni ilana to dara julọ, adadaalẹ ninu ẹsin buru pupọ, gbogbo adadaalẹ anú ni, ẹ si maa wa pẹlu janmọọ musulumi, toripe Ọlọhun mbẹ pẹlu janmọọ, ẹniba dayejẹ yoo daya jẹ. Ẹ mo gbagbe asẹ tỌlọhun pawá pe, ki a maa se asalatu fun anọbi wa Muhammed, leyiti Oun gan ati awọn mọlaika Rẹ ti se siwaju Ọlọhun sọ pe: Dajudaju Ọlọhun ati awọn malaika Rẹ nfi ibukun fun Annọbi 

Ẹyin ti ẹ gbagbọ ni ododo, ẹ ma tọrọ ibukun fun un, ki ẹ si ki ni kiki alafia”. Ọlọhun bani se ikẹ ati igẹ fun ẹru Rẹ ati ojisẹ Rẹ , Annọbi wa Muhammad, bakanna ki Ọlọhun  ba wa yọnu si awọn arole rẹ ti wọn jẹ afinimọna Abu-Bakar, Umaru, Usman ati Aliy ati awọn sahabe toku lapapọ. Ọlọhun gbe ewu agbara wọ Isilaamu ati musulumi lọrun , ki o si bawa run gbogbo ọta ẹsin , Ọlọhun rọ ojo ifọkanbalẹ si ilu wa ati gbogbo ilu Isilaamu lapapọọ, Irẹ Oluwa ati Olutọjuuwa gbọ adura wa.

 

فاتقوا الله عباد الله وأقبلوا على المساجد واعمروها بذكر الله وطاعته لعلكم ترحمون إن الله وملائكته يصلّون على النّبي يأيها الذين آمنوا صلّوا عليه وسلموا تسليما اللهم صلّ وسلم على عبدك ونبيك محمد بن عبد الله وارض اللهم عن خلفائه الراشدين أبي بكر وعمر  وعثمان  وعلي وعن الصحابه أجمعين وعنا معهم  برحمتك ياأرحم الراحمين.