islamkingdomfacebook


SÀKÁ ÌTÚNU AWẸ (JÁKÀ) ÀTI ÌRUN ỌDÚN

SÀKÁ ÌTÚNU AWẸ (JÁKÀ) ÀTI ÌRUN ỌDÚN

5491
Eko ni soki
Dajudaju, Olohun oba alaponle se awon ijosin ti o gbongbon lofin fun wa ni ipari osu Ramadan, eleyiti igbagbo yio maa lekun pelu re, ti yio si maa mu ijosin pee, ti idera yio si maa di pipe pelu re, eleyii naa ni jaka itunu aawe ni yiyo, ati irun odun, Olohun se jaka itunu aawe lofin fun wa lati lee je imora fun eniti o ngba aawe nibi awon asiwi ati isokukuso, ati lati je ounje fun awon alaini, o si fi awon majemu ati idajo lele fun un, O si se irun odun lofin fun wa lati se afihan agbara ati isokan awon musulumi ati idapo won.

 

(SAKATUL FITIRI WASOLATULI IDI)

Erongba Kuthuba

1.      Àlàye ohun to pọn dandan fún Musulumi láti se lẹyin ìparí àwẹ

2.      Àlàyé nípa ìgbárùkù ti Ara ẹni

3.      Àlàyé nípa ìdájọ ìrun yídì ati idi pàtàkì tí a fi nkii.

الحمد لله الذي  بنعمته تتم الصالحات , جعل لكل موجود  في هذه الدنيا زوالا, ولكل مقيم انتقالا ليعتبر بذلك أهل الإيمان  فبادروا بالأعمال , مادمتم في زمن الإمهال , ولا تغتروا بطول الآمال  وأشهد أن  لا إله إلا الله وحده لا شريك له الكبير المتعال , وأشهد أن محمدا عبده ورسوله القائل "بادروا  بالأعمال " صلّ الله عليه وعلى آله وأصحابه خير صحب  وآل , وسلم تسليما كثيرا... أما بعد/

         Ọpẹ ni fỌlọhun ọba to se wipe pẹlu iranlọwọ rẹ ni gbobo nkan fi nyọ ri si rere, Mo jẹri pe ko si ẹniti ijọsin tọ si, tayọ Ọlọhun nikan soso, ọba ti ko lorogun, toto fun un Oluwa rẹ. Mo si tun jẹri pe Anọbi wa Muhammadu ẹrusin Ọlọhun ni ojisẹ Rẹ si ni, O se wa loju ọyin sibi isẹ rere, bẹẹni o kilọ fun wa, nibi yiyapa ase Ọlọhun ati dida ẹsẹ, ki Ọlọhun bani kẹ Annọbi wa ati awọn ara ile rẹ ati awọn to sugba rẹ (sahabe) ti wọn jẹ ẹnirere ẹnipataki, ki ikẹ naa pọ, ki o si se gbere ati ọla naa.

Ẹyin erúsin Ọlọhun, ẹ bẹrù Olúwa yín, e si se ìsiro ohun ti ẹ gbése ninu osù (Rọmadana) ti o nlọ yii, o dabi àlejò tí àtilọ rẹ ti súnmọ, ki ẹ ránti pe yoo jẹri gbé yin tàbí kó takò yín, nipa ohun ti ẹ gbé inú rẹ se nísẹ, nitorinaa, ẹ tara lo èyití ti ó sẹkù ninu rẹ fun ìtúúbá kuro ninu ẹsẹ, ki ẹ si tọrọ àforíjìn, ki ẹ si múra si sisẹ rere, ki Ọlọhun le fi di awon àseètó tó ti síwájú.

Eyin ẹrúsin Ọlọhun, Ọlọhun se afilọlẹ awọn ijọsin kan fun yin lọwọ ipari awẹ yii, ki ẹ le lekun lẹsan. Awọn ijọsin naa ni: yíyọ jàkà, gbígbé Ọlọhun tobi ati kíkí ìrun yídì. Ẹ ẹ rì jàká, oun ni sàká tí a màa n yọ nínú onje ní ọwọ ìparí àwẹ rọmadana. Ẹnu àwọn àfàá-àgbá kò lórí wipe òranyàn ni yiyọ rẹ, ni ibamu si adisii ibnu Umar ti o sọ pe: Ojis Ọlọhun se jàká yíyọ ni òranyàn lórí gbogbo ènìyan, ki wọn yọ mudu mẹrin nínú (sẹiru), òranyàn ni yíyọ rẹ jẹ lórí gbogbo ọmọlúàbí àti ẹrú, okunrin tabi obinrin to jẹ Mùsùlùmí.

          Jàká yiyọ wà fún ífọ-aláàwẹ mọ kúrò nínú ísọkúsọ, ìwokuwo, ẹsẹ kéé-kéé-kéé. Abdul-lahi ọmọ Abasi sọ pé Òjísé Ọlọhun se yíyọ jàká lọranyan kí o le fọ alàáwẹ mọ nibi isọkúsọ, ísekúse, àti àjeyó fun awọn aláìní.

Bẹẹni jákà wa fun sise aanu àwọn aláíní àti làti rọ wọn lọrọ, dẹrin-in pa ẹrẹkẹ wọn, lọjọ ọdún.

          Mùsùlùmí ni yíó yọ jàká, kíì se kèfèrí, kódà kó ní awọn Mùsùlùmí tó n bọ làbẹ, kò jẹ dandan fún un làti yọọ, torípé íjọsin pàtàkì ni nínú Isilamu kíì se òranyàn fún ẹniti kíì se Mùsùlùmí.

          Ọmọluàbí nii yọ jàká kíì se ẹrú torípé ẹrú kòní owó lọwọ, sugbọn ọga rẹ ni yoo bàa yọ ọ. Òjíse Ọlọhun sọ pe: Ẹ yọ jàká gbogbo ọmọluàbí àti ẹrú tí ẹ n bọ.O gbudọ ní owó tí yíó toó nà ní ànásẹkú súlẹ ọjọ ọdun, ki yiyọ jaka too di ọranyan lee lori.

          Akoko yiyọ gbudọ to ki o too yọọ, nigbati òòrun ba wọ ni alẹ ọjọ ti awẹ ba pari, ki o si yọọ ki o to ki irun yidi. Kò sí lẹtọ láti lọ yiyọ rẹ lára tayọ ọjọ ọdún, to bá se bẹẹ sàárà lásán ló se. Okúnrin tóbá lágbára láti yọọ yíó yọ ti ara rẹ, àti ti gbogbo àwon tóbá pọn dandan fun-un láti bọ ọ, bíi íyàwó àti ọmọ, kó da bí ọmọ nàá kò tíì tóó awẹ gbà, ẹrukunrin àti ẹrúbínrin àti ọmọọdọọ rẹ tori adisii to sọ pe: Bẹrẹ lori ẹmi ara rẹ, lẹhinaa kí ó fi àwọn tí ó n bọ tẹ le e, àti èyítí ó sọ pe: Ẹ yọ jàká gbogbo ọmọlúàbí àti ẹrú nínú àwọn tí ẹ nbọ.

Kíi se dandan láti yọ jaka oyún inu, súgbọn kò buru láti se bẹẹ. Múdù mẹrin tábí kílò méji ó lé 2.176kg ni yoo yọ gẹgẹ bíi jàká nínú èyí tó pọju nínú onjẹ ara ílú. Onjẹ ni yíó fi yọọ, àyàfi bí làlúrí kan bá faa lati fi owó yọọ lókú.

 


 

 

Ọlọhun se ọdún alálúbàríká méjì kan lófin fún ẹlẹsín Isilaamu, gbogbo ọdún nàá ló n wà lẹyín íjọsín pàtàkì àti orígun kan nínú ẹsín Isilaamu, ọpọ oore ọrọ, íbùkún àti ànfàní ló sodo sínú àwọn ọdún nàá. Òjísẹ Ọlọhun bèérè lọwọ àwọn arà mẹdínà, lẹyin ti ó dé bẹ to bá wọn tí wọn ya ọjọ méjì sọtọ láti fi seré pé: Sebí Ọlọhun ti fi ọjọ méjì to lóore jùwọn lọ ọdún ítúnu àwẹ àti iléyà dipo wọn.

Nígbati ó jẹ pè gbogbo ẹsín kọọkan lòní àwọn ọdún tí ó kó àwọn éròngbà ẹsin nàá ati awọn àmì sínú. Ọlọhun sọ pé: “Gbogbo ẹsìn kọọkan lóní ọdún un rẹ”.

Bakannaa ni ọdún tún kó ìgbàgbọ to mọ nípa Ọlọhun ní èyí tó tóbi júlọ nidẹra Rẹ lori èniyàn, gbígbé E tobi, yínyín In, sínsìn In. Bẹni yío fi àdúà Sise, írankàn wa ìrànlọwọ Rẹ. Wo suratul Jin 18:  Ọlọhun sọ pe:

"وأنّ المساجد لله فلا تدعوا مع الله أحدا"

"Atipe dajudaju awọn mọsalasi ti Ọlọhun ni wọn, nitorinaa, ki ẹnyin mase ke pe nkankan pẹlu Ọlọhun (nibẹ)". Jíjẹri pè ànọbì Muhammad ẹrú Ọlọhun nii, Ojisẹ Rẹ sì ni, pẹlu gbigba àwọn ìroo Rẹ gbọ lododo, ki a sì sin Ọlọhun pẹlú ìlànà Rẹ.

Àwẹ ọdún dá lóri iyẹpẹrẹ ara ẹni fọlọhun, ìfaragbolẹ ati ìnífẹẹ Rẹ, bẹẹni ò kó àlàyè òfin ẹsìn, ítún íwà ẹni se, jíjẹ onísùúrù, onifaradà alamojukuro ati fífọ ẹmí mọ níbi ílara kèèta, to tún n pa ni lasẹ írẹpọ, sisàánú ọmọnikeji.

قال تعالى: {وَاسْتَعِينُوا بِالصَّبْرِ وَالصَّلاةِ} [البقرة:45].

Ọlọhun se gbígbèetobi lofin, wo suratul Bakọra 45. Gbogbo eniyan ni Òjísẹ Ọlọhun pa lásẹ láti kírun lobinrin, adelebọ, ọmọge to fi dori ẹniti o nse nkan osù bí wọn ò tilẹ níí kírun, tí wọn ò si níí súnmọ ibùkìrun sugbọn kíwọn le farakó oore àti àdúà Músúlùmí gẹgẹ bí Úmù Àtíyá se gbàá wá.

Nitorinaa, ẹ túyááyá túyààyà lọsì papa lati kírun yídì lágbà lọmọdé lọkúnrin lobínrin, lati tẹlé àsẹ Ọlọhun ati ki á le ri oore rẹ gbà, ki Okunrin wọ èyítí ó dára júlọ ninu asọ rẹ, kó sí lo lọfínda oloorun dídun, sugbọn èèwọ ni láti wọ asọ àlàárìí tabi góòlù, bẹni ki awọn obinrin nàá lọ si yidi pẹlú ìtìjú, láláìní fi ọsọ hàn síta.

Ò dára púpọ làti jẹ dàbídùn mẹta, márùn-ún tàbi jú bẹẹ lọ, lórí ònkà tí kò seé fi eeji pín, láti fi kọ ise ànọbi wa (S.A.W) ní íbámu sí àdíìsì anasi wo Suratul Asab 21.

قال تعالى: { لَّقَدْ كَانَ لَكُمْ فِي رَسُولِ اللَّهِ أُسْوَةٌ حَسَنَةٌ لِّمَن كَانَ يَرْجُو اللَّهَ وَالْيَوْمَ الآخِرَ وَذَكَرَ اللَّهَ كَثِيراً } [الأحزاب:21].

 Ọlọhun sọ pe: “Dajudaju ikọse rere nbẹ fun nyin lara ojisẹ Ọlọhun fun ẹniti o nbẹru Ọlọhun ati ọjọ ikẹhin ti o si ranti Ọlọhun ni ọpọlọpọ (igba)”.

A nbẹ Ọlọhun kofi wa se kongẹ ifẹ ati iyọnu Rẹ ki o si se jaka yii ni iwa oju rere Rẹ nikansoso, ki o si tẹwọ gba ijọsin wa lẹsin fun wa, ki o si se alekun arisiki fun wa. Bẹẹni a si tọrọ lọdọ Rẹ ki o fi jaka yii rọ awọn alaini lọrọ nibi mimọ gbe gba bara kiri gẹgẹ bi ojisẹ Ọlọhun se sọ pe: "E fi jaka rọwọn lọrọ kuro nibi gbigbe gba bara dani lọjọ ọdun".

فاتقوا الله عباد  الله -  وأعتنوا بأخراجها  , أعوذ بالله من الشطيان الرجيم " قد أفلح من تزكى وذكر اسم ربه فصلى " (الاعلى : 14-15)