islamkingdomfacebook


IWỌNTUNWỌNSI PẸLU ẸRI LATI INU ALUKURANI ATI SUNNAH

IWỌNTUNWỌNSI PẸLU ẸRI LATI INU ALUKURANI ATI SUNNAH

4794
Eko ni soki
Esin Islam je esin iwontunwonsi, esin deede ati dogba, atiwipe, o wa ninu Alukurani Alaponle ati sunnah anabi, awon egbeoro ati awon hadiith ti o po ti o ntoka si iwontunwonsi esin Islam ati deede re, ati iwontunwonsi eleyiti ko si ikoja enu aala nibe nitori wipe o je ododo eleyi ti o so kale lati sanmo, kosi aseju nibe beeni ko si si aseetoo, kosi ikoja aala beeni kosi igewokuru, kosi kankankan beeni kosi ifirare, kosi awewa beeni kosi ifisefe nibe.

Awọn Erongba Lori Khutubah Naa:

1- Alaye lori bi iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) se jẹ ohun ti o se Pataki lati maa wa ninu Isilaamu.

2- Isilaamu jẹ ẹsin ti o ba àdámọ ọmọ eniyan mu

3- Ise ikilọ nipa aseju ati ijọngbọn sise nibi ẹsìn.

الحمد لله رب العالمين، والصلاة والسلام على أشرف الأنبياء وإمام المرسلين نبينا محمد وعلى آله وصحبه أجمعين. أما بعد/

فإن الله سبحانه وتعالى جعل أمة محمد صلى الله عليه وسلم خير الأمم، لذلك يقول: { كنتم خير أمة أخرجت للناس } ثم جعلها الله عز وجل أمة وسطاً شاهدة على الناس والأمم السابقة ولذلك يقول: { وكذلك جعلناكم أمة وسطاً } .فهم وسط في أمور الدين والحياة جميعاً.

 

Iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) ni ohun ti ijọ Annabi r ni bukata si lati jẹ bi Oluwa ti juwe wọn pe olujẹri ni wọn lori awọn eniyan gbogbo.

Ọrọ Oluwa lọ bayi pe:

كُنْتُمْ خَيْرَ أُمَّةٍ أُخْرِجَتْ لِلنَّاسِ تَأْمُرُونَ بِالْمَعْرُوفِ وَتَنْهَوْنَ عَنِ الْمُنْكَر [آل عمران : 110]

"Ẹyin ni ẹdara julọ ni ijọ ti a mu jade fun awọn eniyan; ti ẹ n pa awọn eniyan lasẹ lati maa se daradara, ti ẹsin kọ fun wọn lati se aburu". (Al-Imran: 110).

 

Gbobo awọn Annabi Ọlọhun patapata, iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) ni akori isẹ wọn. Annabi r jẹ ki o di mimọ pe: "Ohun ti o rọrun ni ẹsin (Isilaamu), bi ẹniyan ba si se aseju nipa ọrọ ẹsin yoo wulẹ da ara rẹ lagara lasan ni. Nitorinaa ẹ se ohun gobgbo ni iwọntún-wọnsì  … "   (Sahih al-Bukhari).

"إن الدين يسر ولن يشاد الدين أحد إلا غلبه فسددوا وقاربوا ..." رواه البخاري   

Ohun ti a n pe ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) ko pin si ọna kan soso.

v A gbọdọ wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipa ọrọ adisọkan ati irori .

v A gbọdọ wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipa ọrọ ijọsin . Ọlọhun sọ ninu AlQuran bayi pe:

وَلَا تَجْهَرْ بِصَلَاتِكَ وَلَا تُخَافِتْ بِهَا وَابْتَغِ بَيْنَ ذَلِكَ سَبِيلًا [الإسراء : 110]

Ma se maa gbohun soke lala nigbati o ba n kirun, ma si se maa se wuyẹ-wuyẹ pẹlu, ri wipe o duro laarin mejeeji yi ni". ( Oluwa ki Annabi r nilọ lati ma se pariwo, ki awọn ọta ma baa gbọ, ki wọnma baa  nii lara, bakanaa ki o ma se rẹ ohun nilẹ to bẹẹ gẹẹ ti awọn Sahabe rẹ  ko fi ni gbọ)

v A gbọdọ wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipa ọrọ-aje, kata -kara ati ibanilopọ. Oluwa sọ pe:

وَالَّذِينَ إِذَا أَنْفَقُوا لَمْ يُسْرِفُوا وَلَمْ يَقْتُرُوا وَكَانَ بَيْنَ ذَلِكَ قَوَامًا [الفرقان : 67]

"(Awọn ẹrusin Ọlọhun ni) awọn ti ọ se pe ti wọn ba n na owo wọn kii na ina-apa bẹẹ wọn kii se ahun, wọn a maa wa ni aarin mejeeji ni."

Oluwa tun sọ pe:

وَابْتَغِ فِيمَا آتَاكَ اللَّهُ الدَّارَ الْآخِرَةَ وَلَا تَنْسَ نَصِيبَكَ مِنَ الدُّنْيَا وَأَحْسِنْ كَمَا أَحْسَنَ اللَّهُ إِلَيْكَ وَلَا تَبْغِ الْفَسَادَ فِي الْأَرْضِ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ الْمُفْسِدِينَ  [القصص : 77]

Fi ohun ti Ọlọhun fun ọ (ni aye yii) wa ọrun (Alijanna), sibẹ-sibẹ ma se gbagbe ipin tirẹ naa ninu (igbadun) aye (ti kii se haraamu). Se daradara gẹgẹbi Ọlọhun naa ti se daradara si ọ. Ma se huwa ibajẹ lori ilẹ, dajudaju Ọlọhun ko nifẹ si awọn obilẹjẹ".

 

A gbọdọ wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipa ọrọ iwa ati ìse.

A gbọdọ wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipa ọrọ òfin, idajọ ati eto-ilu. Oluwa sọ pe:

إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَنْ تُؤَدُّوا الْأَمَانَاتِ إِلَى أَهْلِهَا وَإِذَا حَكَمْتُمْ بَيْنَ النَّاسِ أَنْ تَحْكُمُوا بِالْعَدْلِ [النساء : 58]

"Ọlọhun n payin  lasẹ ki ẹ pe amaanat (daa pada ni pipe) fun awọn ti o ni wọn. Nigbati ẹ ba si n dajọ laarin awọn eniyan ki ẹ dajọ pẹlu deede ".

 

A gbọdọ  wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipa bawo ni ati n lo ara ati ọkan wa.

A gbọdọ wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipa bawo ni ati le lo ọkan ati lakaye (oye) wa.

A gbọdọ wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) laarin ohun ti o jẹ ti awujọ ati eyi ti o jẹ ti adani.

A gbọdọ wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipa ohun ti a fẹ ati eyi ti o n  sẹlẹ lọwọ-lọwọ (koda bi a ko fẹẹ).

A gbọdọ wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipa ọrọ ti o kan agbara ti igbagbọ (Iman) ati agbara ijọba.

 

Iyanla wa Aishat –ki iyọnu Ọlọhun maa baa- sọ pe: Annabi r wọle tọ mi wa ni ọjọ kan ti o si ba arabinrin kan ni ọdọ mi. Nigbati o beere pe taani arabinrin naa, mo daa lohun pe lamọnrin ọmọ lamọnrin ni, ti mo si bẹrẹ si ni se irohin bi o ti maa n ki irun (nafila) lọpọlọpọ to (ati bi kii ti sun rara ni oru). Ojisẹ Ọlọhun r si dahun pe: Rara o! "Ohun ti agbara yin ba ka ni ki ẹ se o. Mo bura lorukọ Ọlọhun , Oun ki yoo da ẹsan rẹ duro fun yin ayafi ti ẹyin naa ba da isẹ ti ẹ nse duro". Aishat –ki iyọnu Ọlọhun maa baa- fi kun un wipe: Eyi ti Annnabi r ni ifẹ si julọ ninu ijọsin ni eyi ti eniyan tẹra mọ (ti o  lee se ni igba gbogbo). (Imam Bukhaari ni o gbaa wa).

وعن عائشة قالت: إن النبي دخل عليها وعندها امرأة قال من هذه قالت فلانة تذكر من صلاتها قال مه عليكم بما تطيقون فوالله لا يمل الله حتى تملوا وكان أحب الدين إليه مادام عليه صاحبه"- أخرجه البخاري.

Ninu Hadiisi miran ẹwẹ, Ibnu Abbas, (ki Oluwa yọnu si awọn mejeeji) sọ wipe: Annabi r pa mi lasẹ ki n lọ sa okuta fun oun lati ju ni asiko Hajji. Nigbati mo sa awọn okuta wẹẹrẹ (keekeeke) naa de, o sọ pe: Iru awọn okuta (keekeeke) bayi ni ki ẹ maa ju o, ki ẹ si jìnnà si aseju sise nibi ijọsin; daju-daju aseju sise nipa ijọsin ni o fa iparun fun awọn ijọ ti o siwajuu yin". (Imam Ahmad ni o gbaa wa bẹẹ).

"بأمثال هؤلاء وإياكم والغلو في الدين ، فإنما أهلك من كان قبلكم الغلو في الدين"- أخرجه أحمد

Oluwa ti Ọla Rẹ ga sọ pe:

يَا أَهْلَ الْكِتَابِ لَا تَغْلُوا فِي دِينِكُمْ وَلَا تَقُولُوا عَلَى اللَّهِ إِلَّا الْحَقَّ إِنَّمَا الْمَسِيحُ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ رَسُولُ اللَّهِ وَكَلِمَتُهُ أَلْقَاهَا إِلَى مَرْيَمَ وَرُوحٌ مِنْهُ فَآمِنُوا بِاللَّهِ وَرُسُلِهِ وَلَا تَقُولُوا ثَلَاثَة [النساء : 171]

"Ẹyin oni tira (Jews ati Christians) ẹma se se aseju ninu ẹsìn yin, ki ẹ si ma se pa irọ mọ Ọlọhun. Mesaya  Isa ọmọ Mọriyamọ ko jẹ ohunmiran yatọ si Ojisẹ Ọlọhun ati ọrọ Rẹ kan ti o ju si Mọriyamọ ati ẹmi kan (ti O dá) lati ọdọ araa Rẹ. Nitorinaa ẹ gba Ọlọhun gbọ ati awọn ojisẹ Rẹ, ki ẹ si yee sọ pe mẹta (ni Oluwa)…. ".  

 

Anasi bunu Mọliki t gba Hadiisi wa wipe: "Awọn arakunrin mẹta kan wa si ile awọn iyawo Annabi r lati waa se iwadi nipa ijọsin Annabi r. Sugbọn nigbati wọn gbọ esi si ibere wọn tan, o da bii wipe ijọsin naa kere jọjọ lojuu wọn, ni wọn wan da ara wọn lohun pe, idi ti o fa eyi ni pe, Ọlọhun ti fi ori ẹsẹ jin Annabi r patapata, (nitorinaa awa ko le fi ara wee). Lẹhin eyi ẹnikan ninu wọn sọ pe: gbogbo oru ni emi yoo maa fi kirun (emi ko nii sun rara loru). Ẹnikeji naa dahun o ni: gbogbo ọsan ni emi yoo maa fi gba awẹ. Ẹnikẹta si sọ pe: Emi ko nii fẹ iyawo lai lai. Nigbati Annabi r de, o sọ bayi: "Ee se ti ẹ fi n sọ iru ọrọ bayi! Mo bura ni orukọ Ọlọhun, emi ni mo bẹru Ọlọhun ju ninu yin, sibẹ-sibẹ emi a maa gba awẹ maa si tun maa jẹhun nigbamiran; bi mo ti ma n dide kirun loru emi a si tun maa sun nigbamiran; bakannaa ni mo si ni awọn iyawo. Ẹnikẹni ti o ba waa gunri kuro ni iru oju ọna temi yii, kii se ara (ijọ) temi o." (Imam Bukhari lo gbaa wa).

Orisirisi ọrọ awọn Oni mimọ, bii Imam Tọbari ati Imam Shatibi, ni o wa ni akọsilẹ lori ọrọ iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah). Wọn jẹ ki o ye wa pe iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) ni irohin awa ijọ Annabi r eyi ti a fi yatọ si awọn ẹlẹsin miran.

Awọn Kiriyo se aseju nipa Annabi Isa u ti wọn pe ni ọmọ Ọlọhun tabi Oluwa gan an funraa rẹ, nigbati awọn Yahudi ko tilẹ gba pe ọmọluabi ni rara . Awa Musulumi ni a wa ni iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) lori ọrọ Anabi Isa u ati awọn Annabi yoku عليهم السلام.

أقول قولي هذا وأستغفر الله لي ولكم ولسائر المسلمين فاستفغروه إنه هو الغفور الرحيم

الحمد لله، والصلاة والسلام على رسول الله وعلى آله وصحبه ومن والاه، أما بعد:

Ninu ohun ti o le jẹ ki a mọ pataki iwọntún-wọnsì  (al-wasatiyyah) nipe a maa jẹ ki isọkan jọba laarin awujọ bi o tilewu ki ede ati àwọ  yatọ si ara wọn to.

A tun maa jẹ ki a fi pẹlẹpẹlẹ se ohun gbogbo.

 Arakunrin ara-oko kan ti o sadede tọ si inu mọsalasi, ti awọn eniyan si bẹrẹ si ni ja igbe mọọ, ti wọn si fẹẹ le luu. Annabi r sọ wipe: Ẹ fi silẹ (ẹ ma se da itọ mọọ ni idi), ohun ti ẹ o se ni ki ẹ bu ọpọlọpọ omi le ori itọ rẹ naa lati fọọ danu; ohun ti a gbe yin dide lati jẹ ni olusenkan ni irọrun kiise olu-lekoko.  (Imam Bukhari ni o gbaa wa).

                                                       

Aseju ati aseeto, mejeeji ni o lewu nipa ọrọ ẹsin. Gbogbo asẹ ti Oluwa ba pa wa a gbọdọ muu sẹ lai se aseju tabi aseeto.

Apejuwe aseju nibi ẹsin niti oni royi-royi lọpọlọpọ lori irun tabi aluwala titi ti irun yoo fi maa bọ fun iru ẹni bẹẹ. Nigbati o ba pẹ kanrin lori aluwala lapejuwe.

Apejuwe aseeto ni ki a si idẹkun ti Oluwa fun wa lo. Lapejuwe Oluwa yọnda fun wa lati lọ irun Suhuri (Ayila) lara diẹ ti oorun ba mu jan-jan. Sugbọn eleyi ko `tumọ si ki a lọ irun lara kọja akoko rẹ. (Wo ẹda khutuba yii ni larubawa fun alekun apejuwe).

Koda o wa ninu Hadiisi Annabi r pe yoo wa ninu awọn alaseju ẹsin ti yoo maa kirun lọpọlọpọ tabi gba awẹ lere-lera, sugbọn ti Esu ti da ọrọ ru mọ loju, depo ti yoo maa fi ohun ti Ọlọhun se ni ẹtọ fun un silẹ ni ero pe oun fi n sin Ọlọhun ni.

 

إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُ بِالْعَدْلِ وَالْإِحْسَانِ وَإِيتَاءِ ذِي الْقُرْبَى وَيَنْهَى عَنِ الْفَحْشَاءِ وَالْمُنْكَرِ وَالْبَغْيِ يَعِظُكُمْ لَعَلَّكُمْ تَذَكَّرُونَ. وَأَوْفُوا بِعَهْدِ اللَّهِ إِذَا عَاهَدْتُمْ وَلَا تَنْقُضُوا الْأَيْمَانَ بَعْدَ تَوْكِيدِهَا وَقَدْ جَعَلْتُمُ اللَّهَ عَلَيْكُمْ كَفِيلًا إِنَّ اللَّهَ يَعْلَمُ مَا تَفْعَلُونَ.

وصلى الله وسلّم على نبينا محمد وعلى آله وصحبه.