islamkingdomfacebook


ÀWỌN ÌLÀNÀ TI A LE FI KO ÀWỌN ỌKÀN JỌ

ÀWỌN ÌLÀNÀ TI A LE FI KO ÀWỌN ỌKÀN JỌ

5252
Eko ni soki
Ibasepo pelu awon okan lati jere won je imo ti o munadoko ti o nwa bukaata si ki omoniyan dangajia nibe, eniti o fe se aseyege nibi ibasepo pelu awon okan gbodo mo awon kokoro ati ede ti o nsi okan, atiwipe ki o mo amodaju wipe, dajusaka, gbogbo okan pata ni o ni kokoro tire, eleyiti o se wipe lairi, eniyan ko lee wo okan, ninu re ni ireerin muse ati ikoko bere salamo ati ifunni ni ebun, ati bee bee lo.

 (ASALIIBU KASBIL KULUUBI)

Awọn erongba khutuba

1.         Síso ọkàn awọn musulumi pọ.

2.         Ìsàfimulẹ itumọ ijẹ ọmọiya ninu ẹsin Ọlọhun

3.         Imu ipepe isilaamu de ọdọ gbogbo eniyan ati sise suuru lori suta ọwọ wọn.

 isẹju marundinlogoji

 isẹju mẹtalelogun

الحمد لله رب العالمين خلق الإنسان في أحسن  تقويم , وفضلّه على كثير ممن خلق بالإنعام والتكريم , فإن استقام على طاعة الله استمر له هذا التفضيل في جنّات النعيم, وإلا ردّه في الهوان والعذاب الأليم.  وأشهد أن لا إله إلا الله وحده لا شريك له , وهو الخلاق العليم  وأشهد أن محمدا  عبده ورسوله شهد له ربه بقوله " وإنك لعلى خلق عظيم" صلّ الله عليه وعلى آله وأصحابه  الذين ساروا على النهج القويم  والصراط المستقيم وسلم تسليما كثيرا .. أما بعد

Ọpẹ ni fun Ọlọhun, Ọba to sẹda gbogbo agbaaye, asi njẹri ajẹdọkan pe ko si ẹlomiran ti a le sin lododo ayafi Allah, ko ni orogun bẹẹni a tun jẹri pe Anọbi Muhammad Ẹrusin Ọlọhun ni Ojisẹ rẹ ni. Ikẹ ati igẹ Ọlọhun ki o maa ba, gbogbo ara ile rẹ, awọn alabarin rẹ ati gbogbo ẹlẹsin Isilaamu lapapọ.

Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, Ọlọhun dá ọkàn ni ohunti yoo maa fà mọ sise rere, titiraka sibi erenjẹ si jẹ àdámọ rẹ.

"فَأَمَّا الأِنْسَانُ إِذَا مَا ابْتَلاهُ رَبُّهُ فَأَكْرَمَهُ وَنَعَّمَهُ فَيَقُولُ رَبِّي أَكْرَمَن".

Ọlọhun sọ pe: sugbọn enia nigbati Oluwa rẹ ba ndan a wo, ti O pọn ọ  le ti O si se idẹra fun Un, nigbana a maa sọ pe: “Oluwa mi pọn mi le” Suratul Fajri: 15.

"وَلَئِنْ أَذَقْنَا الإِنْسَانَ مِنَّا رَحْمَةً ثُمَّ نَزَعْنَاهَا مِنْهُ إِنَّهُ لَيَئُوسٌ كَفُورٌ(9) وَلَئِنْ أَذَقْنَاهُ نَعْمَاء بَعْدَ ضَرّمَسَّتْهُ لَيَقُولَنَّ ذَهَبَ السَّيِّئَاتُ عَنِّي إِنَّهُ لَفَرِحٌ فَخُورٌ(10) إِلاَّ الَّذِينَ صَبَرُواْ وَعَمِلُواْ الصَّالِحَاتِ أُوْلَئِكَ لَهُم مَّغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ كَبِيرٌ".

Ọlọhun tun sọ pe: Atipe ti A ba fi ikẹ tọ enia lẹnu wo lati ọdọ wa, lẹhinnaa ti A ba si gba a ni ọwọ rẹ (pada) dajudaju on yoo sọ ireti nu yoo se aimore .

Bi a ba si fun un ni idẹra tọ wo lẹhin inira ti o ti ba a, dajudaju yoo maa sọ pe: Awọn aburu ti kuro lọdọ mi, dajudaju on yoo yọ ayọju yoo si se iyanran (faari). Ayafi awọn ẹniti o se suuru ti nwọn si se isẹ rere. Awọn elewọn ni ni aforijin ati ore ti o tobi wa fun wọn” Suratul Hudu: 9 – 11.

“Anọbi wa (SAW) sọ pe: Awọn ẹmi dabi awọn ọmọ ogun ti a kojọ, awọn ti wọn ba mọ arawọn laarin wọn ẹnu wọn yoo sọkan, awọn ti wọn o ba mọra wọn yoo pinya”.

    Ẹyin ẹrusin Ọlọhun, bi ẹ ba se akiyesi dada, ẹ o ri wipe isilaamu se akolekan awọn ilana ti o le muni ri ọkan kojọ pupọ, lara rẹ ni awọn ọrọ ti iyawa Khọdijat sọ to fi rohin awọn iwa anọbi (SAW): Dajudaju irẹ jẹ ẹniti o maa nda okun ibii pọ, ti o si maa nran ọlẹ lọwọ, o si maa n pese fun ẹniti ko ni, bẹẹni o si maa npọn àlejo lé, ti o si maa nse iranlọwọ lori ajalu” Buhari lo gba wa.?

Ninu rẹ naa ni ìsopọ ti ọmọìya ti anọbi se laarin awọn Ansọri ati awọn tí wọn bá wọn lálejò (Mùhájìrúnà). A tun lefi adisi Jabiru se ẹri lori awọn ilana naa, o sọ pe: A wa laarin awọn ọmọ ogun kan, ni arakunrin kan ninu awọn Muhajirina ba lu arakunrin kan ninu awọn Ansọọri, ni arakunrin Ansọri ba ke pe: Ẹyin Ansọri ẹ gba mi o, bẹẹni arakunrin Muhajiru na ba sọ pe: Ẹyin muhajirun ẹ gba mi o. Ni ojisẹ Ọlọhun, ba gbọ ohunti wọn sọ yii, lo ba sọ pe: kini o sẹlẹ to jẹpẹ isesi igba alaimọkan lẹ tun nse? Ni wọn ba sọ fun anọbi pe arakunrin kan ninu awọn Muhajirina lo lu ọkan ninu awọn Ansọri, lojisẹ Ọlọhun ba sọ pe: Ẹ gbe e ju silẹ, toripe ọrọ to nrun ni. Nigbati Abdullọhi bunu Ubayi gbọ, o sọ pe: Se wọn se bẹẹ, sugbọn mo fi Ọlọhun búra, ti a ba de mọdina alagbara ilu yoo yọ ẹniyẹpẹrẹ jade ninu rẹ lọrọ ba de etigbọ anọbi (SAW) ni Umọru ba dide, to sọ pe irẹ ojisẹ Ọlọhun jẹ ki nbẹ ori munafiki yii danu, lojisẹ Ọlọhun ni fi silẹ o, ma jẹ ki awọn eniyan maa sọ pe Muhammadu npa awọn sahabe rẹ. Awọn Ansọọru ni wọn si pọju awọn Muhajiruna lọ, nigbati wọn kọkọ delu Mọdinah, lẹhinnaa ni awọn Muhajiruna wa padà pọ jùwọn lọ” Buhari ati Musilimuu lo gba a wa. Ati ọrọ anọbi (S.A.W) to sọ pe: dajudaju awọn kan nbẹ ninu yin ti wọn n mu awọn ẹniyan jinna sẹsin.

A gbọdọ so awọn ilana yii mọ igbagbọ ati iwa wa. Ni àpèjúwe, ẹ jẹki a wo itan arakunrin ti o wa lati ona jinjin ninu ilu.

"وَجَاءَ رَجُلٌ مِنْ أَقْصَى الْمَدِينَةِ يَسْعَى قَالَ يَا مُوسَى إِنَّ الْمَلَأَ يَأْتَمِرُونَ بِكَ لِيَقْتُلُوكَ فَاخْرُجْ إِنِّي لَكَ مِنَ النَّاصِحِينَ(20) فَخَرَجَ مِنْهَا خَائِفاً يَتَرَقَّبُ قَالَ رَبِّ نَجِّنِي مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ".

Ọlọhun sọ pe: Atipe ọkunrin kan sure wa lati ọna jinjin ninu ilu na, o sọ pe: irẹ Musa awọn ijoye ndamọran lati pa ọ, nitorinaa, jade (ni ilu yi) dajudaju alamọran rere ni emi jẹ fun ọ’’ Nitorinaa, o jade kuro ninu rẹ pẹlu ibẹru o nreti. O sọ pe: Oluwa mi, ko mi yọ lọwọ awọn alabosi enia’’ suratul Kọsọsi: 20 -21

Ọlọhun tun sọ nibo miran pe:

"وَجَاءَ مِنْ أَقْصَى الْمَدِينَةِ رَجُلٌ يَسْعَى قَالَ يَا قَوْمِ اتَّبِعُوا الْمُرْسَلِينَ(20) اتَّبِعُوا مَنْ لا يَسْأَلُكُمْ أَجْراً وَهُمْ مُهْتَدُونَ(21) وَمَا لِيَ لا أَعْبُدُ الَّذِي فَطَرَنِي وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ(22) أَأَتَّخِذُ مِنْ دُونِهِ آلِهَةً إِنْ يُرِدْنِ الرَّحْمَنُ بِضُرٍّ لا تُغْنِ عَنِّي شَفَاعَتُهُمْ شَيْئاً وَلا يُنْقِذُونِ(23) إِنِّي إِذاً لَفِي ضَلالٍ مُبِينٍ(24) إِنِّي آمَنْتُ بِرَبِّكُمْ فَاسْمَعُون".

 

Atipe Ọkunrin kan wa lati ipẹkun ilu na ti nsarẹ, o wipe:  Ẹyin enia mi ẹ tẹlẹ awọn ojisẹ na, Ẹ tẹlẹ awọn ti ko bere owo-ọya, nwọn jẹ ẹniti o tọna. Kini o le fa a ti emi ko fi ni sin Ẹniti o pilẹ da mi atipe ọdọ Rẹ ni a o da nyin pada si. Emi yoo ha mu awọn Ọlọhun miran lẹhin Rẹ ti ipẹ-sise wọn ko le se anfaani fun mi bi (Ọlọhun) Ajọkẹ aiye ba fẹ jẹ mi níyà kan  atipe nwọn ko le gba mi silẹ. Nigbanaa emi yoo ma bẹ ninu isina ti o han. Dajudaju emi gbagbọ ni ododo nipa Oluwa nyin, nitorinaa, ẹ gbọ temi”. Suratul Yasin 20:25.

O nfi gbogbo rẹ da abo bo o ni?

Ẹyin mumini ododo, ẹ lọ mọ pe awọn irohin ati iwa kan nbẹ ti a gbọdọ ri lara ẹniti o fẹ jere ọkan elomiran, lara rẹ ni:

1.         Didojukọ Ọlọhun niti ododo.

2.         Nini imọ nipa awọn ilana Anọbi ati awọn ẹniire, ẹni isiwaju lo lati fi jere ọkan awọn eniyan.

3.         Sísàmójútó òde ẹni irisi eniyan.

{فَاعْفُ عَنْهُمْ وَاسْتَغْفِرْ لَهُمْ وَشَاوِرْهُمْ فِي الأَمْرِ فَإِذَا عَزَمْتَ فَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ الْمُتَوَكِّلِينَ }.

          Ọlọhun sọ pe:                    

“Nitori àánu ati ọdọ Ọlọhun  wa, ni iwọ fi rọ fun wọn, ibasepe o jẹ oniwa buburu ati ọlọkan lile nwọn iba ti tuka kuro lọdọ rẹ. “Nitorinaa, mojukuro fun wọn ki o si maa ba wọn jiroro nipa ọran naa, bi o ba si pinnu tan ki o gbẹkẹle Ọlọhun “suratul Ali-imran: 159. 

            Ninu awọn ilana ti a le fi ko ọkan awọn eniyan jọ ni títújúká, bibọ ara ẹni lọwọ,  títẹtígbọ gbájare awon eniyan pẹlu didawọn nimọran tó dára, ríropọmọ wọn, bíbáwọnse, ninifẹsi mimu anfaani de ọdọ wọn, sísewọn lákin, didari wọn sibi rere, síse ìfaradà lori iwa agọ wọn, sísípayá ìsòro wọn, bibawọn sàwàdà to bamu, mimojukuro nibi asise wọn, kikopa to yanju lara wọn, jijinna si líla ohun ti wọn o lagbara rẹ bọwọn lọrun, siso awon isẹlẹ igba mọ awọn itan ododo ti a ríkà lati inu aikur’ani ati adisi anọbi wa [S.A.W] ati awọn irohin ohun ti nsẹlẹ lojumọ toni, didupẹ ati fifi ẹmi imoore han si ẹniti o ba se daada, ati ẹniti ọpẹ ba yẹ.

Ẹri awọn ohun ti a ka silẹ yi ni ọrọ Ọlọhun to sọ pe:

"والكاظمين الغيظ والعافين عن النّاس والله يحبّ المحسنين"

 “…ati awọn ti nkó ibinu (wọn) ni ijanu, ati awọn olumojukuro (ninu asise) fun awọn enia Ọlọhun fẹran awọn ti nsẹ rere Alimran: 134.

Ati ọrọ anabi to fi nse alayẹ ojusẹ musulumi si ọmọ iya rẹ, ati ọrọ rẹ to sọ: Ọlọhun kò níi yẹ, kò nii gbo lẹniti yoo maa ran ẹru Rẹ lọwọ, lopin igbati oun naa ba ti nran ọmọ iya rẹ lọwọ” Ati ọrọ ojisẹ Ọlọhun to sọ pe: musulumi tó nròpọ mọ awọn eniyan to si nsẹ àtẹmọra lórí sútá wọn, loore ju ẹniti kó ròpọ mọ wọn tí ko sì se ìfaradà lori suta wọn lọ

       Ati adisi miran tojisẹ Ọlọhun ti sọ pe “apèjùwe awọn mumini nibi nínífẹ ara wọn ati kíkẹ ara wọn, bi odindi ara kan ni, tó se pè, bi ọkan ninu wọn ba nse aisan, gbogbo orike ara yoku naa ni yoo maa ke ìrora ibà ati àìsùn

Abu Asim Aliaaraju sọ pe: Mo ri wa ni ibujoko saedu ọmọ Asilamu ti a jẹ ogoji afa to mọ fikiu, eyito kere julọ ninu iwa wa laarin wa ni, riranra-ẹni -lọwọ pẹlu ohun ti a ba ni nikapa , n o ri ẹnikan kan to ma n se àrìyànjiyàn tabi ifanfa ninu ọrọ kan ti ko ni se wa ni anfaani. Alfa wa Sahabi lo sọ ọrọ yii, nigbati o nse afihan Saedu bunu Aslam.

 


 

 

(lsẹju mejila)

 Ẹyin ẹrusin Ọlọhun awọn ọna miran naa tun nbẹ ti a le fi ko ọkan awọn eniyan jọ ninu rẹ ni sise amojuto ẹtọ awọn eniyan eyiti ojisẹ ọlọhun se alaye rẹ ninu awọn adisi rẹ ,bii sisalamọ siwọn, sisọrọ rere, fifun wọn lonjẹ jẹ, jijẹpe olupepe, titẹle oku debi itẹ rẹ, kikirun sii lara ,rirẹ oju silẹ. Ojisẹ lọhun sọ pe Iwọ musulumi si ọmọ iya rẹ musilumi mẹfa ni, wọn ni, awọn iwọ wo ni iwọ naa irẹ ojisẹ ọlọhun? O sọ pe: Ti o ba pade rẹ salamọ sii, ti o ba pe ọ, jẹ ipe rẹ, to ba ni ki o gba ohun ni imọran, gba nimọran to dara, ti o ba sín ti o se aliamdu lilahi, yara se adura fun un pada pe yariamukal lọhu, ti o ba saisan, se abẹwo rẹ, ti o ba kú, yara tẹlẹ e debi itẹẹrẹ”. Musilimu lo gbaa wa.

Ni lpari kiko awọn ọkan jọ, ati pipawọpọ pepe soju ọna Ọlọhun, tabi sisisẹ lọkọọkan gaan ni erongba wa, Ọlọhun sọ pe:

{وَمَا أُمِرُوا إلاّ لِيَعْبُدُوا اللهَ مُخْلِصِينَ لَهُ الدّينَ}.

 A ko pa wọn lasẹ ju pe ki nwọn fọ ẹsin mọ fun Un. Suratul Bayyinah: 5

Ọlọhun tun sọ pe:

"وتعاونوا على البرّ والتقوى ولا تعاونوا على الإثم والعدوان"

Ẹ ran ara yin lọwọ lori isẹ rere ati ibẹru Ọlọhun, ẹ mase ran ara nyin lọwọ lati da ẹsẹ, ati lati kọkọ tọ ija” Suratul Maidah: 2.

Ọlọhun tun sọ pe:                                     

"لو أنفقت ما فى الأرض جميعا ما ألّفت بين قلوبهم ولكنّ الله ألّف بينهم"

“Bi o ba se pe o na ohun ti mbẹ ni ori ilẹ patapata, o ko le pa ọkan wọn pọ. sugbọn Ọlọhun ni o se ipapọ ni arin wọn”. Suratul Anfaali : 63.

A nbẹ Ọlọhun  ki o fi aanu Rẹ ko ọkan Musulumi jọ, ki o si jẹ ki ẹnu wa sọkan nidi ẹsin Rẹ, ki o si se wa loloriire laye ati ni alkiyamọ.

فاتقوا الله -  عباد الله وخذوا بالأسباب  التي تكسب  بها القلوب  وذلك بلين الجانب للناس والإحسان اليهم وإعطاء كل ذي حقّ حقّه .... ثم صلّوا وسلموا على رسولنا محمد  وقد أمركم الله بذلك في كتابه قال تعالى:" إن الله وملائكته يصلّون على النّبي يأيها الذين آمنوا صلّو عليه وسلم تسليما . اللهم صلّ وسلم على عبدك ونبيك محمد بن عبد الله وارض اللهم عن الخلفاء الراشدين أبي بكر  وعمر  وعثمان وعلي وعن الصحابة أجمعين . اللهم أعزّ الإسلام والمسلمين وأذلّ الشرك والمشكين ودمّر  أعداء الإسلام اللهم اجعل هذا البلد آمنا مطمئنا  سخاء رخاء وسائر بلاد المسلمين يارب العالمين.