islamkingdomfacebook


IROYIN ATI ORIPA RE NI ISEMI AWON ENIYAN

IROYIN ATI ORIPA RE NI ISEMI AWON ENIYAN

6830
Eko ni soki
Awon ilana ifunniniro ode oni pelu awon oniranran ti o pin si ati awon orisirisi saneeli ni ipa ti o tobi nibi riroo iwoye omode ati ebi ati awujo ni alakotan, ati ikoni ni iwa, a o mo eleyi lati ara ohun ti awon ohun eelo ifunniniro gegebii, ipolowo oja

Awọn erongba lori Khutuba naa:

 

1-     Pipe akiyesi awọn eniyan si Pataki iroyin;

2-     Siso awọn irinsẹ iroyin pọmọ sise amojuto ẹsin;

3-     Sise alaye awọn iwa ti o yẹ ki a ri lara oniroyin;

4-     awọn isoro ti n dojukọ iroyin ninu Isilaamu.

الحمد لله الذي هيّأ سبل الاتّصال. ومنها الإعلام الذي هو وسيلة قديمة نشر الدعوة. والتساؤل عن مدى تأثير التقاليد الأمريكية الأوربية  على المجتمعات، وأن ذلك مرتبط بالإعلام المرئي الصوتي والمقروء، وماذا نفعل نحن المسلمين؟

Dajudaju ijọga ati ilapa ti asa ti ilu Oyinbo gẹgẹ bii Amẹrika ati Lọndọọnu ati bẹẹbẹẹ le jọga lori gbogbo asa ko sẹ lẹyin iroyin, yala eyi ti a n fi oju ri nio, tabi eyi ti a nfi eti gbọ, tabi eyi ti a n ka. Kinwani oripa awa Musulumi labala iroyin?

Dajudaju iroyin jẹ irinsẹ ti o se pataki, ti o si ti wa lati igbati o ti pẹ. Annabi (صلّى الله عليه وسلّم) ninu ọrọ rẹ sọ wipe: "Ẹ jẹ isẹ mi, koda bose aayat kan pere". Ati ọrọ Ọlọhun ti o sọpe: (awọn ti wọn n bẹru Ọlọhun ni awọn oni mimọ) [Fatir 35: 28].

(إنما يخشى الله من عباده العلماء) [فاطر 35: 28].

Ninu awọn ẹri tun ni ọrọ Ọlọhun:

(ثم أذن مؤذن أيتها العير إنكم لسارقون. قالوا وأقبلوا عليهم ماذا تفقدون. قالوا نفقد صواع الملك ولمن جاء به حمل بعير وأنا به زعيم) [يوسف 12: 70-72].

(Ni olupepe ba pepe wipe: ẹyin ero ole ni yin o! Ni wọn dide sumọwọn ti wọn si se ibere pe: ki ni nkan naa ti ẹ s e afẹku rẹ? wọn ni a ko ri osuwọn ọba mọ. Ẹnikẹni ti o ba si muu wa yoo gba ẹbun ẹru rankumi kan . Emi yoo si jẹ oniduro fun un) [suratul Yusuf 12: 70-72].

(وتفقد الطير فقال ما لي لا أرى الهدهد أم كان من الغائبين. لأعذبنه عذابا شديدا أو لأذبحنه أو ليأتيني بسلطان مبين. فمكث غير بعيد فقال أحطت بما لم تحط به وجئتك من سبإ بنبإ يقين. إني وجدت امرأة تملكهم وأوتيت من كل شيء ولها عرش عظيم..) [النّمل 27: 20-23].

(O (Sulaiman) si boju wo ẹyẹ, ni o ba beere wipe: nibo ni Hudihuda lọ ti mi o se ri abi ko wa nibi? Ti o si se ileri ati fi iya ti o nipọn jẹ ẹ, tabi ki oun o dunbu rẹ, afi ti o ba mu irokan ti o fi oju han wa. Ni Sulaiman ba joko diẹ, ni Hudihuda naa ba de ti o si wi fun un pe: mo ri nkan ti iwọ ko ri, koda mo mu iro nla kan ti o daju wa fun ọ lati ilu Sabai. Mo ri obinrin ti o nikapa le wọn lori, gbogbo nkan ni o ni, koda o tun ni aga ọla kan) [An-Naml 27: 20-23].

Titẹpẹlẹ mọ awọn iroyin ati isẹlẹ ti  fi ẹsẹ mulẹ pẹlu awọn onka ati isiro, pẹlu jijina si ifẹẹnu, didunima ojulowo ọrọ, sisọ ododo, sisọ amanat ni igbati a ba n gba iroyin jọ ati igbati a ba n sọọ fun awọn awujọ ti n gbọwa. Ki a mọ wipe gbogbo nkan ti a ba sọ a o se isiro rẹ. wo suratul Israa 17: 36, 56,

قوله تعالى: "ولا تقف ما ليس لك به علم، إن السمع والبصر والفؤاد كل أولئك كان عنه مسؤولا") [الإسراء 17: 36]. وقوله تعالى:"وإذا قلتم فاعدلوا"، وقوله:"وقل لعبادي يقولوا التي هي أحسن" [الإسراء 17: 53].

Ati As-Sọọfaat 37: 24,

وقوله تعالى:"وقفوهم إنهم مسؤولون" [الصّافات 37: 24].

Awọn ofin ti Isilaamu gbe kalẹ fun iroyin ti o fi ẹsẹ mulẹ:

1-     Al-'Akiidah; adisọkan ti o dara, nitoripe ẹni ti ko ni adisọkan ti o dara ọrọ ati isẹ rẹ naa ko lee dara.

2-     Ki oniroyin mọ wipe wọn yoo bi oun nipa iroyin oun.

3-     Ododo ati dọgbadọgba nibi ọrọ ati ise.

4-     Sise amulo ẹkọ ijiroro.

5-     Ki o ma gba itanjẹ pẹlu ero ati ọrọ araa rẹ.

Wo ẹri wọn ninu suratul Muhammad 47: 19, suratul Nahal 16: 125, suratul Lukman 31: 6.

ؤخذ البيان في هذا من قول الله تعالى:"فاعلم أنه لا إله إلا هو"، [محمّد 47: 19]، وقوله تعالى:"ادع إلى سبيل ربك بالحكمة والموعظة الحسنة، وجادلهم بالتي هي أحسن".  [النّحل 16: 125] وقوله تعالى:"ومن الناس من يشتري لهو الحديث ليضل عن سبيل الله بغير علم" [لقمان 31: 6

الحمد لله والصّلاة والسّلام على رسول الله، وبعد فأمثلة من الوقائع المشاهدة في دور النشر والإذاعة. وتوقف الكثير من الصحف والمجلات الخادمة للمجتمع  المكتوبة بلغة اليوربا.

Ninu awọn isoro ti n dojukọ iroyin ninu Isilaamu ni: Aito awọn eniyan ti wọn le se isẹyi de oju ami, aisi owo lati see, aimọkan ati ifẹẹnu. Apejuwe eleyi ni kikere ti ile isẹ iroyin ti n se amojuto ọrọ ẹsin Isilaamu ni ilẹ Yoruba kere, yala tẹlifisọn ni, tabi redio tabi iwe iroyin olojoojumọ.

Awọn ere ori itage; anfaani ti o wa fun wọn ati aleebu wọn. Ọlọhun sọ wipe:

(ما أريد أن أخالفكم إلى ما أنهاكم عنه، إن أريد إلا الإصلاح ما استطعت..) [هود 11: 88].

(mi o gbero ati yapa yin nibi n kan ti mo npe yin lọ sibẹ, nkan ti mo ro ni sise atunse bi mo ba se lagbara mọ) [suratul Hud 11: 88].

Ojuse ati ọranyan ijọba ati aladani si iroyin duro lori ọrọ Ojisẹ Ọlọhun to sọ pe: "ikilọ ni ẹsin jẹ", ati ọrọ Ọlọhun:

(الذين إن مكناهم في الأرض أقاموا الصلاة و ءاتوا الزكاة وأروا بالمعروف و نهوا عن المنكر، ولله عاقبة الأمور). [الححّ 22: 41]

(awọn ti o se wipe ti A ba gbawọn laaye lori ilẹ, wọn yoo maa gbe irun duro, wọn yoo maa yọ Sakat, wọn yoo si maa pa eniyan lasẹ daada, wọn yoo si maa kọ aida fun awọn eniyan) [Al-Hajj 22: 41].

 

وصلّى الله وسلّم وبارك وأنعم على نبيّنا محمّد وعلى آله وصحبه ومَن تبعهم بإحسانٍ إلى يوم الدِين.